Sunday Igboho: DSS fẹ́ gbọ̀nà ẹ̀bùrú yọ lórí béèlì àwọn méjìlá tí wọ́n mú nílé Sunday Igboho, àgbẹjọ́rò wọn ní ere ọmọdé ni wọ́n ńṣe

Oríṣun àwòrán, others
Agbẹjọro fun awọn eeyan mejila ti awọn agbofinro DSS mu nile oloye Sunday Igboho ti kọminu lori iwe ẹjọ ti ileeṣẹ agbofinro DSS tun kọ sile ẹjs lati tako beeli ti wọn fun wọn.
Ni ilu Ibadan ni awọn agbofinro DSS ti ko awọn eeyan naa lasiko ti wọn kọlu ile oloye Sunday Igboho loru ọjọ keji oṣu keje ọdun 2021. Eeyan meji lo ku lasiko ikọlu naa.
Ni ọjọ kẹrin oṣu kẹjọ ọdun 2021 ni ile ẹjọ giga apapọ kan nilu Abuja gba beeli wọn.
Awọn eeyan naa ṣi wa lahamọ awọn agbofinro DSS lẹyin ti awọn agbẹjọro wọn ko tii ri ọrọ gbendeke beeli wọn yanju.
Yiyanju beeli naa n lọ lọwọ lawọn DSS ba tun gbe iwe ipẹjọ tako beeli naa dide eyi ti ọkan lara awọn agbẹjọro wọn, Pẹlumi Ọlajẹngbesi ṣapejuwe gẹgẹ bi ohun to ṣajeji to si tumọ si aṣilo ilana igbẹjọ.
O ni ohun to ṣe ajeji si ofin ilẹẹwa ni igbesẹ naa.
Ninu ọrọ to ba ileeṣẹ iroyin Premium Times sọ ni Ọjọru, amofin Ọlajẹngbesi ni titi di bi a ṣe n sọrọ yii ko ti si ẹsun kankan ti wọn ka si awọn eeyan naa lẹsẹ, sibẹ wọn n fẹ ki ile ẹjọ o yi ọrọ rẹ pada lori beeli to fun wọn lori ero wọn pe awọn n bọ wa pẹjọ.
Ohun ti DSS pe ẹjọ tako ni beeli awọn mẹrin ninu awọn mejila naa ti orukọ wọn n jẹ Amudat Babatunde, Abuideen Shittu, Jamiu Oyetunji ati Bamidele Sunday.
Onidajọ Obiora Egwuatu, ninu idajọ rẹ gba beeli awọn eeyan mejila naa to si wọgile ipe ti amofin DSS pe tako beeli awọn mẹrin naa.













