Irọ́ ni gbogbo ohun tí ìyàwó mi ń sọ nípa mi - Dókítà tó ń jẹ́jọ́ ìfipábánilopọ̀ sọ fún ilé ẹjọ́

Dokita Femi Olaleye

Oríṣun àwòrán, Others

Dókítà Olufemi Olaleye ti ilé ìwòsàn Optimal Cancer Foundation tó ń kojú ìgbẹ́jọ́ pé ó fipá bá àbúrò ìyàwó rẹ̀, ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún lòpọ̀ ti sọ fún ilé ẹjọ́ pé irọ́ ni wọ́n pa mọ́ òun.

Nígbà tí ìgbẹ́jọ́ tún wáyé ní ilé ẹjọ́ tó ń rí sí ẹ̀sùn ìbálòpọ̀ àti ìfìyàjẹni tó wà ní Ikeja ní Ìpínlẹ̀ Eko lọ́jọ́ Ẹtì, ọjọ́ Kejìdínlógún, oṣù Kẹrin ni Dókítà Olaleye ṣe àfọ̀mọ́ ara rẹ̀ fún ilé ẹjọ́.

Dókítà Olaleye ní gbogbo ẹ̀sùn tí ìyàwó òun, Remi Olaleye fi kan òun ló jẹ́ irọ́ pọ́ńbélé àti pé ó hun gbogbo rẹ̀ jọ ni láti fi ṣe àkóbá fún òun.

Olaleye nígbà tó ń gba ẹnu agbejọ́rò rẹ̀, Babatunde Ọgbà sọ̀rọ̀ ní ọdún kejìlá rèé tí òun àti ìyàwó òun ti fẹ́ ara àwọn tí àwọn sì ní ọmọ méjì papọ̀.

Ó ní láti ìgbà tí àwọn ti fẹ́ ara àwọn ni ìyàwó òun ti máa ń pá irọ́ lọ́kan-ò-jọ̀kan fún òun àti pé ìyàwó òun máa ń yan àlè, tó sì ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú ọ̀rẹ́kùnrin rẹ̀ tẹ́lẹ̀ rí kan.

Ó fi kun pé àwọn pínyà fún odidi ọdún kan gbáko lẹ́yìn ọdún méjì tí àwọn ṣe ìgbéyàwó nítorí àwọn irọ́ tí ìyàwó òun pa fún òun èyí tí àṣírí rẹ̀ tú sí òun lọ́wọ́ lẹ́yìn tí àwọn ṣègbéyàwó.

“Gbogbo ilé ẹ̀kọ́ tí ìyàwó mi sọ pé òun lọ ló jẹ́ irọ́ pọ́ńbélé, kódà ó tún fún mi ní ìwé ẹ̀rí tó jẹ́ ayédèrú.”

Mi ò lọ́wọ́ sí bí ìyàwó mi ṣe mú àbúrò rẹ̀ wá gbé pẹ̀lú wá

Bákan náà ni dókítà Olaleye tún sọ fún Adájọ́ Ramon Oshodi pé òun kò lọ́wọ́ sí bí ìyàwó òun ṣe mú àbúrò rẹ̀ tí wọ́n fi ẹ̀sùn kan òun pé òun ń bá ní àjọṣepọ̀ wá sí inú ilé àwọn láti máa gbé.

Ó ní ọmọ ọdún méjìdínlógún ni ọmọ náà nígbà tó dé ọ̀dọ̀ àwọn dípò ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún tí wọ́n ń pe ọmọ ọ̀hún.

Ó ṣàlàyé pé ọmọ náà tẹ̀lé ìyá ìyàwó òun tó rẹ̀ lásìkò náà wá sí ilé àwọn fún ìtọ́jú ni.

Dókítà Olaleye tẹ̀síwájú pé ilé ẹjọ́ ni òun wà nígbà tí wọ́n ní ọmọ ọ̀hún fi ẹ̀sùn kan òun pé òun fipá bá ọmọ náà lòpọ̀ àmọ́ irọ́ ni ẹ̀sùn náà.

“Remi ṣe ètò láti jẹ́ kí ọmọ náà bẹ̀rẹ̀ ilé ẹ̀kọ́ lọ́dọ̀ wa èyí tí mo lòdì sí nítorí kò sí ẹbí kankan tó ń báwa gbé pọ̀ àmọ́ ìyàwó mi fárígá nítorí ọmọ náà tí fìdí rẹmi níbi ètò ìdánwò àṣekágbá ìwé mẹ́wàá.”

“Ó fẹ́ kó tún WAEC ṣe kó tó padà sí Sapele tó ti wá.”

Ẹ̀rọ ayàwòrán wà ní gbogbo ilé wa

Bákan náà ló tún sọ fún ilé ẹjọ́ pé inú yàrá kan náà ni òun àti ìyàwó òun ń sùn àti pé ẹ̀rọ ayàwòrán mẹ́rìndínlógún ni àwọn ní nínú ilé àwọn.

Ó ní kò sí bí irú ìṣẹ̀lẹ̀ bẹ́ẹ̀ yóò ṣe máa wáyé tí èèyàn kò ní tètè mọ̀.

Ṣáájú ni ìyàwó dókítà Olaleye, Remi Olaleye sọ fún ilé ẹjọ́ ní ọjọ́ Kọkàndínlógún oṣù Kejìlá ọdún 2022 pé ọkọ òun ní ààrùn kó máa ní ìbálòpọ̀ ní gbogbo ìgbà.

Ẹ̀wẹ̀, Adájọ́ Oshodi ti wá sún ìgbẹ́jọ́ síwájú di ọjọ́ Kejìlélógún oṣù karùn-ún, ọdún 2022.