Ìṣẹ̀lẹ̀ ilẹ̀ rírì Morocco ti mú ẹ̀mí èèyàn tó lé ní 2,000 lọ

Morocco earthquake

Oríṣun àwòrán, getty images

Apapọ iye eyann to ti jade laye lẹyin iṣẹlẹ ilẹ riru to waye ni Morocco ti le ni ẹgbẹrun meji bayii.

Minisita fun ọrọ abẹle orilẹ-ede naa sọ pe o le ni ẹgbẹrun kan ati rinwo eeyan to farapa yanayana.

Ọba Morroco, Mohammed Kẹrin, ti kede ọfọ ọlọjọ mẹta kaakiri orilẹ-ede naa latari iṣẹlẹ ọhun.

Ọpọ awọn ti wọn padanu ile wọn ni wọn ti bẹrẹ si n sun ita gbangba bayii.

Nnkan bii aago mọkanla alẹ ọjọ Ẹti ni iṣẹlẹ naa waye nigba meji leralera.

Bo tilẹ jẹ pe agbegbe Atlas Mountains ni iṣẹlẹ ilẹ riru naa ti waye, wọn gburo rẹ ni Rabat, to jẹ olu ilu orilẹ-ede ọhun to si wa ni nnkan bii kilomita 350.

Ìṣẹ̀lẹ̀ ilẹ̀ rírì tó wáyé ní Morocco ti mú ẹ̀mí èèyàn 1,037 lọ

Morocco earthquake

Oríṣun àwòrán, Getty images

Iroyin to n tẹ wa lọwọ bayii lati orilẹ-ede Morocco ti sọ pe apapọ iye eeyn to ti ku latari iṣẹlẹ ilẹ riri to waye lorilẹ-ede naa ti di ẹgbẹrin ati ogun (820) bayii.

Ibi ti iṣẹlẹ naa ti milẹ titi julẹ ni Atlas Mountains, to wa ni maili mẹrinlelogiji iha iwọ oorun Marrakesh.

Nnkan bii aago mọkanla kọja iṣeju mọkanla aṣalẹ ni iṣẹlẹ ilẹ riri naa waye, ko to tun ṣẹlẹ nigba keji ni nnkan bii iṣeju mọkandinlogun lẹyin naa.

Minisita fun ọrọ abẹle orilẹ-ede naa sọ pe yatọ si Marakesh ti awọn eeyn ti ku, ọpọ awọn mii lo tun ku ni iha guusu orilẹ-ede ọhun.

Pupọ ninun awọn tro ba iṣẹlẹ naa lọ ni igbagbọ wa pe wọn n gbe lawọn igberiko.

Lara awọn ibo mii ti awọn eeyan tun ti ku ni al-Haouz, Marrakesh, Ouarzazate, Azilal, Chichaoua ati Taroudant.

Ẹgbẹta (600) eeyan lo farapa ninu iṣẹlẹ ọhun.

Ó ti di òkú 632 tó bá ìṣẹ̀lẹ̀ ilẹ̀ ríri lọ ní Morocco,329 farapa

Aworan awọn ti ilẹ riri ṣakoba fun ni Morocco

Oríṣun àwòrán, Reuters

O kere tan eeyan to le ni ẹgbẹta lo ti padanu ẹmi wọn ninu iṣẹlẹ ilẹ riri kan to waye ni orileede Morocco.

Awọn taa si gbọ pe o farapa ninu iṣẹlẹ naa ti le ni ọọdunru,

Ni agbegbe kan ti oke pọ nibẹ to wa ni itosi Marrakesh ni iṣẹlẹ yi ti waye gẹgẹ bi iroyin taa gbọ lọdọ ileeṣẹ to n risi iṣẹlẹ ayika,US Geological Survey.

Nkan bi ago mẹwa kọja iṣẹju mọkanla ni ilẹ riri yi waye.

Ilẹ riri miran to to iwọn agbara 4.9 tun tẹle ilẹ riri akọkọ ni ṣiṣẹntẹle ni nkan bi iṣẹju mọkandilogun.

Lọpọ awọn ilu to yi Marrakesh ka ni ila guusu orileede naa ni a gbọ pe ọpọ ti farapa tawọn eeyan si padanu ẹmi wọn.

Ileeṣẹ aabo labẹle lo fidi ọrọ yi mulẹ ni Morocco

Iṣẹlẹ ilẹ riri yi mu ki ọpọ agbagbe ma ni ina mọnamọna.

Ko tan sibẹ, a tun gbọ pe o ṣe akoba fun ipese internet ẹrọ ayelujara ti awọn eeyan ko si ribi kan si ara wọn mọjumọ iṣẹlẹ yi.

Awọn ti iṣẹlẹ yi ṣoju wọn ni niṣe lawọn n jaya nigba ti ilẹ riri yi waye.

Ọmọ orileede Faranse kan to ba ileeṣẹ iroyin AFP sọrọ ṣalaye pe oun n sun lọwọ ni nigba ti ilẹ riri yi ṣẹlẹ.

O ni ''niṣe ni mo ro pe ibusun mi n gbera sioke lati fo lọ.O sunmọ pe ihoho ni mo sare jade lati lọ wo awọn ile ibilẹ mi ti mo kọ.O kọja afẹnusọ''

'It was total chaos': Night-time disaster sows panic

Arabinrin kan Dalila Fahem sọ fun Reuters pe '' Ori ba mi ṣe wi pe mi o ti sunlọ nigba ti iṣẹlẹ yi waye.'' O ni ilẹ riri naa ba ile oun jẹ.

Ita gbangba lọpọ sun si ni Marrakesh

Ibẹru ati ifoya ko jẹ ki awọn eeyan sun sinu ile wọn eyi to mu ki wọn sun si ita gbangba ni Marrakesh.

Titi ti ilẹ fi mọ, ita ni ọpọ sun si tawọn mii ko si tiẹ ri orun sun rara nitori ibẹru ohun ifoya.

Awọn aworan yi ṣafihan bawọn eeyan '\se da aṣọ bora sun sita ni Marrakesh.

Aworan awọn ti ilẹ riri sọ di ero ita ni Marrakesh

Oríṣun àwòrán, AFP

Aworan bawọn eeyan ṣe sun sita ni Marrakesh

Oríṣun àwòrán, AFP