Kehinde Omolola Ayeni: Pádí kòkó tí àwọn Bàbá wa ń dànù ní oko àti eérú ni à ń lò fí ṣe ọ̀ṣẹ̀ dúdú
Inú mi bàjẹ́ lọ́jọ́ tí mo gbọ́ pé wọ́n ń kó ọṣẹ dúdú wọ Naijiria láti òkè òkun- Omolola Ayeni
Ọdọbirin kan to n fi iṣẹ ọṣẹ dudu ṣiṣe ni ọna igbalode dárà niluu Ado Ekiti, Omolola Ayeni, ti sọ pe oun yan iṣe naa laayo nitori pe awọn kan ti bẹrẹ si ni ko o wọle lati oke okun.
Obinrin ọhun, to jẹ akẹkọọjade ile ẹkọ giga kan niluu Ibadan sọ pe alabagbe oun kan lo sọ fun oun nile ẹkọ naa pe orilẹ-ede Ghana ni wọn ti n gbe ọṣẹ dudu ti oun n lo wọ Naijiria.
Idi ti mo fi kọ iṣẹ ọṣẹ dudu
- Àwon Mùsùlùmí àtàwon onísẹ̀ṣe tọwọ́ bọ̀wé àdéhùn àlááfíà nílùú Ilorin, wọ́n ní kò sí ìjà ẹ̀sìn mọ́
- Àwọn agbébọn jí ọ̀gá àgbà FCE Abẹokuta tẹ́lẹ̀ àti awakọ̀ rẹ̀ gbé
- Wo oúnjẹ oníkóró mọ́kànlá tó yẹ́ kí ó má a jẹ láti dènà àìsàn ní àgọ́ ara rẹ
- Njẹ́ o ní ǹkan tí èèyàn lè ṣe tí kò bá fẹ́ bí ọmọ àfín?
- Mọ̀ sí i nípa Oba Yesufu Asanike, Olubadan tí kìí fi ọ̀rọ̀ sí abẹ́ ahọ́n sọ kódà níwájú sọ́jà
- Ìdí tí wọn kii fi jẹ́ kí obìnrin jẹ Ọ̀ọ̀ni ni Ile Ife
- Ìtàn nípa orúkọ àdúgbò tó níí ṣe pẹ̀lú ìjà Oyo, Fulani àti Ilorin ní 1835
Gẹgẹ bii ohun to sọ, iyalẹnu lo jẹ pe wọn n ko ọṣẹ naa wọ Naijiria, loun ṣe pinnu lati lọ kọ bi wọn ṣe n ṣe ọṣẹ ọhun.
Bo tilẹ jẹ pe o ni aitete ri iṣẹ wa lara idi ti oun fi kọ iṣẹ ọṣẹ dudu naa, iya to kọ oun niṣẹ ọhun ṣalaye pe iwọmba eeyan perete lo n ṣe ọṣe naa lagbegbe oun, iyẹn niluu Aramoko Ekiti.

Omolola Kehinde Ayeni ni "Iṣẹ yii, iṣẹ ti awọn iya wa atawọn baba-baba wa fi le wa lọwọ ni, ni mo ṣe wo pe ki awa naa pada sibẹ,
Ki a gbe e larugẹ, ki awa naa maa fi kọ awọn eeyan, ki a si ṣe e ni ọna to jẹ pe yoo ṣe itẹwọgba ni gbogbo orilẹ-ede agbaye fun ogo Naijiria."
- Àwọn Olùkọ́ Akure pegedé lórí ètò Akomolede àti Aṣa lórí BBC Yorùbá
- Wo ìtàn bí ààlọ́ ṣe bẹ̀rẹ̀ àti onírúurú ààlọ́ àpagbè àti àpamọ̀
- Àwọn Olùkọ́ Yorùbá ní ìpínlẹ̀ Osun ṣe bẹbẹ lórí ètò Akomọlede àti Aṣa lórí BBC
- Ó máa ń dùn mí tí Òbí Yorùbá kò bá kọ́ ọmọ̀ rẹ̀ ní èdè nítorí pé èmi ti fi Yorùbá soriíre púpọ̀- Tiago Òyìnbó
Ki ni wọn fi n ṣe ọṣẹ dudu?
Gẹgẹ bii ohun ti Omolola sọ, eroja meji pataki ti wọn fi n ṣe ọṣẹ naa ni eeru ati ororo ekurọ.
O ni padi koko lawọn maa n jo ti wọn si maa lo eeru rẹ tabi ki wọn lo eeru igi ti wọn ti jo.
Omolola ni "nnkan meji ti a fi n ṣe ọṣẹ naa niyẹn."
- N kò nílò ọtí tàbí sìgá kí n tó wa ọkọ̀ ńlá Tírélà bí àwọn yòókù- Ademola Taiwo
- “Ọ̀pọ̀ ọ̀rẹ́ kọ mi torí mò ń wọ aṣọ ìbílẹ̀, wọ́n ní nǹkan míì wà nídìí rẹ̀ - Bàbá Àṣà
- "Awọn ọmọ tó ń ta ilẹ̀ Ibadan láìtọ́ rugi oyin bí ọba ṣe wà ní ìjọba ìbílẹ̀ kọ̀ọ̀kan"
- Adire: Àwọn èèyàn wa ló ń tú àṣírí f'áwọn tó ń kó ayédèrú Àdìrẹ wọlé láti orílẹ́èdè míì
- Ayé ń yí! Wo ìdí tí ọ̀pọ̀ ọkùnrin ṣe ń lọ kọ́ bí a ti ń ṣiṣẹ́ ilé
Omolola Kehinde Ayeni tun sọ fun BBC pé: "Inu igbo lati maa n ri padi koko, ọfẹ lawọn baba wa maa n ko fun wa loko, a fi ti a ba tilẹ fun wọn ni owo kekere diẹ ki wọn ba wa ko."
"Awọn nnkan ti awọn n danu ni, ohun lawa fi n ṣe ọrọ aje ni tiwa."
O mẹnuba ipa ti kikọ iṣẹ owọ yii ti ni ati awọn ọmọ ẹkọsẹ loriṣiiriṣii to ti wa kọ iṣẹ naa lọwọ rẹ ati obinrin, ati agbalagba yatọ si awọn ọdọ to kawe ati awọn abarapá eeyan.
Omolola tẹsiwaju pe "lọjọ ti mo kọkọ gbọ pe wọn n ko ọṣẹ dudu wọ Naijiria, o kọkọ jẹ nnkan ibanujẹ fun mi pe iṣẹ ilẹ wa, a tun fi silẹ to wa di nnkan ti wọn n ko wọle wa fun wa."
Ẹkunrẹrẹ ohun ti Omolola sọ wa ninu fidio oke yii.