₦100m ni a ó fún ẹnikẹ́ni tó bá lè ṣamọ̀nà bí ọwọ́ ṣe lè tẹ àwọn tó gé orí DPO – Ìjọba Rivers

Oríṣun àwòrán, Sir Siminalayi Fubara
Gomina ipinlẹ Rivers, Siminalayi Fubara, ti kede ẹbun owo ọgọrun miliọnu naira fun ẹnikẹni to ba le ṣamọna bi ọwọ yoo ṣe tẹ awọn to ṣekupa DPO kan nipinlẹ naa.
Fubara lo fi ọrọ naa lede ninu atẹjade kan loju opo Facebook rẹ lọjọ Abamẹta.
Ti ẹ ko ba gbagbe, ṣaaju ni awọn afurasi ọmọ ẹgbẹ okunkun kan ti kọkọ da oloogbe naa, Bako Angbashim atawọn akẹgbẹ rẹ lọna, ti wọn si ge ori ati nnkan ọmokunrẹ lẹyin ti wọn pa a tan.
Gẹgẹ bii atẹjade gomina naa, orukọ olori awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun to pa DPO ọhun ni Gift David Okpara Okpolowu, apẹle rẹ n jẹ “ 2-Baba.”
O ni “Lakọkọ afurasi ti a n wa ganga ni ọgbẹni Gift David Okpara Okpolowu, ti apẹle rẹ n jẹ 2-Baba, ati gbogbo ọmọ ẹgbẹ rẹ.”
“Ẹlẹẹkeji, a o fun ẹnikẹni to ba le fun wa ni iroyin bi ọwọ yoo ṣe ọgbẹni naa ni ọgọrun miliọnu naira ko le foju wina ofin.”
“Ikẹta ni pe ni a ti jawe lọ rọọkun nile fun Kabiesi Eze Cassidy Ikegbidi Eze Igbu Akoh II, fun aibikita rẹ, ti agbegbe rẹ fi di ibi ti awọn ọdaran naa ti n ṣọṣẹ bo ṣe wu wọn ti ko si ri nnkan ṣe si.”
Lẹyin naa lo ba mọlẹbi oloogbe kẹdun iku rẹ, to si tun juwe rẹ gẹgẹ bii akikanju agbofinro to ṣe e mu yangan lawujọ awọn akẹgbẹ rẹ.
Àwọn afurasí ọmọ ẹgbẹ́ òkùnkùn ṣekúpa DPO, wọ́n gé orí àti nǹkan ọmọkùnrin rẹ̀

Oríṣun àwòrán, Portharcourt specials
Awọn afurasi ọmọ ẹgbẹ okunkun ti ṣekupa DPO ọlọpaa kan, Bako Amgbanshin, nipinlẹ Rivers, ti wọn si ṣe oku rẹ baṣubaṣu.
Iroyin ni ṣe ni awọn agbegbọn naa dena de ọlọpaa naa atawọn akẹgbẹ rẹ lasiko ti wọn n bọ lati ibi ti wọn ti lọ tọpinpin awọn ọdanran kan lagbegbe Ahoada.
Gẹgẹ bii ohun ti a gbọ, ṣe lawọn agbebọn naa ṣina ibọn bolẹ ni kete ti wọn foju ganni ọlọpaa ọhun atawọn to wa pẹlu rẹ, ti iro ibọn si dun lakọlakọ.
Oṣojumi koro kan ti ko fẹ fi orukọ rẹ lede ṣalaye pe “Wọn ṣina ibọn bolẹ fun ara wọn ni kete ti awọn ọmọ DPO naa atawọn ọmọ Iceland ti 2baba ko sọdi ri ara wọn titi ti ọta fi tan ninu ibọn wọn.”
A gbọ pe oloogbe naa duro digbi bi iro ibọn naa ṣe n dun lakọ lakọ bo tilẹ jẹ pe awọn akẹgbẹ rẹ yoku na papa bora.
Ko pẹ lẹyin naa ni ọwọ awọn afurasi ọmọ ẹgbẹ okunkun naa tẹ DPO ọhun, ti wọn si mu laaye.
Fidio kan to gba ori ayelujara ṣafihan ori ati nnkan ọmọkunrin oloogbe naa ti awọn afurasi fi n ṣe ẹlẹya lẹyin ti wọn ge tan.
Ninu fidio ọhun ni ọkan ninu awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun naa ti n sọ pe “DPO ṣe iwọ niyẹn... ki lo n ṣẹlẹ... iwọ lo laya lati gbena woju awọn ọmọ ẹgbẹ Iceland.”
Ọlọpaa Rivers ṣeleri lati mu awọn afurasi
Ẹwẹ, alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Rivers, Grace Iringe-Koko, ti sọ pe iṣẹlẹ naa ba awọn ninu gigi, ati pe kọmiṣọna ọlọpaaa ipinlẹ naa ṣọfọ oloogbe ọhun.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
Ninu atẹjade kan loju opo Twitter rẹ, ileeṣẹ naa sọ pe awọn ko ni sinmi titi ti ọwọ yoo fi tẹ gbogbo awọn to lọwọ ninu iku oloogbe baa.
O pari atẹjade naa pe oloogbe ọhun jẹ akinkanju agbofinro to gbogun ti iwa ọdaran ni ipinlẹ Rivers ṣsaju iku rẹ.












