Wo kókó ìgbésẹ̀ méje tí ìjọba Eko gbé jáde lórí ikú dókítà tí Elevator pa

Dokita Vwaere Diaso

Oríṣun àwòrán, EDIDIONG IKPE

Ijọba ipinlẹ Eko ti gbe abọ iwadii rẹ jade lori iṣẹlẹ akasọ igbalode ‘elevator’ to gba ẹmi dokita kan nipinlẹ naa ni ọsẹ to kọja.

Ninu atẹjade kan to fi sita ni alẹ ọjọ Aiku loju opo ayelujara Twitter rẹ, ijọba ọ pe oun kabamọ iku dokita naa, Vwaere Diaso, to ku ni ileewosan gbogboogbo to wa ni Odan, Lagos Island, lọjọ kinni, oṣu Kẹjọ.

Lẹyin iku dokita naa, eyi to fa awuyewuye ati iwọde laarin awọn akẹgbẹ rẹ, ni ijọba ipinlẹ Eko kede pe oun ti gbe igbimọ kan kalẹ lati wadii ohun to ṣokunfa bi elevator naa ṣe ja lulẹ, ati awọn to ni ẹbi rẹ.

Ọjọ Satide ni igbimọ naa gbe abọ iwadii rẹ fun ijọba.

Ninu alaye to ṣe ninu atẹjade to fi sita, ijọba ni ileeṣẹ aladani kan ni oun gbe iṣẹ agbaṣe fun lati ma a ṣe amojuto ati itọju ileegbe awọn dokita naa.

O ni labẹ idari ileeṣẹ to n mojuto awọn dukia ijọba ipinlẹ Eko, he Lagos State Infrastructure and Asset Management Agency (LASIAMA) si ni isẹ naa wa.

Awọn nnkan to wa ninu abọ iwadii igbimọ

Ilegbee awọn dokita ni General Hospital, Odan, nibi ti ijamba naa ti waye
Àkọlé àwòrán, Ilegbee awọn dokita ni General Hospital, Odan, nibi ti ijamba naa ti waye

"Ọdun 2021 la ri elevator tuntun to ja"

  • Ni bii aago meje ku iṣẹju mẹwaa alẹ ni iṣẹlẹ naa waye. Wọn ni nitori jija lulẹ ti elevator naa ja, awọn ilẹkun rẹ bajẹ eyi to mu ko ṣoro diẹ lati ṣi ilẹkun naa lati doola dokita to ha sinu rẹ.
  • Ni bii aago mẹjọ alẹ ku iṣẹju mẹwaa ni wọn to ri dokita naa gbe jade, ti iṣẹ idoola ẹmi rẹ si bẹrẹ loju ẹsẹ.
  • Wọn gbe e lọ si yaara itọju pajawiri, nibi ti awọn dokita ti bẹrẹ iṣẹ pẹlu idari agba dokita kan to mọ nipa egungun ara. Wọn ni awọn nnkan ti wọn kọkọ mojuto ni lati ri i daju pe ọna eemi rẹ ko di pa, ko le raaye mi daadaa.
  • Gbogbo igbiyanju wọn lati doola ẹmi Dokita Diaso lo ja si ofo, nitori pe ni aago mẹjọ alẹ kọja iṣẹju mẹtala lo mi eemi ikẹyin.
  • Wọn tun gbiyanju lati wo o boya o le laju saye pada nipa ṣiṣe Cardio Pulmonary Resuscitation (CPR) fun un titi di aago mẹsan-an ku iṣẹju kan, amọ ẹpa ko boro mọ.

Ijọba ipinlẹ Eko sọ pe ko si otitọ ninu ẹsun ti awọn eeyan kan fi kan ileewosan naa pe wọn ko ri ẹjẹ fun oloogbe naa.

Wọn ni ijọba ni ọpọ ibudo to n ko ẹjẹ si, ati ọpọ awọn eeyan to ma n fi ẹjẹ silẹ nigbakugba ti wọn ba pe wọn.

Yatọ si eyi, ijọba tun ṣalaye pe ọdun 2021 ni wọn ri elevator tuntun naa.

Ati pe awọn akọṣẹmọṣẹto n ṣiṣẹ pẹlu ijọba ipinlẹ Eko yoo ṣe ayẹwo ohun to fa a ti gbogbo irinṣẹ idaabo bo to wa lara rẹ ṣe bajẹ lẹẹkan naa.

Wọn ni abọ iwadii wọn ni yoo sọ boya wọn yoo ba ileeṣẹ to ri i ṣe ẹjọ.

Awọn igbesẹ ti ijọba fẹ ẹ gbe bayii

Lẹyin abajade iwadii igbimọ to gbe kalẹ, ijọba ipinlẹ Eko sọ pe oun ti gbe awọn igbesẹ wọn yii:

O ti da ileeṣẹ to n mojuto ile naa duro

Ọga agba ajọ LASIAMA ti gba iwe idaduro ọlọjọ diẹ

Wọn ti gbe aṣẹ fun awọn alakoso ileewosan naa lati ma a tọpinpin ileeṣẹ to n mojuto ilegbe naa

Ijọba ti fa ileeṣẹ to ri elevator naa, ati eyi to n ṣe amojuto igbadegba rẹ, le ọlọpaa lọwọ fun iwadii. Wọn o si gbe wọn lọ sile ẹjọ ti iwadii ba fihan pe wọn jẹbi. Ileeṣẹ ọlọpaa yoo tun wadii ẹnikẹni to ba ṣeeṣe ko lọwọ ninu iṣẹlẹ naa.

Ijọba sọ pe gbogbo awọn oṣiṣẹ oun ni oun ṣe eto adojutofo ẹmi fun - o si ti kàn si ileeṣẹ adojutofo ẹmi lori iṣẹlẹ naa.

Ta ni Dokita Vwaere Diaso?

Dokita Vwaere Diaso jẹ dokita onisegun oyinbo nto n gba ẹkọ ni ile wosan General ni Odan nipinlẹ Eko ki ọlọjọ to de lọjọ kinni oṣu kẹjọ, ọdun 2023.

Dokoita Diaso lo pari ni ile ẹkọ ninu oṣu keji ọdun 2022.

Gẹgẹ bi ọrẹ rẹ, Edidiong Ikpe se sọ, Diaso lo jẹ agbabọọlu apẹẹrẹ, ti wọn si kopa lasiko ti wọn wa ni fasiti Babcock

Ikpe lori ayẹlujara sapejuwe ọrẹ rẹ gẹgẹ ọmọ ti gbogbo obi fẹ ni