Àgbà òṣèré tó rọpá, rọsẹ̀ bẹ̀bẹ̀ fún àánú, Saheed Osupa dìde ìrànwọ́

Oríṣun àwòrán, Collage
Gbajugbaja olori Fuji, Saheed Osupa tí na ọwọ oore sì agba oṣere kan, Baba Bankefa, to ni ipenija aarun rọparọsẹ.
Saaju ni fọnran aworan kan jade lori ayelujara níbi Baba naa ti n kesi gbogbo ọmọ Naijiria paapa awọn akẹgbẹ rẹ ninu ere tiata lati se iranlọwọ fun un.
Ninu fọnran ọhun, Bankefa salaye bí isẹ kan to fẹ gbe síta ṣe poora, eyi to fa gbese si lẹsẹ, to fi wa pada rọlapa rọlẹsẹ.
O ni ipenija ọhun ni ko fi aye gba oun mọ lati le pese owo fun ile ẹkọ awọn ọmọ oun ati ìlera oun lapapọ.
"Mo ti kan si gbogbo awọn akẹgbẹ mi sugbọn n ko ri nnkan"
Ninu fidio naa, Baba Bankefa ni lati igba ti oun ti ni ipenija ni oun ti kan si awọn akẹgbẹ oun bii Funke Akindele, Eniola Badmus, Foluke Daramola, Lizzy Anjorin ati Funke Etti.
O ni bakan naa ni oun kan sì àwọn olorin Fuji, Pasuma ati Saheed Osupa sugbọn oun ko ri esi pada.
"Ere tiata ti mo fẹ gbe jade lo ko mi si gbese, to si fa rọparọsẹ si mi lara. Gbogbo dukia ni mo padanu ti ko sisi nnkan mọ.
"Awọn ọmọ mi ko le lọ ile ẹkọ mọ. Mo ti ransẹ si Saheed Osupa, Pasuma, Eniola Badmus ati awọn miiran sugbọn wọn ko da mi lohun."
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post
Osupa fi 500k ransẹ Baba Bankefa
Gẹgẹ bii Temilola Sobola ṣe gbe jade lori opo ayelujara instagram, Saheed Osupa kan si, to si fi owo ransẹ si Baba Bankefa.
"Lana mo gbe fọnran osere tiata Bankefa jade to tí n sunkun, to si n tọrọ iranlọwọ lọwọ awọn akẹgbẹ rẹ lia gba esi
"Ní owurọ oni, Saheed Osupa kan sì mi, o si beere nọmba apo owo Bankefa.
O fun ni N500,000. Adupẹ gan an lọwọ Saheed Osupa fun nnkan to ṣe "

Oríṣun àwòrán, instagram.com/temilolasobol















