Ìjọba àpapọ̀ buwọ́lu àjẹmọ́nú N25,000 fún àwọn dókìtà

Oríṣun àwòrán, @vanguardngrnews
Ijọba apapọ ti buwọlu sisan ẹgbẹrun marundinlọgbọn Naira fun awọn dokita nileewosan ati awọn dokita to n tọju eyín, gẹgẹ bi ajẹmọnu.
Amọ awọn dokita to n ṣiṣẹ pẹlu ijọba apapọ nikan ni eyi kan.
Ikede naa jẹyọ ninu atẹjade ti alaga ajọ to n mojuto owo oṣu ni Naijiria, Ekpo Nta, fi sita.
Igbesẹ naa n waye lasiko ti awọn dokita n yan iṣẹ lodi.
Ọjọ Iṣẹgun, ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu Keje, ni ẹgbẹ awọn dokita ni Naijiria, NARD, ti bẹrẹ iyanṣelodi alailọjọ.
Awọn dokita ọhun kede bẹẹ ninu atẹjade kan ti wọn fi ṣọwọ si awọn akọroyin.
Kini awọn dokita n beere lọwọ ijọba?
Lara awọn nnkan ti awọn dokita naa n bere fun ni sisan awọn gbese ti ijọba jẹ wọn ati sisan owo MRTF ti ọdun 2023.
Awọn dokita ọhun tun n bere fun sisan owo oṣu wọn ni ilana ti wọn fẹnuko si tẹlẹ, iyẹn CONMESS ati bi ajọ Medical And Dental Council Of Nigeria, MDCN, ṣe ja iyẹ iwe ẹri awọn ọmọ ẹgbẹ kan kalẹ.
Ko tan sibẹ, wọn tun ni ijọba gbọdọ bẹrẹ si n san owo ijamba lẹnu iṣẹ ‘hazard allowance’ tuntun fun awọn, bakan naa, ko tun san owo ọhun kan naa to ti jẹ awọn sẹyin.
Iyanṣẹlodi yii lo n waye lẹyin ti wọn fun ijọba ni ọsẹ meji lati ṣe awọn ohun ti awọn n fẹ amọ ti ijọba kuna.
Ọjọ karun un, oṣu keje yii ni wọn fun ijọba apapọ ni gbedeke naa.
Ninu igbiyanju ijọba lati bẹgi dina iyanṣelodi ọhun, agbẹnusọ ile igbimọ aṣojuṣofin, Tajudeen Abbas ṣe ipade awọn adari ẹgbẹ awọn dokita naa ni idakọnkọ.
Lẹyin ipade naa ni Abbas ṣeleri lati ṣe ipade pẹlu Aarẹ Bola Tinubu ki iyanṣelodin ọhun ma baa waye.
Abbas tun rọ awọn dokita naa lati fun ijọba ni ọsẹ meji mii lati wa ojutu si ọrọ ọhun.












