Yemoji River: Ejò Olúwẹri yóò yọ látinú odò sí ẹnikẹni tó bá jẹ èṣúrú

Àkọlé fídíò, Ìtàn odò Yemoji rèe, obìnrin arìnrìnàjò tó di odò tó ń sẹ àlááfíà fún aráàlú

N jẹ o nira fun ẹ lati sun daadaa tabi o n ni irora ara riro?

Se o ti gbọ nipa odo Yemoji ri to wa lagbegbe Ijebu Ode ati isẹ iwosan ti wọn lo n se?

Ọna lati fidi otitọ ọrọ yii mulẹ lo mu ki BBC Yorùbá dé ìlú Òdòlọfà, lágbègbè Ijebu Ode níbi tí odò Yemojì wà, ti a si gbọ́ nípa bí odò náà ṣe ṣẹ̀, èèwọ̀ rẹ àti ọpọ àǹfààní to n se fawọn eeyan agbegbe naa.

Awọn agbaagba ni ilu Odolọfa to ba BBC Yoruba sọrọ wa sapejuwe Odo Yemoji gẹgẹ bi odo alabiyamọ, eleyii ti o jẹ obinrin arinrinajo to di odo.

Ọja apapọ igberiko ni wọn pe ọja to wa lagbegbe odo naa wa, ti awọn eniyan lati Sagamu, Ijebu-Ode yoo si pejọ lati na ọja nibẹ.

Nitori omi to ṣọwọn nigba naa ti awọn araalu a si rin ọpọlọpọ maili lati wa omi kan, ti awọn araalu si n ke gbajare nipa rẹ.

Asiko yii si jẹ asiko ti arabinrin Yemoji yii rin irinajo wa si ilu naa, to si beere omi, amọ ko si ẹni to lee fun nitori wọn ko ni.

Lẹyin naa ni obinrin naa wọlẹ ni agbegbe Ijebu-Ode, to si di odo nla ti awọn oyinbo ti ma n gba afẹ, ti awọn araalu si n na ọja nibẹ nigba naa lọhun.

Ẹ wo fidio naa fun ẹkunrẹrẹ nipa omi abalaye yii, ti awọn eniyan n bọ ni ọdọọdun ati idi ti ejo se n yọ si ẹnikẹni t5o ba jẹ eewọ.