Àwọn obìnrin 340 ló lu ọkọ wọn ní àlùbami láàárín ọdún kan - Ìjọba Eko

Aworan afihan Obinrin to n lu ọkọ won

Oríṣun àwòrán, Others

Ìjọba ìpínlẹ̀ Eko ti ní kò dín ní 340 àwọn obìnrin tó ń dá sèríà fún ọkọ wọn ní ìpínlẹ̀ náà láàárín ọdún kan.

Ọ̀gá àgbà àjọ tó ń rí sí ìwà ìfìyàjẹni àti àwọn ìwà ipá ìyẹn Domestic and Sexual Violence (DSVA), Titilola Vivour-Adeniyi ló ṣíṣọ lójú ọ̀rọ̀ ọ̀hún láìpẹ́.

Vivour-Adeniyi ní àwọn ọkùnrin tó ń wá fi ẹjọ́ ìwà ipá nínú ìgbéyàwó wọn sùn ń lékún ní ojoojúmọ̀ ní ọdún kan sẹ́yìn.

Ó ní àwọn ọkùnrin 340 ló wá fi ẹjọ́ bí àwọn ìyàwó wọn ṣe máa ń nà wọ́n nínú ilé sùn wọ́n láàárín oṣù Kẹsàn-án ọdún 2022 sí oṣù Keje ọdún 2023.

Ó ṣàlàyé pé iye àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ló fi ìdá ọgọ́rùn-ún ju iye ìṣẹ̀lẹ̀ tí wọ́n rí láàárín oṣù Kẹsàn-án ọdún 2021 sí oṣù Keje ọdún 2022 tí ó jẹ́ 140.

Ó ní èyí ṣàfihàn pé bí àwọn ọkùnrin ṣe máa ń dákẹ́ tí wọ́n bá ń kojú àwọn ìwà yìí nínú ìdílé ti ń wá sópin láìpẹ́.

Vivour-Adeniyi tẹ̀síwájú pé ìwádìí fi hàn pé ní ọwọ́ alẹ́ ni àwọn ìwà ipá yìí máa ń wáyé.

Ó fi kun pé ìdá ọgọ́rin àwọn ẹ̀sùn ìwà ipá tí wọ́n mú wá sí ọ̀dọ̀ àwọn ló jẹ́ pé àwọn obìnrin ni ó ṣẹlẹ̀ sí jùlọ.

Ó ní ó túmọ̀ sí pé àwọn obìnrin ló ṣì ń kojú ìwà ipá nínú ìgbéyàwó jùlọ àti pé àwọn obìnrin tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣẹlẹ̀ ṣàlàyé pé inú oyún ni àwọn wà tí àwọn ìwà ipá náà fi wáyé sí àwọn.

Bákan náà ló fi kun pé bí àwọn ènìyàn ṣe ń fi ìwà ipá sùn ni àlékún ti bá láàárín 2022 sí oṣù Keje ọdún 2023.