Irọ̀ ni pé mo dọ̀bálẹ̀ fún Makinde níbi ìpàdé tí a ṣe - Adeleke

Oríṣun àwòrán, @amakinde
Agbẹnusọ fun gomina ipinlẹ Osun, Olawale Rasheed ti sọ pe irọ patapata ni iroyin to n lọ pe Gomina Ademola Adeleke dọbalẹ bẹ akẹẹgbẹ rẹ nipinlẹ Oyo, Seyi Makinde laipẹ yii.
Ọgbẹni olawale sọ pe awọn ọrọ to ni i ṣe pẹlu ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party ni ẹkun Iwọ-oorun Naijiria, ni ọga oun ati Makinde jiroro le lori nibi ipade wọn naa to waye ni ọsẹ to kọja.
O ni “Adeleke lọ si ile ijọba ipinlẹ Oyo to wa niluu Abuja, lati wo atunṣe to n lọ lọwọ lara ile naa, nitori pe ipinlẹ Osun naa n gbereo lati sẹ atunṣe ile ti ẹ naa.
“Gomina kan lo anfaani naa lati jiroro lori awọn nnkan to nii ṣe pẹlu PDP pẹlu Makinde ni.”
“Ko si igba kankan ti awọn gomina mejeeji ṣe ipade ni kọọrọ, ojutaye ni wọn ti sọ gbogbo nnkan ti wọn sọ.
Olawale tẹsiwaju ninu ọrọ rẹ pe lara nnkan ti wọn jiroro le lori ni bi wọn yoo ṣe yan awọn eeyan si awọn ipo adari ẹgbẹ oṣelu naa to ṣofo ni ẹkun wọn.
Bakan naa lo tun ni awọn gomina mejeeji ọhun tun jiroro lori ọna ti wọn yoo gba lati ro PDP lagbara ni ẹkun Iwọ-oorun gusu.
“Ko si igba kankan ti awọn gomina mejeeji ṣe ipade ni kọọrọ, ojutaye ni wọn ti sọ gbogbo nnkan ti wọn sọ.
“Ko si si igba kankan ti ọrọ ẹbẹ tabi didọbalẹ waye nitori ko si ohunkohun lati bẹbẹ fun.”
O wa a rọ gbogbo awọn ọmọ ẹgbẹ osẹlu PDP ni Iwọ-oorun gusu lati ma fi eti si iroyin naa, dipo bẹẹ ki wọn o gbajumọ aṣeyọri ipade wọn to n bọ lọna fun anfaani ẹgbẹ.
Makinde kéde oúnjẹ ọ̀fẹ́, ọkọ̀ ọ̀fẹ́, àti àwọn ìdẹ̀rùn mìí fún aráàlú nínú ètò ‘Safer Package’

Oríṣun àwòrán, Other
Gomina ipinlẹ Oyo, Seyi Makinde ti sọrọ lori awọn ọna ti ijọba rẹ yoo gba mu igbeaye idẹrun ba awọn eniyan ipinlẹ naa ni asiko yii.
Ninu ọrọ to ba awọn eniyan ipinlẹ naa sọ ni ọjọ Abamẹta lori ileeṣẹ agbohunsafẹfẹ ipinlẹ Oyo, BCOS, Gomina Makinde sọ pe ijọba oun ti gbe ilana kan to pe ni ‘Safer Package’ kalẹ lati mu itura ba araalu.
Lara awọn nnkan to ni ijọba yoo sẹ niyii:
Ijọba yoo ṣe afikun akọsilẹ iye awọn eniyan to kudiẹ kaato fun ni awujọ,eyi to lo lasiko ajakalẹ aarun Covid-19. Akọsilẹ eeyan ẹgbẹrun lọna igba eeyan ti nnkan buru fun jai. Ijọba yoo pese awọn nnkan ti ẹnu n jẹ fun awọn eeyan naa. O ni ijọba yoo ri daju pe akoyawọ wa ninu ilana ti wọn yoo gba pin awọn ounjẹ naa lati ri daju pe awọn to tọ si nikan lo gba a.
Ijọba yoo san owo adojutofo ilera fun ẹgbẹrun lọna ọgọrun awọn arugbo fun ọdun kan, labẹ eto adojutofo ilera ti ipinlẹ Oyo ki wọn le ni anfaani si eto ilera to peye lai san owo kankan.
Ọkọ ijọba, Omi Tuntun Bus Service, yoo bẹrẹ si ni ko ero lati ilu Ibadan si awọn ẹkun miran yika ipinlẹ Oyo, ni owo ti ko ga ju ara lọ rara.
Ijọba yoo ko irugbin fun ẹgbẹrun mẹwaa agbẹ. Bakan naa ni ijọba yoo pese ẹẹdẹgbẹta miliọnu Naira lati fi ran awọn ọdọ to n ṣiṣẹ agbẹ lọwọ
Miliọnu lọna ẹẹdẹgbẹta Naira lati ya awọn oniṣowo pẹlu ele ti ko pọ, nipasẹ awọn banki ayanilowo ti ijọba fi ọwọ si.
'Ẹgbẹ NLC àti TUC kò ní ẹ̀tọ́ láti ti ìlẹ̀kùn mọ́ àwọn òṣìṣẹ́ wa'
Lori ọrọ iwọde ti ẹgbẹ oṣiṣẹ, NLC ati TUC n ṣe niluu ibadan lati ọsẹ to kọja, Gomina Makinde sọ pe ẹgbẹ naa ko ni ẹtọ lati di ọna mọ awọn oṣiṣẹ ijọba ipinlẹ naa ki wọn o ma wọ inu ọgba ileeṣẹ ijọba lati ṣe iṣẹ wọn.
O ni ibọde ni igbesẹ yoowu to ba pagidina eto ọrọ aje ipinlẹ Oyo, ti ko fi bẹẹ duro daada, jẹ́.
O ni oun ti paṣẹ fun awọn oṣiṣẹ alaabo lati ri i daju pe awọn oṣiṣẹ ijọba n ni anfaani lati wọle si ibi iṣẹ wọn, bẹrẹ lati ọjọ Aje, ọjọ keje, oṣu Kẹjọ.
Bakan naa lo ni oun paṣẹ fun gbogbo oṣiṣẹ lati pada si ẹnu iṣẹ wọn.
“ A gba awọn olori ẹgbẹ oṣiṣẹ ni imọran lati pada si ijiroro lori afikun owo oṣu ti wọn ba n fẹ.”
O ni nitori pe owo ti ijọba ipinlẹ Oyo n pa wọle ni oṣooṣu ko ju biliọnu mẹwaa Naira lọ, “yoo ṣoro lati ṣe afikun owo oṣu tabi owo ifẹhinti lasiko yii.”
Ètò ìdẹ̀rùn fún àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba
Lati mu ki ara dẹ awọn oṣiṣẹ, Gomina Makinde sọ pe ijọba yoo fi kun awọn ọkọ bọọsi to n ko awọn oṣiṣẹ lọ si ibi iṣẹ wọn ati pada si ile lati mẹsan-an si mejila.
Ijọba yoo san owo alajẹṣẹku to yọ fun oṣu meji pada pẹlu owo oṣu Kẹjọ. O ni funra awọn oṣiṣẹ to ba fẹ tẹsiwaju lati ma a da owo alajẹṣẹku ni yoo tọ ajọ to n mojuto lọ, nitori pe ijọba ipinlẹ Oyo yoo dẹkun lati ma a ba wọn yọ owo naa lara owo oṣu.
Ijọba yoo san owo adojutofo ilera fun awọn oṣiṣẹ fẹhinti, ti yoo si da owo pada fun awọn to ba ti san owo naa funra wọn.
O ni igbagbọ oun ni pe ọrọ aje ipinlẹ Oyo yoo pada sipo nigba ti awọn eto amayedẹrun ‘Safer Package’ ba bẹrẹ l’ọsẹ diẹ si asiko yii.
Gomina Seyi Makinde sọ pe awọn ileeṣẹ ijọba ati ajọ ti yoo mojuto abala kọọkan ninu eto idẹrun naa yoo kede ọna ti wọn yoo gbe e gba laipẹ.













