Adire: Àwọn èèyàn wa ló ń tú àṣírí f'áwọn tó ń kó ayédèrú Àdìrẹ wọlé láti orílẹ́èdè míì
Bi iku ile o ba pani Yoruba bọ, wọn ni tode o le pani.
Bẹẹ ni ọrọ yi ri ninu alaye ti awọn aladirẹ ni ọja Asero Abeokuta ṣe fun ikọ BBC lasiko ifọrọwanilẹnuwo.
Ifọrọwanilẹnuwo yi to da lori iṣẹ wọn ipenija to wa nibẹ ati iru anfaani ti asọ Adire ni tubọ tan imọlẹ si awọn nkan miran.
Iyalọja awọn aladirẹ́ naa Arabirin Oluwakemi Oloyede sọ pe Adirẹ kọ ni wọn n ko wa lati ilẹ okere kii ṣe ojulowo adirẹ.
O ni lootọ lawọn ijọba ko awọn akẹkọọ kan wa lati wa kọ nipa adirẹ ṣiṣe ṣugbọn pupọ ayederu adire lonii lati ọwọ awọn ara ilẹ China lo ti n wa.
''Awọn Chinese yẹn, wọn maa nw a ra aṣọ wa, wọn a si tun maa ran awọn eeyan wa lati wa ra lọdọ wa.''
O ni ti wọn ba ra aṣọ naa tan wọn yoo ''ko pada lọ si ilu wọn ti wọn a si wa fi ẹrọ igbalode ṣe lọdọ wọn''
A o le pe ti wọn yẹn ni Adirẹ!
Iyalọja Oloyede tẹsiwaju pe awọn eeyan ilẹ China a maa ji ẹya to ba wa lara awọn Adirẹ tawọn ba ṣe ti wọn a si maa ta lowo pọọku.
O ni aṣọ ti ko ba wọ arọ ti ko ba wọ inu omi gbonaa, kii ṣe Adirẹ.
Bakan naa Olutọju Asa ati Ede Yoruba kan Adejoke Somoye sọ pe aimọkan lo jẹ ki ọpọ eeyan maa ra tabi ta aṣọ adirẹ ayederu to n wa lati China yi.
O ni bi eeyan naa ba mọ pe ogun ini oun lo fẹ ta, ko ni bawọn ko ayederu adirẹ pọmọ ojulowo rẹ.