Osun Osogbo festival: Ọdún Osun gbìnàyá, t'onílé t'àlejò péjú fún ẹ̀bl àdúrà

Ojubọ Osun Osogbo

Oni ọjọ kẹtala oṣu kẹjọ ọdun ni aṣekagba ọdun Osun Osogbo ti ọdun 2021 yii to waye ni ilu Osogbo, nipinlẹ Osun.

Gbajugbaja ni ojubọ oriṣa Ọṣun nilẹ Yoruba, ati kaakiri agbaye fun awọn to jẹ olufọkansin fun oriṣa naa.

Ilu Oṣogbo nipinlẹ Ọṣun ni igbo Ọṣun-Oṣogbo naa wa, ni agbegbe Eti Oso Ọṣun.

Niṣe lawọn oloriṣa Osun ro dẹdẹ kan dudu, aṣọ funfun balau ni ọpọ wọn wọ pẹlu ẹgba lọrun.

Bawọn obinrin ṣe ro iro aṣọ funfun lawọn ọkunrin naa ro aṣọ funfun, koda fila funfun ni wọn de pẹlu ilẹkẹ funfun lọrun.

Awọn oloriṣa Osun

Wamu wamu lawọn ọlọpaa duro lati ri pe abo wa fun awọn oloriṣa Osun to n sẹ ọdun.

Ọgọọrọ eeyan ti wọn wa lati ilẹ okeere atawọn to wa lorilẹede Naijiria lo peju pesẹ sibi ayẹyẹ ọdun Osun yii.

Awọn oloriṣa Osun

Awọn onimọ nipa ẹsin abalaye ni Naijiria sọ pe o ti le ni nkan bi ẹẹdẹgbẹrin ọdun ti awọn alaalẹ to tẹ ilu Osogbo do, ti bẹrẹ sii ṣe ọdun Osun Osogbo.

Ọdẹ nla kan, Olutimẹhin, lo jẹ adari awọn eeyan kan to n wa ọna abayọ si iyan to mu nibi ti wọn tẹdo si tẹlẹ.

Awọn ọlọpaa nibi ayẹyẹ Osun Osogbo

Erongba wọn ni lati kọ ile ti wọn o maa gbe si eti odo Osun, ṣugbọn bi wọn ṣe bẹrẹ si ni ge awọn igi to wa nibẹ, itan sọ pe oriṣa odo naa, Osun, pariwo jade si wọn, o si le wọn kuro nibẹ.

Lẹyin naa lo sọ fun ẹni to dari awọn eeyan naa, Olutimehin, pe ko ko awọn eeyan rẹ lọ si ibi pataki kan (to di ilu Osogbo).

Osun ṣeleri lati daabo bo wọn, ti yoo si fun wọn ni ọrọ pupọ. Kikii pe ki wọn ma a fun un ni ẹbọ lọdọọdun.

Awọn eeyan naa gba lati maa ṣe bẹẹ. Ẹbọ ti wọn ma n fun un, lodi ọdun Osun Osogbo to n waye lọdọọdun bayii.

Awọn oloriṣa Osun

Lati igba naa si ni ibẹ ti di igbo mimọ nibi ti awọn olujọsin ti n korajọ lati sin jọsin fun.

Ohun si ni igbo oriṣa to tobi julọ titi di ode oni ni ilẹ Yoruba.

Lati mu ẹjẹ ti awọn to tẹ ilu Oṣogbo do, ṣe fun oriṣa Ọsun ṣẹ, wọn bẹrẹ si ni ṣe ọdun irubọ fun un ni ọdọọdun.

Ọsẹ meji gbako ni ayẹyẹ ọdun Osun-Osogbo fi ma n waye.

Bi eto ọdun Ọṣun-Oṣogbo ṣe ma n lọ