Wo ìdí táwọn aṣaájú G20 fi ń ṣe ìpadé ní Delhi

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Awọn asiwaju orilẹede atawọn olootu ijọba yika agbaye lo n sepade nilu Delhi, lorilẹede India.
Ipade G20 naa, to maa n waye lọdọọdun lo bẹrẹ lọjọ Kẹsan osu kẹsan ọdun 2023, ti yoo si waye lọjọ kẹwa osu Kẹsan.
Akori ipade ti ọdun yii ni Ifẹsẹmulẹ idagbasoke, bakan naa ni wọn yoo jiroro lori ogun to n waye laarin orilẹede Ukraine ati Russia.
Ki lo n jẹ G20?
Ẹgbẹ G20 yii, ti wọn jẹ ogun niye, lo jẹ gbẹ awọn orilẹede to maa n joko se ipade lọdọọdun lati jiroro lori eto to wa nilẹ fun agbega ọrọ aje agbaye.
Laarin wọn, awọn orilẹede to wa ninu ẹgbẹ G20 naa lo n pese ida marunlelọgọrin ọrọ aje agbaye ati ida marundinlọgọrin ọrọ aje agbaye.
Awọn si lo ko ida mmeji ninu ida mẹta iye eeyan to wa lorilẹ aye.
Awọn orilẹede to wa nilẹ Yuroopu ati awọn orilẹede mọkandinlogun mii bii Argentina, Australia, Brazil, Canada, China, France, Germany, India, Indonesia, Italy, Japan, Mexico, Russia, Saudi Arabia, South Africa, South Korea, Turkey, to fi mọ ilẹ UK ati Amẹrika lo wa ninu ẹgbẹ G20 naa.
Amọ wọn maa n ransẹ pe orilẹede Spainlati bawọn peju bii alejo.
Bakan naa, ida kọnkọ awọn ọmọ ẹgbẹ G20 naa si maa n sepade gẹgẹ bii ọmọ ẹgbẹ mii ti wọn n pe ni G7.
Bakan naa, lara awọn ọmọ ẹgbẹ G20 yii bii Brazil, Russia, India, China ati South Africa -lawọn naa tun ti da ẹgbẹ miran silẹ ti wọn n pe ni Brics.
Nitori ki ẹgbẹ naa le gbooro, wọn tun ti ransẹ pe awọn orilẹede mẹfa miran lati darapọ mọ wọn.
Awọn orilẹede naa ni: Argentina, Egypt, Iran, Ethiopia, Saudi Arabia ati United Arab Emirates.
Ki ni wọn n jiroro le lori?

Oríṣun àwòrán, Reuters
Awọn koko ọrọ tawọn asaaju orilẹede to wa ninu ẹgbẹ G20 n jiroro le lori lọdọọdun tun ti gbooro si lati ọdun diẹ sẹyin, o si ti kuro ni ti ọrọ aje nikan.
Lara awọn ohun mii ti wọn tun n jiroro le lori ni ayipada oju ọjọ, ifẹsẹmulẹ ohun amusagbara, aforijin ọrọ aje ati awọn ajọ olowo ori lagbaye.
Ni ọdọọdun ni aarẹ ẹgbẹ tuntun maa n gbakoso ẹgbẹ naa, ti wọn si maa n kede afojusun wọn tuntun.
Orilẹede Indonesia lo se aarẹ kọja lọdun 2022, ilu Bali si ni wọn ti se ipade wọn ni eṣin.
Gẹgẹ bii aarẹ gbẹ lọdun 2023, orilẹede India n fẹ ki ipade to waye nilu Delhi naa dojukọ rifẹsẹmulẹ idagbasoke ati itankalẹ idagbasoke ọrọ aje laarin awọn orilẹede to ti dide nilẹ atawọn orilẹede to si n rakoro.
Ipade naa lo tun n pese anfaani fun ikọọkan orilẹede naa lati jiroro laarin ara wọn tabi ki wọn pin ara wọn si isẹri-isọri.
Orilẹede Amẹrika ni aarẹ Joe Biden yoo ba ikọọkan asaaju orilẹede sọrọ lori wiwa ojutu si ayopada oju ọjọ, Ogun to n waye laarin Russia ati Ukraine, mimu ki awọn ajọ agbaye bii Banki agbaye tubọ sa ipa wọn lati gbogun ti osi.
Amọ aarẹ orilẹede Russia, Vladimir Putin ko ni bawọn peju si ibi ipade naa, tawọn iroyin kan si tun fikun pe aarẹ orilẹede China, Xi Jinping, naa ko ni bawọn peju.

Ọgbẹni Lavrov lo soju aarẹ Putin nibi ipade Brics to waye nilẹ South Africa, bi o tilẹ jẹ pe Putin ba ipejọpọ naa sọrọ lati ori ẹrọ igbalode itakun agbaye.
Ni osu Karun, China atiSaudi Arabia ko peju sibi ipade G20 to wa fun irinajo afẹ to waye ni agbegbe Kashmir ti orilẹede Indian-n dari rẹ nitori pe agbegbe Kashmir yii naa ni orilẹede Pakistan n dari abala kan nibẹ.
Bakan naa ni ija ti bẹ silẹ laarin orilẹede India ati China lori aala ilẹ ọlọjọ pipẹ, lẹyin ti Beijing gbe maapu kan sita eyi to n safhan pe ipinlẹ Arunachal Pradesh ati oke Aksai Chin jẹ ara orilẹede China.

Oríṣun àwòrán, Reuters
Ki ni aseyọri ẹgbẹ G20?
Ni ipade awọn adari to waye ni ọdun 2008 ati 2009, lasiko isoro ọda owo, awọn asaaju naa fẹnuko lori oniruuru ọna lati gba agbaye kalẹ lọwọ isoro ọrọ aje.
Amọ awọn onwoye salaye pe ko si aseyọri kankan mọ lasiko awọn ipade to tẹle eyi nitori wahala awọn orilẹede alagbara lagbaye to n ba ara wọn se orogun.
Amọ awọn ipade isọri isọri to maa n waye lasiko ipade gbogbo G20 naa maa n seso rere.
Lọdun 2019 nilu Osaka, Aarẹ Donald Trump ti Amẹrika ati aarẹ ilẹ China, Xi Jinping, fẹnu ko lati bẹrẹ ipade pada lati yanju edeaiyede nla kan to da lori aawọ okoowo.












