Ṣó o Láyà: Mr Success, gbajúmọ̀ adẹ́rìnínpòṣónú kópa nínú ìdánwò nípa àṣà àti èdè Yorùbá

Àkọlé fídíò, Ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè lórí èdè Yorùbá

Gbajúmọ̀ adẹ́rìnínpòṣónú, Hassan Adesanya, tí ọ̀pọ̀ mọ̀ sí Success Guy ti kópa lórí ètò Ṣó o Laya tí BBC Yorùbá ṣe fun un.

Nibẹ si ni o ti dahun awọn ibeere lọkan o jọkan eyi to nii se pẹlu ede Yoruba, asa ati iṣe wa.

Awada kẹrikẹri gbaa si ni awọn ọna ti Success guy naa gba dahun awọn ibeere naa, eyi to pa ni lẹrinin pupọ.

Ẹ wa nnkan fidi le, lati gbadun awọn idahun Success guy lori ibeere ti BBC Yoruba bi lori eto wa, Ṣó o Láyà.