Ilé ẹjọ́ fi méjì nínú àwọn tó lu Temitope Olorunfemi pa lórí ẹ̀sùn Yahoo pamọ́ sọ́gbà ẹ̀wọ̀n, gba béèlì mẹ́ta

Meji ninu awọn afurasi marun un to lu Temitope Olorunfemi pa lori ẹsun ṣiṣe Yahoo ni ile ẹjọ ti ni ki wọn lọ rọkun lọgba ẹwọn fun igba diẹ na.
Awọn meji ọun, Victor Amos, ọmọ ọgbọn ọdun ati Pelumi Farotimi, ọmọ ọdun mejilelogoji ni adajọ ile ẹjọ majistreeti ọhun, Musa Al-Yunus wi pe ẹri wa to fidi rẹ mulẹ pe o yẹ ki wọn wa ni ihamọ titi di akoko tawọn oṣiṣẹ ẹka to n mojuto igbẹjọ gbogbogbo nile iṣẹ ijọba to n ri si eto idajọ, DPP, yoo fi amọran wọn lede.
Amos Victor lo wa ninu fanran to n tan kaakiri lori ẹrọ ayelujara nibi to di da ẹṣẹ bo oloogbe naa to si tun la ogulutu mọọ lori.
Pelumi Farotimi ni ẹgbọn oloogbe jẹri pe o ti oun lulẹ lakoko ti un n gbiyanju lati doola ẹmi aburo ohun, to si pa awọn kan laṣẹ lati tẹsiwaju nipa nina oloogbe naa titi ti ẹmi fi bọ lara rẹ.
Onidajọ Al-Yunus waa ni ki wọn fi awọn olujẹjọ mejeeji pamọ si ọgba ẹwọn Olokuta titi ti amọran DPP lori ẹjọ naa yoo fi jade.
Ẹwẹ, awọn afunrasi mẹta to ku, Boboye Ismaila, Nurudeen Kumuteyi ati Samuel Olatunji ni Majistreeti Musa Al-Yunus ni ko si ẹri to nipọn lati fihan pe wọn wa nibi ti iṣẹlẹ naa ti ṣẹ to le mu ki ohun fi wọn si ipamọ ọgba ẹwọn.

Al-Yunus waa gba oniduro awọn mẹtẹẹta pẹlu ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹta naira, (₦500,000) ati oniduro meji fun ẹni kọọkan wọn.
Awọn oniduro meji naa ni wọn gbudọ ni dukia bii ile tabi ilẹ ni agbeegbe ile ẹjọ naa.
Lẹyin eyii ni adajọ sun igbẹjọ ọhun si ọjọ kẹjọ, oṣu Kẹjọ, ọdun 2023 yii.
Ohun tó ṣẹlẹ̀ nílé ẹjọ́ lánàá rèé lórí ìgbẹ́jọ́ Temitope Olorunfemi tí wọ́n lù pa nílùú Akure

Oríṣun àwòrán, citizen tosin
Ile ẹjọ majistreeti to n gbọ ẹjọ ẹsun ipaniyan ti wọn fi kan awọn afurasi to lọwọ ninu iku Temitope Olorunfemi ti wọn pa niluu Akure ti sun igbẹjọ naa si ọla.
Orukọ awọn afurasi marun un to n jẹjọ naa ni Victor Amos; Ismalia; Pelumi Farotimi; Nurudeen Kumuyi ati Samuel Olatunji.
Ẹsun iditẹ, ipaniyan lọna ti ko ba ofin mu ati didana sun dukia ni wọn fi kan awọn eeyan naa.
Adajọ ile ẹjọ ẹjọ majistreeti ọhun, Musa Al-Yunus sun igbẹjọ naa si ọla ode yii to jẹ ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu Kẹrin, ọdun 2023 lẹyin to pe igbẹjọ ọhun amọ ti olupẹjọ ko wa sile ẹjọ.
Ọjọ ọdun Ajinde ‘Easter Monday’ lawọn afurasi naa atawọn mii ti wọn ti na papa bora lu Temitope Olorunfemi pa lori ẹsun ṣiṣe Yahoo lẹyin to fi ọkọ ayọkẹlẹ rẹ kọlu awọn eeyan kan ladugbo Ijoka, niluu Akure.
Inu ijamba ọkọ naa ni eeyan kan ti jade laye, ti awọn mẹfa mii si farapa yanayana.
Ẹwẹ, iya oloogbe naa ti sọ fun BBC Yoruba pe ọmọ kii ṣe ọmọ Yahoo gẹgẹ bii ẹsun ti awọn to lu u pa fi kan, bẹẹ naa ni iyawo rẹ sọ fun w ape oun loun ni awọn aṣọ ti wọn ba ninu ọkọ ayọkẹlẹ rẹ.
Àwọn afurasí tó lu Temitope Olorunfemi pa lórí ẹ̀sùn 'Yahoo' nílùú Akure fojú balé ẹjọ́

Marun un ninu awọn afurasi to lu Temitope Olorunfemi pa lori ẹsun ṣiṣe Yahoo ti foju bale ẹjọ kan niluu Akure.
Awọn afurasi ọhun, Victor Amos; Ismalia; Pelumi Farotimi; Nurudeen Kumuyi ati Samuel Olatunji, ni wọn n jẹjọ lori ẹsun mẹta ọtọọtọ.
Ẹsun ti wọn fi kan wọn ni iditẹ, ipaniyan lọna ti ko ba ofin mu ati didana sun dukia.
Nnkan bii aago mẹsan an ku iṣẹju mẹwaa aarọ ni ọkọ alawọ dudu Hilux gbe awọn afurasi naa wọ ile ẹjọ ọhun ti awọn agbofinro atawọn mọlẹbi wọn si n tẹle wọn lẹyin.
Gẹgẹ bii ohun ti ikọ olupẹjọ sọ, wọn wu iwa ọdaran naa ladugbo Ijoka, to wa niluu Akure, lọjọ kẹwaa, oṣu Kẹrin, ọdun 2023 yii.
“Igi, okuta atawọn ohun ija oloro mii ni wọn fi ṣekupa Temitope”
Ọlọpaa to gbe ẹjọ ọhun lọ iwaju adajọ, Insp Nelson Akintimehin sọ pe awọn afurasi naa gbimọpọ lati ṣekupa Temitope Olorunfemi lẹyin ti wọn fẹsun kan an pe o jẹ ọmọ Yahoo, eyii ti ko ri bẹẹ.
O ni wọn mọọmọ pa oloogbe naa pẹlu igi, okuta atawọn ohun ija oloro miran.
Akintimehin tun sọ fun ile ẹjọ ọhun pe awọn afurasi naa fi ẹtanu sọ ina si ọkọ ayọkẹlẹ Toyota Camry oloogbe ọhun, eyii to ni nọmba idanimọ KRD 627 GY.
O ni ẹsun ti wọn fi kan wọn tako abala 324 ninu iwe ofin iwa ọdaran to wa lori 324, 316(1) ati 451(6)(J) ti ipinlẹ Ondo.
Olupẹjọ naa wa rọ ile ẹjọ ọhun lati fi awọn afurasi naa si ọgba ẹwọn Olokuta to wa niluu Akure bi igbẹjọ naa yoo ṣe maa lọ lọwọ.
Adajọ ile ẹjọ ọhun, Musa Al-Yunus gbọ ẹbẹ agbẹjọro awọn afurasi naa lati sun ẹjọ ọhun si ọla ode yii, to jẹ ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu Kẹrin, ọdun 2023.
O wa ni ki wọn da wọn pada si ahamọ ọlọpaa titi igba ti igbẹjọ ọhun yoo tẹsiwju lọla.
Ti ẹ ko ba gbagbe, ọjọ ọdun Ajinde ‘Easter Monday’ lawọn afurasi naa atawọn mii ti wọn ti na papa bora lu Temitope Olorunfemi pa lori ẹsun ṣiṣe Yahoo lẹyin to fi ọkọ ayọkẹlẹ rẹ kọlu awọn eeyan kan ni Ijoka, nibi ti eeyan kan ti jade laye, ti awọn mẹfa mii si farapa yanayana.












