Àṣírí ọ̀pọ̀ Alfa ‘oníwòsàn ẹ̀mí’ tó ń pa irọ́ mọ́ àlùjọ̀nú láti fipá bá obìnrin lòpọ̀ tú

Alfa ati obinrin musulumi kan

Iwadii ọtẹlẹmuyẹ BBC kan ti tu aṣiri awọn alfa oniwosan ẹmi kan to n fi ọna ẹtọ ni ibalopọ pẹlu awọn obinrin.

Ẹka wa, BBC Arabic lo tu iṣu de isalẹ ọrọ iwa buruku yii.

Kaakiri lawọn ilẹ musulumi ni iṣẹ jalabi yii ti gbalẹ.

Lọpọ igba, awọn obinrin lo maa n ṣe ayẹwo lọdọ awọn onijalabi yii, ti wọn si nigbagbọ pe wọn le ba wọn ṣẹgun àárẹ̀ nipa lilo alujọnu.

Laarin ọdun kan gbako, la fi gba ọrọ lẹnu awọn obinrin marundinlaadọrun to naka aleebu si awọn onijalabi iru rẹ marundinlaadọrin ni Sudan ati Morocco.

Iru iṣeṣi yii wọpọ lorileede mejeeji naa, ti ifipabanilopọ ati ihalẹ ibalopọ wa lara ẹsun ti wọn fi n kan awọn alufa onijalabi nibẹ.

Bakanna ni akọroyin wa lo ọpọ oṣu lati fi gba ọrọ lẹnu awọn ajọ ẹlẹyinju aanu, ile ẹjọ, agbẹjọro ati awọn obinrin lọna ati fi ẹsẹ iwadii yii rinlẹ.

Koda akọroyin wa fara kaasa nigba ti ọkan ninu awọn Alfa yii bẹrẹ si ni fọwọ pa a lara.

Akọroyin wa ni lati fẹsẹ fẹẹ ni.

Ikilọ pataki: O ṣeeṣe ki awọn nkan ti ẹ o ba pade ninu apilẹkọ yii jẹ nkan to kani laya.

Aworan afihan obinrin musulumi

Oríṣun àwòrán, Getty Images

"Onijalabi fipa ba mi lopọ, o parọ pe alujọnu lo fun mi loyun"

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Dalal (kii ṣe orukọ gan ree) tọ alufa oniwosan ẹmi kan lọ lọdun meloo kan sẹyin nigba to wa ni nkan bi ogun ọdun lọna ati wa ojutu si irẹwẹsi ọkan to n daamu rẹ.

Alufa yii wa ni ilu kan ti ko jina pupọ si Casablanca.

O ni alufa naa sọ fun oun pe alujọnu kan to jẹ ọrẹkunrin oun, lo n da oun laamu.

Lasiko to wa lọdọ rẹ, o ni alufa ọhun ni ki oun fin turari kan simu, ti eyi si kun oun loorun.

Dalal ni oun pada fura pe turari lasan kọ, bi kii ṣe oogun lati fi kun oun loorun.

Dalal, ti ko tii mọ ọkunrin nigba naa sọ pe, oun taji lati ri wi pe wọn ti bọ pata nidi oun.

Nigba naa lo to mọ wi pe wọn ti fipa ba oun lopọ.

O ni oun bẹrẹ si ni pariwo mọ onijalabi naa pe iru ki lo danwo yii?

''Ha! Ki lo de to fi ṣe iru nkan bayii fun mi?''

Esi ti alufa naa fọ pada ni pe ''Ki alujọnu ba a le kuro lara rẹ ni mo fi ṣe''

Dalal ni oun ko sọ fun ẹnikankan amọ o ni niṣe loju n ti oun, to si da oun loju pe oun lawọn eeyan yoo da lẹbi.

Lẹyin ọsẹ meloo kan, o loun ri wi pe oyun ti duro lara oun.

O buru debi pe o ni oun fẹ gbẹmi ara oun nitori idojuti.

Nigba to sọ ọrọ oyun yii fun Alfa taa n wi yi, o ni Alfa naa ni o ṣeeṣe ko jẹ pe alujọnu lo fun oun loyun.

Ọrọ yii ko iporuru ọkan ba Dalal.

Nigba ti o pada bimọ, o ni oun ko le boju wo tabi fọwọ kan ọmọ naa.

O pada gbe ọmọ naa tọrọ fawọn alagbatọ ni.

O sọ fun akọroyin BBC pe tawọn mọlẹbi oun ba fi mọ si iṣẹlẹ yii, ṣe ni wọn yoo pa oun.

"Alfa sọ pe oun yoo ni ibalopọ pẹlu mi, oun yoo si fi omi to jade lara awa mejeeji fi ṣe ipese oogun ifẹ ti maa fun ọkọ mi jẹ"

Pupọ awọn obinrin taa ba sọrọ sọ pe ẹru ba awọn pe awọn eeyan yoo dawọn lẹbi tawọn ba fẹjọ awọn to fipa bawọn lo pọ sun.

Idi ree ti ọpọ fi dakẹ lai sọ fun mọlẹbi tabi awọn agbofinro.

Awọn mii a si tun maa bẹru pe fifẹjọ sun le mu ki alujọnu gbẹsan lara awọn.

Ni Sudan arabinrin kan torukọ rẹ n jẹ Sawsan sọ fun wa pe nigba ti ọkọ oun fẹ iyawo keji, iporuru ọkan de ba oun.

O ni lootọ ni oun mọ pe ọkọ oun lẹtọ lati fẹ iyawo mii labẹ Sharia.

O tori eleyi tọ onijalabi kan lọ boya yoo le fun oun ni nkan ti ọkọ rẹ yoo fi woju rẹ pada.

Amọ ko lero nkan to ba pade lọdọ alfa ọhun.

''O sọ pe oun yoo ni ibalopọ pẹlu mi, oun yoo si fi omi to jade lara awa mejeeji fi ṣe ipese ti maa fun ọkọ mi jẹ''

Aba to mu ya yii ṣafihan pe ko ni ibẹru Ọlọrun lọkan rara.

''Ọkan rẹ balẹ pe mi o ni fẹjọ rẹ sun lọdọ ọlọpaa, ile ẹjọ tabi fun ọkọ mi''

Aworan ọkan alara awọn obinrin ti awọn alufa fi ibalopọ lọ ni Sudan
Àkọlé àwòrán, Sawsan ni onijalabi toun tọ lọ fi ibalopọ lọ oun

Mẹta ninu obinrin aadọta ti BBC ba sọrọ nipa ihuwasi buruku yii tabi ibalopọ lọna aitọ darukọ Alfa yii ti orukọ rẹ n jẹ Sheikh Ibrahim.

Sawsan sọ pe kia loun sa kuro lọdọ rẹ, ti oun ko si fẹjọ rẹ sun ẹnikankan.

Mẹta ninu obinrin aadọta ti BBC ba sọrọ nipa ihuwasi buruku yii tabi ibalopọ lọna aitọ darukọ Alfa yii ti orukọ rẹ n jẹ Sheikh Ibrahim.

Ọkan lara awọn obinrin yii ti ko fẹ ka darukọ oun sọ pe o lo ọgbọn ete lati fi ni ibalopọ pẹlu oun.

Obinrin mii, Afaf sọ pe oun ni lati ti kuro nigba to beere ibalopọ lọdọ oun.

O ni ''awọn eeyan kii gbagbọ pe awọn Sheikh yi a maa hu iru iwa bẹẹ.

Wọn kii gba wa gbọ.

Bawo ni mo ṣe fẹ ri ẹlẹri?Ko si eeyan kankan ninu iyara pẹlu wa nigba to n fi ilọkulọ lọ wa''

Aworan alfa onijalabi kan ti BBC kan si
Àkọlé àwòrán, Sheikh Ibrahim fọwọ pa akọroyin BBC lara

Sheikh Ibrahim fi ọwọ si oju ara akọroyin BBC, ti onitọun si tete sa kuro nibẹ

Lọna ti fidi ọrọ yi mulẹ, BBC fi akọroyin kan dẹ ọdẹ fun Alfa naa, to si tọ Sheikh Ibrahim lọ lati fi le fi idi ẹri pataki mulẹ.

Akọroyin naa ti a pe orukọ rẹ ni Reem ṣe bi onibara to ni ipenija airọmọbi lọ ba Sheikh.

Sheikh sọ pe oun yoo ṣe adura fun, to si peelo omi iye kan ti yoo gbe lọ si ile lọ maa mu.

Reem sọ pe lẹyin igba naa lo sunmọ oun gbagba to si fi ọwọ le oun ni ikun.

Nigba to sọ pe ki Sheikh gbe ọwọ rẹ kuro, o gbe ọwọ lọ si isalẹ ara rẹ lọ si abẹ oju ara rẹ.

Nigba naa ni akọroyin wa sa jade kuro lọdọ rẹ.

O sọ fun wa pe ''iwa to hu yii dẹru ba mi pupọ. Oju rẹ n dẹru ba mi gaan''

Neem sọ pe iṣesi Sheikh yii fi han pe kii ṣe igba akọkọ re ti yoo dan iru nkan bayi wo.

BBC kan si Sheikh Ibrahim lori iwa to hu si Reem yii ṣugbọn o sọ pe oun ko fi ilọkulọ lọ Reem tabi awọn obinrin mii to ba iwosan wa si ọdọ rẹ.

Ko jẹ ki ifọrọwanilẹnuwo yii pẹ rara to fi pari.

Wo Sheikha Fatima to n se iwosan ẹmi fawọn obinrin lai si ipalara

Obinrin kan to n pese ọna itọju lai ko ipalara ba awọn obinrin yii ni Sheikha Fatima jẹ.

Ni Khartoum lo wa, to si ṣi ile iwosan fawọn obinrin nikan.

O le ni ọgbọn ọdun to ti wa nibẹ, ti aaye yii si jẹ ọkan lara ibi tawọn obinrin le ti gba itọju lọwọ obinrin ẹgbẹ wọn.

Wọn fun wa laaye lati wọ ile iwosan yii .

O jẹ iriri to ya ni lẹnu fun akọroyin wa.

O ṣalaye pe Sheikha Fatima sọ fun oun pe ipo ẹlẹgẹ lawọn obinrin maa n wa, ti eleyi a si maa mu ki awọn Alfa kan maa ko wọn ni panpẹ.

''Pupọ awọn obinrin sọ fun wa pe awọn ro pe onijalabi wọnyi a maa yọ alujọnu kuro lara wọn lasiko ti wọn n fọwọ kan wọn.

Wọn ni awọn ro pe ara itọju lo wa.''

O fikun pe ọrọ ti ko ṣe feti gbọ lawọn maa n gbọ lẹnu awọn obinrin to tọ awọn Alfa onijalabi naa lọ.

Ki ni esi tawọn alaṣẹ fọ si iwadii wa?

A mu ẹri nkan taa ṣe iwadii lọ sọdọ awọn alaṣẹ ni Morocco ati Sudan .

Ni Sudan, Dr Alaa Abu Zeid,to jẹ alaṣẹ ẹka to n mojuto ọrọ ẹsin Islaamu, amọ ko kọkọ fẹ gbagbọ pe aduru obinrin yii lo sọ iriri ifipabanilopọ wọn fun wa.

Amọ o pada gba wi pe aisi ofin to de iṣẹ awọn Alfa yii tunmọ si pe wọn yoo maa da wahala silẹ ni, paapa awọn Alfa to sọ isẹ iwosan ẹmi di isẹ oojọ nitori ainiṣẹ.

O sọ fun BBC pe oun gbiyanju lati fofin lelẹ nipa ṣiṣe iṣẹ awọn Alfa ni igba kan ri ṣugbọn irukerudo lagbo oṣelu ko jẹ ki awọn oloṣelu ka ọrọ yii kun.

Ni Morocco Minisita feto ọrọ ẹsin Islaamu Ahmed Toufiq sọ pe oun ko gbagbọ pe o yẹ ki ofin to yatọ maa dari siṣe iṣẹ onijalabi.

''O ṣoro lati fi ofin da si ọrọ yi. Ọna abayọ ni ka maa ṣe idanilẹkọ ati iwaasu to peye''

Toun ti gbogbo ẹri ti a ṣe akojọpọ yi, awọn alaṣẹ ni Morocco ati Sudan ko fi tara tara ṣetan lati gbe igbesẹ kankan lori rẹ.

O ku sọwọ awọn obinrin ti ọrọ naa kan lati jade sita tu aṣiri awọn alaburu to n sa sabẹ iṣẹ Alfa lati ko ipalara ba awujọ.