Ọ̀gá ilé ẹ̀kọ́ FCE tẹ́lẹ̀ rí, Ajayi gba ìtúsílẹ̀ kúrò ní àhámọ́ ajínigbé

Ayọdele Adetayọ Ajayi

Oríṣun àwòrán, FCE

Orin ọpẹ l'awọn mọlẹbi ati alabaṣiṣẹ pọ ọga agba tẹlẹ nile ẹkọ awọn olukọni agba, Federal College of Education (FCE) to wa niluu Abẹokuta, ipinlẹ Ogun, Ọmọwe Ayọdele Adetayọ Ajayi mu sẹnu nigba ti wọn gbọ pe awọn ajinigbe ti fi silẹ lahamọ wọn.

Bi a o ko ba gbagbe, Ọjọru ọsẹ yii la mu iroyin naa wa fun un yin wi pe awọn ajinigbe da Ọmọwe Ajayi, iyawo ati awakọ rẹ lọna, lasiko ti wọn n bọ lati ibi eto ayẹyẹ kan ti wọn lọ, iyẹn lọjọ Iṣẹgun ọsẹ yii kan naa.

Ni bayii, iroyin to tẹ ileeṣẹ BBC News Yoruba jẹ ko di mimọ pe awọn ajinigbe yii ti fi Ọmọwe Ajayi silẹ kuro lakata wọn, to si ti wa ni ọsibitu kan ti a fi orukọ bo laṣiri, nibi to ti n gba itọju lọwọ.

Agbẹnusọ fun ile-ẹkọ FCE, Ọgbẹni Anthony Ogundipẹ fidi rẹ mulẹ laaarọ ọjọ Ẹti ni pe wọn ti fi ọga agba awọn tẹlẹri naa silẹ, ati pe o ti wa nibi to ti n gba itọju lọwọ.

O jẹ ko ye wa pe nnkan bi aago marun-un aabọ si mẹfa irọle ni wọn fi ọga awọn tẹlẹ naa silẹ, bo tilẹ jẹ oun ko ti i ni kulẹkulẹ iroyin ọhun lọwọ.

"N29m ni awọn Ajinigbe yii bere fun"

Ogundipẹ sọ pe miliọnu mọkandinlọgbọn naira l'awọn ajinigbe yii n beere, ki wọn to le fi silẹ, ṣugbọn to sọ pe ileewe naa ko gbe owo kankan silẹ, nitori igbagbọ wi pe awọn ọlọpaa, at'awọn ileeṣẹ eleto aabo ti n ṣiṣẹ wọn.

Siwaju si i lo sọ pe oun ko wa le sọ boya awọn mọlẹbi Ọmọwe Ajayi gbe owo kalẹ, ṣugbọn to sọ pe ko da oun loju, nitori pe oun nigbagbọ ninu ọlọpaa daadaa.

O tẹsiwaju pe awọn ko nilo lati maa tu iṣu de isalẹ ikoko, bi ko ṣe pe ohun to jẹ wọn logun ju ni ẹmi ọga agba awọn tẹlẹ naa.

"Lotitọ ni awọn ajinigbe naa n beere owo, ṣugbọn ile-ẹkọ wa ko fun wọn lowo, mi o wa le sọ boya awọn mọlẹbi fun wọn lowo. Miliọnu mọkanlelọgbọn ni wọn n beere, mi o wa le sọ boya awọn mọlẹbi pada gbe owo kalẹ, ṣugbọn mo nigbagbọ ninu awọn eleto aabo wa.

"Irọlẹ ana ni wọn fi to mi leti wi pe wọn ti fi wọn silẹ, bo tilẹ jẹ pe mi o ti i gbọ kulẹkulẹ nipa ẹ. Ọmọwe Ajayi ti wa ni ọsibitu kan ti mi o ni fẹẹ darukọ nitori ọrọ aabo ṣe pataki pupọ."

Siwaju si i lo gbe oriyin ati oṣuba kare fun ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun, ileeṣẹ ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ (DSS), So-Safe Corp, to fi mọ awọn Fijilante, pẹlu bo ṣe sọ pe wọn iṣẹ takuntakun.

Ki ni Ileeṣẹ Ọlọpaa sọ?

Agbẹnusọ ọlọpaa ipinlẹ Ogun, Ọmọlọla Odutọla nagba to n ba BBC YORUBA sọrọ, o ni bo tilẹ jẹ oun naa ti n gbọ nipa wi pe wọn ti fi ọkunrin naa silẹ, ṣugbọn oun ko ti i le fidi otitọ mulẹ, nitori pe awọn mọlẹbi ko ti i wa fi to awọn leti

O sọ pe o digba ti awọn mọlẹbi Ọmọwe Ajayi ba fi to ileeṣẹ ọlọpaa leti, l'awọn too le sọ pe wọn ti fi silẹ lootọ, bi bẹẹ kọ, oun ko ni ohunkohun lati sọ.

Bakan naa lo sọ pe ki ilẹ oni too ṣu, oun yoo fi atẹjade sita lati mọ ibi ti ọrọ de duro si.

Àwọn agbébọn jí ọ̀gá àgbà FCE Abẹokuta tẹ́lẹ̀ àti awakọ̀ rẹ̀ gbé

Iroyin to tẹ BBC Yoruba lọwọ laipẹ yii ti fi idi rẹ mulẹ pe awọn agbebọn kan ti ẹnikẹni ko tii mọ ti ji ọga agba patapata tẹlẹ nile ẹkọ awọn olukọni, Federal College of Education (FCE) to wa lagbegbe Oṣiẹlẹ, niluu Abẹokuta, Ọmọwe Ayọdele Adetayọ Ajayi gbe.

Ọmọwe Ayọdele Adetayọ Ajayi; iyawo rẹ, ati awakọ rẹ la gbọ pe awọn ajinigbe ọhun jigbe, ṣugbọn ti wọn pada fi iyawo silẹ.

Nnkan bi aago meje kọja iṣẹju mẹtadinlogun la gbọ pe awọn agbebọn naa da ọga agba ọhun duro lakoko ti wọn n bọ lati ibi irin ajo ti wọn lọ.

BBC Yoruba gbọ pe agbegbe abule Ikija to wa nitosi Olodo, loju ọna marosẹ Abẹokuta si Ibadan, ni wọn ti ji awọn eeyan naa gbe.

Bi ijinigbe na ṣe waye

Wọn ni niṣe ni awọn agbebọn naa sare jade lati inu igbo, ti wọn si da awọn ọkọ to n kọja lọ duro, pẹlu ibọn ti wọn yin soke lakọlakọ.

Asiko yii ni a gbọ pe Ọmọwe Ajayi, iyawo ati awakọ rẹ n kọja lọ siluu Abẹokuta.

Ọpọ awọn awakọ ati awọn ara agbegbe naa ni wọn juba ehoro lati sa asala fun ẹmi ara wọn.

Gbogbo awọn mọto to ku diẹ ki wọn de agbegbe yii ni wọn n sare yi pada lati ma ba a ko sọwọ awọn ajinigbe ọhun.

Lara awọn eeyan to wa nitosi lasiko ti ijinigbe naa waye la gbọ pe wọn ranṣẹ s'awọn ọlọpaa fun iranwọ.

Ko to di pe awọn ọlọpaa debẹ ni wọn l'awọn agbebọn yii ti gbe wọn wọnu igbo lọ, ti awọn ọlọpaa si tẹle wọn wọnu igbo lati mu wọn.

Lile ti awọn ọlọpaa le wọn lọwọ lo mu ki wọn fi iyawo Ọmọwe Ajayi silẹ, ti wọn si ko awọn toku lọ.

Awọn eeyan agbegbe naa sọrọ

Lara awọn to fi iṣẹlẹ naa to wa leti lagbegbe yii ti wọn kọ lati darukọ wọn ṣalaye pe kii ṣe igba akọkọ ree ti iru iṣẹlẹ naa yoo maa waye lagbegbe ọhun.

Wọn ni ko din ni eeyan marun-un ti wọn ti jigbe loju ọna naa laaarin ọsẹ kan si asiko yii, bo tilẹ jẹ pe wọn pada fi wọn silẹ.

L'oṣu to kọja ni wọn sọ pe awọn ajinigbe yii ji gbajugbaja oniṣowo agbẹ kan to ni oko n la lagbegbe ọhun gbe.

Koda, wọn sọ pe diẹ lo ku ki wọn ji Olu ti ilu Ọdẹda, Ọba Dabid Ọlọruniṣọla gbe laipẹ yii, ṣugbọn ti ori ko o yọ, bo tilẹ jẹ pe wọn yinbọn fun awakọ rẹ, ẹni ti wọn lo n gba itọju ni ọsibitu FMC to wa ni Idi-Aba, Abẹokuta.

Ki ni awọn alakoso FCE sọ?

Ọgbẹni Anthony Ogundipẹ to jẹ agbẹnusọ fun ile-ẹkọ olukọni FCE, lakoko to n ba BBC YORUBA sọrọ laaarọ oni sọ pe otitọ ni iṣẹlẹ naa, ati pe awọn ọlọpaa ti bẹrẹ iṣẹ iwadii won.

Ogundipẹ jẹ ko di mimọ pe nnkan bi aago mẹfa aabọ ni iṣẹlẹ ọhun waye, to si ni gẹgẹ bi Ọmọwe Ajayi ṣe jẹ ọga agba awọn to ṣẹṣẹ fi ipo silẹ laipẹ yii, o loju ẹsẹ l'awọn ti kan si ọga ọlọpaa ipinlẹ Ogun.

Siwaju sii lo sọ pe bo tilẹ jẹ pe awọn ajinigbe naa ko tii kan si wọn titi di asiko yii, sibẹ, o loun nigbagbọ pe Ọmọwe Ajayi yoo jade layọ lahamọ awọn ajinigbe naa.

Bẹẹ lo ni k'awọn eeyan ma ṣe bẹru tabi foya nitori pe iṣẹ iwadii ti n lọ lọwọ, ati pe ọwọ yoo tẹ awọn ọdaran naa.

Ileeṣẹ ọlọpaa sọrọ

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ninu ọrọ tiẹ, agbẹnusọ ọlọpaa ipinlẹ Ogun, Ọmọlọla Odutọla sọ pe lotitọ l'awọn gbọ nipa ijinigbe to ṣẹlẹ, ṣugbọn toun ko le fi idi iru eeyan ti wọn jigbe mulẹ.

Odutọla ni sibẹ, awọn ọlọpaa ati awọn ileeṣẹ eleto aabo yooku ti bẹrẹ iṣẹ iwadii latigba naa, koda to ni b'awọn eleto aabo ṣe le awọn ajinigbe ọhun ni kete ti iṣẹlẹ naa ṣẹlẹ, ni wọn ti fi ọkan lara awọn ti wọn jigbe, to jẹ obinrin silẹ.

"A ko tii mọ orukọ ọkunrin ti wọn jigbe naa. A ko le sọ boya ọga agba tẹlẹ ni tabi bẹẹ kọ. Ṣugbọn a le sọ pe lotitọ ni wọn ji eeyan gbe.

"A gbọ pe ẹni ti wọn jigbe yii ati iyawo rẹ jọ n bọ lati ode kan ni. Mo ro pe iyawo ọkunrin naa da ileewe silẹ, ati pe wọn n bọ lati ode ayẹyẹ ileewe naa nigba ti awọn agbebọn da wọn lọna.

"Ọpọ eeyan ni awọn ajinigbe yii ko, ṣugbọn ti wọn pada fi wọn silẹ, to si jẹ pe ọkunrin naa, iyawo ati awakọ rẹ ni wọn ko lo.

"Awọn ọlọpaa ati oṣiṣẹ eto aabo miran ti bẹrẹ iṣẹ, wọn si ti n gbogun ti awọn ajinigbe yii. Lara iṣẹ ti wọn n ṣe lo jẹ ki wọn tu obinrin naa silẹ.

"A ti gba mọto ti awọn agbebọn yii fi ṣiṣẹ, bẹẹ la si ti n tọpinpin wọn, pẹlu igbagbọ wi pe ọwọ yoo tẹ wọn, ti awọn to wa lahamọ wọn yoo si jade layọ ati alaafia."