Segun Johnson: Ọ̀nà àrà tí mò ń gbà kọrin, lu ìlù, ló mú mi tayọ láàrin ẹgbẹ́ mi
Yoruba ni ori lo mọ isẹ asela, ọmọ ti yoo ba si jẹ aṣamu, kekere ni yoo ti maa jẹnu samu-samu.
Bẹẹ ni ọrọ itan igbe aye Segun Johnson tii se gbajumọ akọrin juju to fi ilu Eko se ibujoko se ri.
Ẹni to ba ti gbọ ori Johnson ri, yoo mọ pe ara ọtọ ni nitori ilu ati orin tiẹ yatọ si ti awọn akẹẹgbẹ rẹ.
Ti ẹ ba ti n gbọ 'So ta lẹnu, so fine gan' isẹ ọwọ Segun Johnson ni.
- Ẹ wo ìbejì ológo tó bẹ̀rẹ̀ orin kíkọ̀ ní ọmọ ọdún mẹ́ta
- N kò kàwé rí nílé ìkàwé àmọ́ èmi ni akẹ́kọ̀ọ́ tó pegedé jùlọ ní fásitì LASU - Sotunde
- "Kékeré ni mo ti ń wádìí bí wọn ti ṣe bàálù, mo dúpẹ́ pé mo ṣe Dírónù jáde"
- Small Mummy, aláwàdà ọmọ ọdún mẹwàá gba ẹ̀bùn ọkọ̀ olówó iyebíye
- Wo ohun mẹ́wàá tó yẹ kóo mọ̀ nípá ọmọ ọdún mẹ́wàá Emmanuella tó kọ́ ilé ńlá fún ìyá rẹ̀
Ọna ara ti ọkunrin naa n gba kọ orin yii lo mu ki BBC Yoruba se awari akọrin naa lati mọ ohun to sun de idi ara nla yii.
Bi Akọrin naa se n fi gbo ara jo, ti ilu n lọ kikankikan, naa ni awọn asa lorisirisi yoo maa tẹlẹ.
"Ọmọ iya oniburẹdi ni mi, inu pako ni mo sun dagba amọ ile ijọsin ni mo ti bẹrẹ orin kikọ."
Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ, Segun Johnson ni ọmọ atapata dide ni oun, to si jẹ pe mama oun lo tọ awn dagba.
" Burẹdi ni mama mi n ta nigba ti a wa lewe, ọmọ iya oniburẹdi si ni wọn maa n pe mi.
Inu ile pako la n sun nitori pe mama mi ko ri owo gba ilegbe.
Amọ isẹ orin kikọ mi bẹrẹ nigba ti mo n tẹle mama mi lọ sile isjọsin, ti mo si dara pọ mọ ẹgbẹ akọrin.
Lati ibẹ naa si ni mo ti di ẹni to n kọrin, ti aye si mọ lonii."
- Ìtàn odò Yemojì rèé, obìnrin arìnrìnàjò tó di odò tó ń ṣe ìwòsàn
- N kò nílò ọtí tàbí sìgá kí n tó wa ọkọ̀ ńlá Tírélà bí àwọn yòókù- Ademola Taiwo
- Nítorí mi ò fẹ́ kí àwọn ọmọ òrukàn ya ìpátá sílùú ni mo ṣe ń fi ijó kó wọn jọ
- Inú mi bàjẹ́ lọ́jọ́ tí mo gbọ́ pé wọ́n ń kó ọṣẹ dúdú wọ Naijiria láti òkè òkun- Omolola Ayeni
- Kazeem Dosunmu, Alfa tó fi owó ilé ẹ̀kọ́ àwọn ọmọ rẹ̀ kọ́ afára fún ìlú rẹ̀
"Olorin gbọdọ ni ami idamọ tiẹ nitori awọn to n kọ orin pọ, ero wa, eeyan si wa laarin wa"
Nigba to n salaye idi to se tayọ laarin awọn akẹẹgbẹ rẹ to jẹ akọrin juju, Segun Johnson ni ọna ara ti oun n gba kọ orin ni.
Bakan naa lo salaye pe ode iyawo kan ni oun ti kọ kọrin nibi inawo, nigba ti isẹlẹ kan waye, ti oun si bọ soju agbo lati kọrin fawọn obi to n se igbeyawo fun ọmọ wọn.
"Olorin to ba fẹ tayọ gbọdọ ni ọna ara to tayọ lati fi kọrin, eyi ti aye yoo gba mọ.
Gẹgẹ bi ẹ se mọ pe awa ti a n kọrin pọ, awọn ero wa nidi isẹ orin kikọ, bẹẹ si ni awa eeyan wa pẹlu.
Amọ ọna kan to rọrun lati jẹ ki olorin kan mu oke tente ni pe ki aye mọọ pẹlu ọna ara tiẹ to n gba kọrin.
Ko dara ka maa sin olorin kan jẹ, tabi maa kọrin gẹgẹ bi onitọhun se n kọrin, kii tete jẹ ki eeyan ri ọwọ mu."
Segun Johnson wa salaye fun BBC Yoruba nipa awọn inawo ati isẹlẹ to n gbe pade awọn gbajumọ olorin mii ati amuludun loniran n ran.
Lara awọn eekanlu to si ti pade ni Naira Marley ati Mr Remote.
O si tun sisọ loju rẹ pe ọdun meje sẹyin ni oun ti bẹrẹ isẹ orin kikọ, ti oun si ti gba ọpọ ami ẹyẹ lorisirisi.



