Gansu earthquake: Ó lè ọgọ́rùn ùn èèyàn tó bá ìjàmbá ilẹ̀ rírì tó lágbára jùlọ láàrin ọdún mẹ́tàlá ní China lọ

Oríṣun àwòrán, Reuters
O kere tan eeyan mejidinlọgọfa lont8 padanu ẹmi wọn ninu ijamba ilẹ riri kan to waye ni iwọ oorun Ariwa China.
Ni akọsilẹ ijamba yi lo l'agbara julọ laarin ọdun mẹtala sẹyin.
Ilẹ riri yi to to iwọn 6.2 ṣe ikọlu si agbegbe ori oke Gansu ni nkan bi ago mẹrin irọlẹ ọjọ Aje to si tun milẹ titi de Wing hai to wa nitosi.
O ṣeéṣe ki iye àwọn to ku ninu iṣẹlẹ naa lekun si ti a sí gbọ pe awọn kan farapa nibi ti otutu yiyin pọ si.
Aarẹ Xi Jinping ti pàṣẹ ki wọn ko awọn adoola ẹgbẹgbẹrun lọ si agbegbe naa nibi t'awọn talaka pọ si ni China.
Lọjọ Ìṣẹgun awọn ileeṣẹ amohunmaworan ilẹ China safihan odindi abule ti ilẹ riri yi la si meji ati awọn ile to dawo.
O tun safihan awọn olugbe to sa asala níbi ti wọn ko ara wọn jọ si lẹgbẹ ina ti wọn n ya ninu otutu.
Ileeṣẹ iroyin China jabo pe otutu naa pọ to odiwọn -13C (8.7F) lọjọ Iṣẹgun.
Awọn ti ori ko yọ ninu ilẹ riri yi sọ pe o da bi pe "omi okun n ya bo wa ninu ile"
Ọpọ lo ba are jade kuro ninu ile wọn.
Arákùnrin kan Mr Qin gẹgẹ bi awọn ileeṣẹ iroyin China ṣe salaye sọ pe:
"Mo ji awọn idile mii tí gbogbo wa si sare sọkalẹ ninu ile alaja mẹrindinlogun papapa"

Oríṣun àwòrán, Reuters
Awọn alaṣẹ ni agbegbe Jishisha nibi ti wọn ti faragba ìṣẹlẹ ilẹ rírì yí julọ ni Gansu sọ pe o le ni ile ẹgbẹrun marun un ti ilẹ riri yi da wó.
Awọn ileeṣẹ iroyin China sọ pe oludari awọn adoola ni Gansu ni ọpọ ile to ti d'arugbo lo jẹ ki ile to wo pọ tori amọ̀ ni wọn fi kọ awọn mii ninu wọn.
Ilu Gansu wa laarin ori oke Tibet ati Loess to fara ti ibode pẹlu Mongolia.
Agbegbe to jina yi lọpọ awọn ti oṣi n ba finra n gbe ni China bẹẹ si ní wọn yatọ nípa ẹya ati ìṣesí wọn pẹlu araalu to ku.
Agbegbe Linxia Hui ni aarin ibi ti ilẹ riri yi ti sakoba julọ.
Ibi si ni ọpọ awọn musulumi n gbe to fi mọ awọn ẹya Hui, Bonan, Dongxiang ati Salar.












