Àwọn akẹ́kọ̀ọ́bìnrin méjì yí ṣé àgbéjáde ẹ̀rọ tó n sọ omi ìdọ̀tí dì mimọ̀
Ara meeriri, a ti ri ori ologbo lori atẹ.
Ara ti awọn oyinbo ko lee da,ọmọ akẹkọbinrin Naijiria meji yi ti da ti wọn si tun gba oṣuba kaare lori rẹ
Nkan ti awọn akẹkọọ taa n wi yi ṣe ni agbekalẹ ẹrọ kan to n pese omi mimu to mọ kedere latara omi idọti.
Ohun ti wọn ṣe yi mu anfaani wa lati ṣe afọmọ omi idọti lawọn agbegbe ti ipenija omi abuwẹ abumu ba wa ti irufẹ omi yi yoo si di mimọ nipasẹ ẹrọ ti wọn ṣe.
Nigba tawọn akẹkọọ meji yi n ṣalaye asiri ẹrọ naa fun ileesẹ BBC, ọkan ninu wọn salaye pe, ọna lati yọ awọn ọmọ Naijiria kuro ninu wahala omi mimu lo jẹ ki awọn ṣe agbekalẹ ẹrọ yi.
Orukọ awọn akẹkọọbinrin meji taa n wi yi si ni Elizabeth Korolo Boluwatife ati Abdulsalam Ajara.
Akẹkọọ ni wọn jẹ ni ile ẹkọ Wesley Girls Senior Secondary School.
Ile idana ni mo wa ti imisi fi wa lori agbekalẹ ẹrọ yi
Ile lọkan ninu awọn akẹkọọ yi wa ni agbegbe Makoko ni ipinlẹ Eko to si ni imisi wa si oun lọkan nipa agbekalẹ ẹrọ yi.
Elizabeth Ajara sọ pe ''Mo gbe omi lena ninu ile idana ni nigba ti mo woye bi omi naa 'se n ho. Ibẹ naa ni mo ti ro wi pe bi eruku omi ṣe n yọ sita labẹ ideri pọọti, bẹẹ mo le lo ọna yi lati sọ omi di mimọ nitori irufẹ eruku yi lo jẹ omi to mọ julọ.
Nipasẹ eyi lo sọ pe oun ati kẹgbẹ rẹ Abdulsalam Ajara bẹrẹ si ni ṣe iwadii ati igbiyanju eleyi to pada wa bi ẹrọ ti wọn pe orukọ rẹ ni Bithermal Water Distillation Device to n lo agbara oorun lati fi ṣe afọmọ omi idọti si eleyi to ṣe mu.
Awọn ọmọdebinrin naa sọ pe awọn lo awọn nkan to wa layika wọn bi eedu,iyepẹ ati awọn nkan mii tawn ṣa jọ.
Abdulsalam Ajara ni tiẹ ṣalaye pe didagba ni adugbo Makoko jẹ ki ounmọ pataki omi to ṣe bu mu nitori atiri omi jẹ ipenija nla lagbegbe naa.
''Omi lo yi wa ka ni Makoko ṣugbọn omi yi jẹ omi idọti ti ko ṣe bu mu.Ibi ni wn bi mi si ti o si jẹ ibi tawọn eeyan n da idọti silae bikita.Eleyi mu ki ipenija omi to ṣe mu jẹ nkan to n kan wa lominu ladugbo Makoko''

Igbiyanju wọn mu ami ẹyẹ ati idanimọ wa lagbaye
Ẹrọ alabọde Bi- Thermal Water Distillation Device tawọn akẹkọọ yi pese gbe wọn de ibi ọla nigba ti wọn kopa ninu idije kan ti wọn ṣaagbekalẹ rẹ fawọn akẹkọọ ti ọjọ ori wọn ko ju ọdun mẹẹdogun si ogun dun lọ.
Idije yi jẹ iyanju ṣiṣẹ agbekalẹ iwadii tabi ẹrọ ti yoo mu iyipada ba ayika ẹni.
Awọn mejeeji gba ipo kini ninu idije yi iyẹn Stockholm Junior Water Prize.
Ileeṣẹ Aṣoju orileede Sweden ni Naijiria ati awọn ajọ idagbasoke kan lo ṣagbatẹru eto yi.
















