Bí o ṣe lè kó àwọn èèyàn kúrò lágbègbè tí ogun ti ń jà

Aworan

Oríṣun àwòrán, Reuters

Ijọba ilẹ Gẹẹsi ti ko awọnv aṣoju rẹ at’awọn mọlẹbi wọn kuro lorilẹede Sudan l’asiko igbesẹ maṣafira kan ti awọn ọmọ ogun orilẹede naa ṣe lọjọ Aiku

Eyi n waye lẹyin t’awọn ikọ ologun kan n ja ija emi ji ọ iwọ ko ju mi bẹrẹ lati ọsẹ to kọja eyi to ti mu ọpọ ẹmi lọ ni ilu Khartoum to jẹ olu ilu orilẹede naa.

ọpọ awọn ọmọ orilẹede miran, ninu eyi ti Naijiria wa, lo ṣi ha si Sudan bayii ti wọn si n ke gbajare si ijọba orilẹede koowa wọn pe inu ewu nla lawọn wa.

Orilẹede Amẹrika ni tirẹ kede lọjọ Aiku pe awọn naa ti n ko awọn ọmọ orilẹede wọn kuro ni Sudan.

Bakan naa lawọn orilẹede bii France, Germany, Italy, Ghana at’awọn miran pẹlu ni awọn ti n gbe igbesẹ bẹrẹ lati ọjọ Aiku.

Ijọba orilẹede Naijiria ni awọn yoo bẹrẹ si nii ko awọn ọmọ Naijiria kuro ni Sudan lọjọ Iṣẹgun, ọjọ Karundinlọgbọn osu kẹrin ọdun 2023.

Awọn alaṣẹ ajọ to n bojuto iṣẹlẹ ajalu ati pajawiri, NEMA ni orilẹede Egypt ni wọn yoo kọkọ ko wọn lọ pẹlu ọkọ ki wọn to fi baluu gbe wọn lati Egypt wa si Naijiria.

BBC News bi Phillips Ingram ẹni to fi ọdun mẹrindinlọgbọn ṣiṣẹ ọmọ ogun nileeṣẹ ọmọ ogun ilẹ Gẹẹsi lori awọn igbesẹ ti orilẹede nilo lati ko awọn eeyan kuro ni orilẹede tabi agbegbe ti ogun ti n ja.

Alaye to ṣe re e:

Igbesẹ akọkọ: Eto ati igbaradi

Aworan

Oríṣun àwòrán, Reuters

Awọn ologun lo maa n ṣe igbaradi yii lati rii pe ohun gbogbo duro deede.

Gẹgẹ bi oro ti Ingram sọ, awọn oṣiṣẹ ilee abo ati ọrọ okeere pẹlu naa yoo tu ma bẹ awọn ileeṣẹ aṣoju ijọba orilẹede naa wo lati jiroro lori awọn eto ti wọn ni fun iṣẹlẹ pajawiri.

O ni ewu pupo lo wa ninu lílo ọmọ ogun lati ko awọn eeyan orilẹede kan kuro ni agbegbe ti wahala ogun ba ti n waye, nitori naa, lẹyin ti wọn ba ti yẹ gbogbo ọna ni wọn maa n lo o.

Wọn kii sii lo o lai jiroro pẹlu awọn orilẹede miran to n gba iru bẹẹ.

Igbesẹ keji: Ṣiṣe e ni awo oru lai ni jẹ ki ẹnikẹni mọ

Aworan

Oríṣun àwòrán, Reuters

O ni pataki lara igbesẹ kiko awọn eeyan kuro ni agbegbe ti ogun ti n ja ni lati de ba awon to n figagbaga nibẹ lojiji.

Ọgbẹni Ingram ni wọn kii si lu awo igbesẹ naa sita fun ẹnikẹni ki awọn igun to n ja ma ba a lọ ji ẹnikẹni ninu wọn gbe.

Ki eyikeyi ninu awọn igun to n ja ma baa le e di ihamọra yoowu to yẹ.

O ni idi niyi ti wọn kii fi I sọ fun ẹnikẹni.

Ipele kẹta: Wiwọle si orilẹede tabi agbegbe ti ogun tabi wahala ti n ṣẹlẹ

Aworan

Wọn yoo ti ko awọn ọmọ ogun, baluu ati ohun elo gbogbo ti wọn nilo fun eto naa kalẹ.

Ọgbẹni Ingram ni wọn a ti gbe awọn nnkan wonyi kalẹ sí awọn orilẹede tabi agbegbe to sunmọ Sudan ṣaaju ọjọ ti wọn yoo wa ṣe iṣẹ naa.

O ni ni ti eyi to waye ni Sudan, orilẹede Cyprus ni wọn gbé wọn si nitori ibẹ ni ibudo awọn ọmọ ogun Ilẹ Gẹẹsi to sunmọ Sudan ju wa.

O ni lara awọn baluu akero ti wọn gbe kalẹ ni sepe ni Airbus A400Ms ati baluu Lockheed C-130J Hercules.

Ipele kẹrin Jijade kuro ni agbegbe wahala naa

Aworan

Oríṣun àwòrán, Reuters

Lẹyin ti awọn ọmọ ogun ba ti gunlẹ wọn ti pe awọn ọmọ orilẹede naa ti wọn fẹ ko wa si ileeṣẹ aṣoju ijọba orilẹede naa tabi agbegbe miran ti wọn ti fimọ ṣọkan si.

Ogbẹni ingram salaye pe nibẹ ni wọn yoo ti ko wọn si inu ọkọ akero lọ si ibi ti wọn yoo ti gbe wọn jade.

Ohun to han si BBC ni pe ibudo papakọ baalu Wadi Seid a ni Sudan lawọn ologun ti fi baluu ko awọn eeyan naa jade lọjọ Aiku.