Iná jó ilé Alao Akala ní Ogbomoso, ẹ̀mí èèyàn kan bá a lọ

Ni airotẹlẹ ni ina dede ṣeyọ ninu ọkan lara awọn ile to n bẹ ninu ọgba Gomina tẹlẹri n'ipinlẹ Ọyọ, Oloogbe Ọtunba Adebayọ Alao Akala l'owurọ ọjọ Aje.
BBC Yoruba ṣe abẹwo si ile naa to n bẹ ni agbegbe Randa niluu Ogbomọṣọ lati wo ohun to ṣẹlẹ nibẹ.
Ọkan lara awọn olugbe ile naa, ti a fi orukọ bo l'aṣiri, fi idi ọrọ mulẹ fun akọroyin BBC wi pe ni nnkan bii aago meje aabọ si mẹjọ owurọ ọjọ Aje ni iṣẹlẹ naa waye.
Olugbe ile naa ni, "Ina ẹlẹntriki lo de lojiji l'owurọ yii ti o si jo ẹni kan. Ẹlomii naa tun fi ara pa."
Ṣugbọn, iroyin kan ti BBC ko le fidi rẹ mulẹ sọ pe eeyan meji lo ku ninu ina to jo naa.

Bakan naa ni iroyin sọ pe obinrin meji lo jona ninu ile naa, amọ awọn alaṣẹ ko tii fidi eyi mulẹ.
Gẹgẹ bi ileeṣẹ iroyin ori ayelujara Ogbomoso Insight ṣe sọ, inu ile alaja kan ọhun ni Oloogbe Alao Akala gbe titi to fi di igbakeji gomina ipinlẹ Oyo lọdun 2003.
Ninu oṣu kinni ọdun 2022 ni Ọtunba Adebayọ Alao-Akala jade laye.
O jẹ gomina ipinlẹ Oyo laarin ọdun 2007 si 2011
Lati igba ti Gomina tẹlẹri naa ti re ibi agba n re, girigiri ẹsẹ ko fi bẹẹ wọpọ ni ile naa, ki o to di wi pe ina sọ nibẹ l'owurọ oni.












