Ọwọ́ ọlọ́pàá tẹ ọkùnrin tó gbé agbárí èèyàn sínú ilé nílùú Ondo, ariwo sọ

Funmi Odunlami

Ọwọ awọn ọtẹlẹmuyẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo ti tẹ afurasi ẹni ọdun mẹrindinlọgbọn kan ti wọn ba agbari eeyan ninu ṣọọbu rẹ.

Afurasi ọhun, ti wọn pe orukọ rẹ ni Franklin Akinyosuyi, ti wa lahamọ ọlọpaa bayii fun ifọrọwanilẹnuwo.

Iroyin ni inu ọra dudu kan ni agbari eeyan naa wa, nibi ti awọn ọmọ onile afurasi naa ti ri ṣaaju, ki wọn to ke gbajare sita, eyii to mu ki baba onile naa fi to ọlọpaa leti.

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo ti fidi iṣẹlẹ naa mulẹ.

A gbọ pe nigba ti awọn ọlọpaa yoo fi de ile naa, wọn ṣawari awọn nnkan abami miran bii ẹya ara eeyan atawọn oogun abẹnu gọngọ nibẹ.

Nigba ti ọlọpaa bere lọwọ rẹ bi awọn nnkan ti wọn ba nile rẹ ṣe jẹ, o ni oun loun ni awọn nnkan naa, baba onile oun ko si mọ nnkankan nipa rẹ.

Ninu ọrọ ti alukoro ileeṣe ọlọpaa ipinlẹ Ondo, Funmi Odunlami-Omisanya, fi ṣọwọ si awọn akọroyin, o ni iṣẹ ayaworan ni afurasi naa sọ pe oun n ṣe.

O ni “Ọkunrin kan, Franklin Akinyosuyi, to pe ara rẹ ni ayaworan, to tun ni ile itaja aṣọ igbalode ni baba onile rẹ bere eredi to fi gbe baagi dudu kan si kọrọ ile naa.”

“Baba onile naa bẹrẹ si n fura si, o si sọ fun pe ko ṣi baagi naa.”

“Nigba ti yoo fi ṣi baagi naa, agbari eeyan lo wa nibẹ.”

“Lẹyin ti ọwọ ọlọpaa tẹ afurasi naa tan, o sọ pe babalawo kan lo gbe ori eeyan naa fun oun nipinlẹ Osun lati ṣe aajo fun itẹsiwaju owo ti oun n ṣe.”

Odunlami-Omisanyan pari ọrọ rẹ pe “Iwadii ti n lọwọ, a si ti fi afurasi ọhun ti ahamọ.”