Ọkọ̀ ojú irin tàsé ojú òpó rẹ̀, èèyàn 30 kú, 100 míì farapa

Aworan

Oríṣun àwòrán, AFP

O kere tan eniyan ọgbọn ti padanu ẹmi wọn, ti awọn eniyan to le ni ọgọrun un si farapa lẹyin ti ọkọ oju irin ya kuro ni ọna rẹ lorilẹede Pakistan.

Agbẹnusọ fun ileeṣẹ ọlọpaa ni agbegbe guusu orilẹede Pakistan lo fi idi iṣẹlẹ naa mulẹ.

Ọpọlọpọ ọkọ oju irin ti ileeṣẹ Hazara Express lo yi danu ni agbegbe Sahara Railway Starion ni Nawabshah, ti ko jina si ilu Karachi to tobi julọ lagbegbe naa.

Awọn to fi ara pa naa ni wọn gbe lọ si ileewosan, ti awọn oṣiṣẹ pajawiri si n ṣiṣẹ takuntakun lati doola ẹmi awọn eniyan ninu ọkọ oju irin to lọ naa.

Kii ṣe igba akọkọ ni yii ti ọkọ oju irin yoo maa da lulẹ ni orilẹede Pakistan.

Awọn fidio ti wọn fi si ori ẹrọ ayelujara ṣafihan ọgọọrọ eniyan nibi iṣẹlẹ naa, ti awọn arinrinajo kan si n bọ silẹ gba oju ferese ọkọ naa.

Awọn eeyan ti isẹlẹ naa soju wọn ni ọpọ eeyan lo jabọ silẹ lẹ, ti wọn si n ke irora

Ọkan lara awọn ero inu ọkọ naa to jajabọ ni oun ri awọn ọmọ ati obinrin ti wọn wa ni ilẹ.

‘’Awọn wọnyii n ke pẹlu irora, mi o si mọ nkan ti mo le ṣe, mo yara lọ pọn omi ninu canal ki n da si oju awọn eniyan to da bi ẹni pe wọn ko lee la oju wọn.

Nasser ni oun jajabọ ninu ọkọ oju irin naa nitori bi ọkọ naa ṣe ya kuro ni oju ọna rẹ bayii, ni oun fo jade gba oju ferese.

Ẹlomiran to sọ iriri rẹ ni oun pẹlu ọmọ oun ni awọn wa ninu ọkọ oju irin naa, ti awọn si n sun.

Laipẹ ni wọn ri ti ọkọ oju irin naa jabọ, to si dabi ẹni pe aye ti pare.

Aworan

Oríṣun àwòrán, AFP

O seese ko jẹ pe awọn eeyan laabi lọwọ ninu isẹlẹ ijamba naa - Ijọba

Minisita fun eto irinna oju irin, Saad Rafiq ni iwadii fihan pe ọkọ naa ko sare kọja bi o se yẹ.

Nitori naa ni wọn ti bẹrẹ iwadii ohun to fa bi ọkọ naa se ya kuro ni ọna rẹ.

Wọn ni o ṣeeṣe ko jẹ bi ọkọ naa yọnu tabi awọn eeyan laabi lọwọ ninu rẹ.

Amọ ijọba ti ni kii se pe oju ọna irin naa kun fun agbara ojo lẹyin ojo arọrọda.

Bakan naa lo ni awọn ikọ ọmọogun to fi mọ awọn ẹṣọ alaabo miran wa ni ibi iṣẹlẹ naa lati doola ẹmi awọn araalu.

Nibayii ijọba ti kede eto iwọsan pajawiri ni ileewosan Nawabshah ati agbegbe Sindh.

Bakan naa ni wọn ti fofin de eto irinna ni agbegbe Sindh nitori iṣẹlẹ naa.

Ni ọdun 2021, ọkọ oju irin meji to n rin irinajo ni agbegbe Sindh lo kọlu ara wọn, ti awọn eniyan to le ni ogoji si gbẹmi mi, ti ọpọ eniyan si farapa.

Laarin ọdun 2013 si ọdun 2019, eniyan 150 lo ti ku ninu awọn iṣẹlẹ bayii, bi ileeṣẹ iroyin labẹle ṣe gbe jade.