Njẹ́ o mọ̀ pé àmujù omi le fa ikú òjìjì?

Eeyan kan to n mu omi

Oríṣun àwòrán, Getty Images

    • Author, Busayo James-Olufade
    • Role, Journalist
  • Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Lootọ la nilo lati mu omi fun alaafia ara wa, ṣugbọn ti a ba mu omi ju, a n fi ara wa sinu ewu nini aisan kan ti wọn n pe ni hyponatremia.

Diẹ lo ku ki arabinrin kan, to jẹ elere idaraya, Johanna Pakenham, ku lọdun 2018, lẹyin to mu omi bii lita marun-un.

Ninu iriri rẹ to sọ fun BBC, Johanna sọ pe oun ko mọ pe nnkan ti ko l’agbara bi omi mimu, le pa eeyan.

Ni ọjọ kan, Johanna kopa ninu ere sisa ọlọpọ maili, Marathon, nibẹ lo si ti mu omi lita marun-un.

Ori ere sisa lo wa nigba to deede ṣubu lulẹ lati ibẹ si lo ti di eero ileewosan.

O yọri si aisan hyponatremia – irufẹ aisan to ma n waye nigba ti eeyan ba mu omi ju bo ṣe yẹ lọ. Amuju omi ma n fa ki iy ati eroja minira to wa ninu ara sọ agabra wọn nu.

Ẹlomiran, Michelle Whitehead, ku ninu oṣu Kẹsan-an, ọdun 2023, lẹyin to mu omi ju bo ṣe yẹ lọ.

Iya ọlọmọ meji ọhun n gba itọju nilewosan aarun ọpọlọ. Nibẹ si lo ti bẹrẹ iwa ko ma a mu omi ju bo ṣe yẹ.

Lọjọ kan lo mu omi ju, to si gba ibẹ yọri si agbedemeji aye ati ọrun, ko to o di pe o pada gbẹmi mi.

Nigba wo ni omi minu le fa aisan hyponatremia?

Awọn onimọ sọ pe ti eeyan ba mu omi to pọ lẹẹkan naa, fun apẹẹrẹ, lẹyin ere idaraya to le tabi lẹyin ti eeyan mu ọti lile to pọ, omi le fa Hyponatremia.

Ti eeyan ba ti ni aisan yii, kindinrin to wa ninu ara ko ni i le ti odiwọn omi to yẹ ko ti jade ninu ara, jade. Eyi yoo si yọri si ki iyọ to wa ninu ẹjọ o di alailagbara, nitori a pọju omi.

Ti iyọ naa ba ti ri bẹẹ, o le yọri si gìrì, irin ẹsẹ ko nii ja gere, eeyan le wa ni agbede meji aye ati ọrun tabi iku.

Ẹnikẹni to ba wa niru ipo yii nilo itju pajawiri lati da iyọ inu ẹjẹ pada si ipo rẹ.

Itọju naa yoo fun kindinrin ni anfani lati ti omi jade ninu agọ ara alaisan naa.

Ọna ti wọn n gba ṣe itọju aisan hyponatremia ni p, wọn o fa apopọ iyọ ati awọn nnkan mi sinu ẹjẹ alaisan naa

Bawo wo lo ṣe yẹ ki o mu omi to loojọ?

Omi to wa ninu gilaasi

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Iye omi ni ti eeyan kọọkan nilo lati mu lojoojumọ yatọ si ara wọn – eyi nii ṣe pẹlu ilera ara wọn, ọjọ ori, bi ara wọn ṣe tobi to, iru iṣẹ ti wọn n ṣe, agbegbe ti wọn n gbe.

Ni ọdun 2010, ajọ to n mojuto ipese ojulowo ounjẹ nilẹ Yuroopu, EFSA, sọ ninu abọ iwadii kan pe, mimu lita nnkan mimu loojọ lo dara fun awọn obinrin, ati lita meji aabọ fun ọkunrin.

Onka yii jẹ akojọpọ omi, awọn nnkan mimu mii, ati omi to wa lara ounjẹ ti a n jẹ.

Iwadii sọ pe ida ogun ninu omi to n wọ agọ ara wa lo n wa lati ara ounjẹ.

Awọn onimọ sayẹnsi mii tun sọ pe lita omi mẹta, tabi gillasi omi mẹjọ lo yẹ ki eeyan o mu lojumọ.

Ṣugbọn iwadii tuntun kan lọdun 2022, eyi ti awọn onimọ sayẹnsi ni fasiti Aberdeen ṣe, tun sọ pe lita omi meji ti pọ ju fun ẹnikan lati mu loojọ.

Awọn onimọ naa sọ pe niwọn igba to jẹ pe pupọ ninu omi to n wọ agọ ara n wa lati inu ounjẹ, ko yẹ ko ju lita kan aabọ si lita meji din diẹ (1.8) omi ti ara nilo.

Ọjọgbọn John Speakman lati fasiti Aberdeen sọ fun BBC pe omi to yẹ ka mu, jẹ iyatọ to wa laarin omi ta a nilo ninu ara ati iye to n wa lati inu ounjẹ.

“Nitori pe awọn eeyan kii ṣaba sọ odinwọn ounjẹ ti wọn n jẹ, ko si bi aṣisẹ ko ṣe ni wa ninu ṣiṣe odinwọn iye omi to yẹ ki wọn o mu.”

Nigba wo ni a le sọ pe omi minu pọ ju?

Lootọ ni odinwọn omi minu nii ṣe pẹlu awọn nkan ti a mẹnu ba tẹlẹ, ṣugbọn to ba mu omi debi pe ikun rẹ yọ sita pupọ tabi ti ara rẹ wuwo, jẹ ikọja aaye.

Mu omi de ipele pe ongbẹ ko gbẹ ọ mọ, ki o si da wọ duro.

Yago fun mimu omi to pọ tabi awọn nnkan mimu miran lẹẹkan naa.

Nitori naa, nigbakugba ti o ba fẹ mu omi, boya lẹyin ere idaraya, tabi lẹyin amuju ọti lile, ranti pe omi mimu le ṣe akoba fun ọ ti o ba mu u ju.