Osun Osogbo festival: Wo iná olójú mẹ́rìndínlógún, arugbá àtàwọn ohun míì tí yóò wáyé l'Ọdún Osun Osogbo 2021

Osun Osogbo Festival

Oríṣun àwòrán, Negrohood

Yoruba ni ọdọọdún là ń rí awusa, ọdọọdún là ń rí orogbo, kii yẹ bí ọdún Osun Osogbo, kárí ilé kárí oko sì ni ìròyìn rẹ máa ń kan ká.

Ayẹyẹ ọdún Osun Osogbo tí ọdun yìí tún ti gberasọ tohun ti iyi to máa ń mú dání.

Wiwẹ ìlú mọ lọ kọ́kọ́ fi ṣide tí ọdun yìí, èyí tí wọn ń pè ní "Ìwọpopo" tí wọn máa fi ń bẹ̀rẹ̀ bíbọ yemoja odò Oṣun lọdọọdún.

Ataoja ti ilu Osogbo, Kabiyesi Ọba Jimoh, Oyè Tunji (Olaonipekun Laaroye II) lo dárí àwọn ìgbìmò Ìwọpopo, àwọn Oloye, àwọn olùjọsìn, aṣojú ijọba àtàwọn olùgbé ìlú Osogbo nínú ìlànà ṣíṣe wiwẹ ìlú mọ gẹ́gẹ́ bí wọn ṣe rìn ja àwọn pooro àti ona kan ni ilu ja ni ìsòrí ìsòrí, lomode àti lagba láti lọ ṣe Kabiyesi Ataoja to joko si aarin gbùngbùn ìlú.

Àkọlé fídíò, Esabod, Sunday Igboho: Kò burú bí Igboho ṣe wà lẹ́wọ̀n báyìí,ọ̀rọ̀ rẹ̀ dàbí i ti aláboyún

Pẹlu ọpọ ìjọ àti ilu, gbogbo ìlú lọ ń hó fún idunu fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ wákàtí gẹgẹ bí àwọn aráàlú ṣe tú jáde kẹti kẹti láti side ayẹyẹ ọdún ńlá yìí laarin gbogbo ọdún ní ilè Yoruba.

Àkọlé fídíò, Ọmọ Ìjọ Deeper Life Pọ́ńbélé ni ìyà mi àti bàbá mi, mo sì dàgbà síbẹ̀ àmọ́ bíbọ Èṣù ọ̀dàrà lọ́nà tó tọ́ -

Àwọn ètò míì tó ti wà níkalẹ tí yóò wáyé nìbi ayẹyẹ ọdún Oṣun Osogbo tí ọdun yìí ni:

  • Titan "iná olójú mẹ́rìndínlógún" to tí lo eedegbeta ọdún laye èyí tí yóò wáyé ní Ọjọbọ ọjọ́ Kàrún oṣù kẹjọ.
Àkọlé fídíò, Bí ìjọba bá kọ̀ tí kò ṣèdájọ́, tí Ọlọ́pàá kọ̀ pé àwọn kọ́ ló paá, ẹni tó pa ọmọ mi, náà máa ...
  • Iboriade - eyi ni akojopo àti àfihàn gbogbo adé àwọn Ọba Ataoja Osogbo tó ti je lateyin wa fún ṣíṣe àdúrà èyí tí yóò wáyé lọ́jọ́ Kẹ̀sán oṣù kẹjọ.

Pabanbari asekagba ọdún náà èyí tí wọn safihan rẹ lórí ayélujára fún gbogbo agbaye yoo waye ni ọjọ kẹtàlá oṣù kẹjọ, ohun si ni ọjọ bí ó odò Oṣun èyí tí Arugba Oṣun yóò lọ rúbọ ní Odò isembaye ti Oṣun Osogbo.

Àkọlé fídíò, Igi Ọ̀pẹ abàmì tó dá ní orí 42 l'Ekiti rèé o, 'bí mo ṣe ríi l'orí mi ń dìde fììì'