Ìwà tí ìjọba n hù sí ẹ̀gbọ́n mi kò dárá, lẹ́yìn tó sin Naijiria fún ọdún mẹ́sàn-án- George Emefiele

Godwin Emefiele

Oríṣun àwòrán, Other

Ẹnikan to jẹ aburo fun gomina banki apapọ Naijiria (CBN), George Emefiele, ti sọ pe iwa ti awọn alaṣẹ n hu si Godwin Emefiele ko bojumu rara.

Bakan naa lo sọ pe ija to waye laarin awọn oṣiṣẹ DSS ati ti ọgba ẹwọn lẹyin ti adajọ gba beeli Emefiele pẹlu ogún miliọnu Naira, ko tọna labẹ ijọba awaarawa.

Arakunrin George Emefiele sọ pe ọwọ ti ijọba fi mu ẹgbọn oun ko dara, lẹyin to ti sin Naijiria fun ọdun mẹsan-an.

O ni ẹgbọn oun kii ṣe ẹni to le salọ.

“Ọdun mẹsan-an gbako lo fi ṣiṣẹ sin Naijiria. Amọ ṣe bi ijọba ṣe fẹ ẹ san ẹ̀san fun un re e?”

O ni eyi ko tọna, o si kesi ijọba apapọ lati gbọnran si aṣẹ ile ẹjọ nitori pe ẹgbọn oun ko tọ si awọn nnkan to n koju lọwọlọwọ lẹyin to fi ara rẹ sin orilẹ-ede.

Ọgbẹni Emefiele sọ pe nnkan ti awọn n fẹ ni pe ki ijọba tẹle ilana to yẹ lori ọrọ rẹ.

Kí ló fà ìjà láàrin DSS àti Iléeṣẹ́ ẹlẹ́wọ̀n lẹ́yìn tí iléẹjọ́ gba béèlì Emefiele?

Ija nla bẹ silẹ laarin ajọ DSS ati ajọ to n mujoto ọgba ẹwọn lorilẹede Naijira lẹyin ti ileẹjọ giga to n joko niluu Eko gba beeli Gomina tẹlẹ fun banki apapọ lorilẹede Naijiria, Godwin Emefiele .

Ọrọ di iṣu ata yaunyaun ni kete ti Adajọ Nicholas Oweibo gbe idajọ ọhun kalẹ lori taani yoo gbe Emefiele si akata rẹ lẹyin idajọ.

Fọnran to tẹ Ileeṣẹ BBC lọwọ ṣafihan bi awọn osisẹ ajọ DSS se n fa asọ ya mọ ọga agba ọgba ẹlẹwọn kan laraninu ọgba ile ẹjọ.

Adajọ ti pa lasẹ saaju pe ki Emefiele wa ni akata ọgba ẹwọn 'Correctional Center' titi ti yoo fi san beeli ti ileẹjọ ni ko san.Ko pẹ lẹyin idajọ naa ni ajọ DSS wa ọkọ ayọkẹle wọn si ẹnu ọna ile ẹjọ pẹlu erongba lati gbe Emefiele sinu rẹ kete to ba jade sita.

Eyi lo fa awuyewuye ti agbẹjọro agba fun Emefiele, Joseph Dauda ati awọn akẹgbẹ rẹ si pariwo sita.

Bẹẹ lawọn ajọ ti ọgba ẹlẹwọn naa si n gbinyanju lati gbe Emefiele.

Fakinfa waye lori ẹni ti yoo gbe Emefiele llọ ṣugbọn ajọ DSS lo pada gbe Emefiele kuro nile ẹjọ.

Fọnran fidio yi ṣafihan asiko ti wọn ya aṣọ mọ ọga ileeṣẹ ẹlẹwọn kan lara.