Olùkọ́ ẹni ọdún 86 ń kojú ẹ̀wọ̀n ọdún 600 nítorí aṣemáṣe pẹ̀lú akẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀

Oríṣun àwòrán, Twiiter/@NouvellesA1
Obirin ẹni ọdun mẹ́rìnléláàdọ́rin kan to ti fi akoko igba kan jẹ olukọ ri ti jẹbi ẹsun ṣiṣe aṣemaṣe pẹlu akẹkọọ rẹ to jẹ ọmọ ọdun mẹrinla pere.
Iroyin ni o ṣeeṣe ki obinrin naa ri ẹwọn ti iye ọdun rẹ to ẹgbẹta he lẹyin idajọ rẹ.
Olukọ tẹlẹri ọhun, Anne N. Nelson-Koch jẹbi gbogbo ẹsun marundinlọgbọn ti wọn fi kan an niluu Wisconsin, nilẹ Amẹrika.
A gbọ pe Nelson-Koch, to jẹ olukọ nile ẹkọ aladani kan maa n ba ọmọ naa ṣe aṣemaṣe ninu kọrọkọndu kan nile ẹkọ naa laarin ọdun 2016 si 2017.
Eni ọdun mẹrinlaadọrin ni olukọ naa, nigba ti akẹkọọ naa jẹ ọmọ ọdun mẹrinla lasiko ti ibaṣepọ wọn ọhun waye.
Odidi ọjọ mẹta gbako ni igbimọ awọn adajọ fi jiroro lori ẹsun aṣemaṣe naa, ki wọn to fẹnuko pe o jẹbi.
Ọkan lara awọn agbẹjọro to da si igbẹjọ ọhun, Sarah M. Skiles ni “akinkanju ni ọmọkunrin ti olukọ yii ṣe aṣemaṣe pẹlu.”
“O sọ ododo bi ọrọ naa ṣe jẹ niwaju awọn adajọ, ọrọ rẹ si ye wọn, inu wa dun si afojusun awọn adajọ ọhun lati ṣe iwadii ododo ọrọ naa.”
Skiles rọ ile ẹjọ ọhun lati fi ọdanra naa si ahamọ titi ti wọn yoo fi ṣe idajọ rẹ, amọ adajọ Richard Radcliffe fi ni ko maa lọ ile rẹ.
Amọ ile ẹjọ so ẹrọ GPS ti yoo maa sọ ibi to wa ni gbogbo igba mọ lara titi ti wọn yoo fi ṣe idajọ rẹ ti yoo waye lọjọ kẹtadinlọgbọ, oṣu Kẹwaa, ọdun yii.
Agbẹjọro agbegbe Monroe ti igbẹjọ naa ti waye, Kevin Croninger sọ pe o ṣeeṣe ki ye akoko ti olukọ naa yoo lo lọgba ẹwọn to ẹgbẹta ọdun.












