Àwọn nnkan tí o ní láti mọ̀ nípa ìpàdé tí Russia n ṣe pẹ̀lú àwọn olórí ní Africa

Oríṣun àwòrán, The Cable
Ipade apero ti Aarẹ Vladimir Putin ti orilẹ-ede Russia pè larin Africa ati Russia, ti bẹrẹ ni Ọjọbọ, ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu Keje, niluu St. Petersburg.
Awọn olori orilẹ-ede mẹtadinlogun lati Africa lo n kopa nibi ipade naa fun ti ọdun yii, eyi to kere pupọ si awọn mẹtalelogoji to kopa ni ọdun 2019.
Yatọ si ogun to n waye ni Ukraine, ọwọn gogo ounjẹ ni yoo leke ninu ijiroro wọn nibi ipade naa, paapaa bi Russia ṣe pinnu ni ọsẹ to kọja lati jawọ ninu adehun agbaye kan to nii ṣe pẹlu ipese ounjẹ oniworo, eyi to nipa lori Africa.
Ajọ United Nations ati orilẹ-ede Turkey lo ṣe agbatẹru adehun naa lọdun to kọja, lati ri i daju pe awọn nnkan ere oko n gba papakọ ori omi Black Sea ni Ukraine kọja, lai fi ti ogun to n waye ṣe.
Ṣaaju asiko yii ni awọn alẹnulọrọ nilẹ America ati Europe ti n ri China gẹgẹ bi orogún wọn gboogi ni Africa, ṣugbọn ni bayii wọn ti n woye bi Russia ṣe n gbiyanju lati fi ẹsẹ ara rẹ mulẹ ni Africa.
Eyi ri bẹẹ paapaa pẹlu bi awọn ajagun tà Wagner ṣe wa ni Mali, Central African Republic (CAR), Libya, ati Mozambique.
Ipaya lori ounjẹ niworo
Lasiko ipade ijiroro naa, lara awọn nnkan pataki to jẹ ọpọ ijọba ni Africa logun, ni kiko ounjẹ oniworo lati Ila-oorun Europe wọ awọn orilẹ-ede Africa ti ọwọn ounjẹ n ba a finra.
Ọpọ orilẹ-ede ni inu wọn ko dun si Russia nitori bo ṣe fi opin si bi Ukraine ṣe n ko awọn ounjẹ naa gba Black Sea, ni ọsẹ to kọja.
Ogun Russia-Ukraine
Nibi ipade ijiroro ọhun to n waye ni St. Petersburg, ireti wa pe awọn adari ni Africa yoo tun gbiyanju lati wa ọna abayọ si ogun to n waye ni Ukraine.
Ninu oṣu Kẹfa, olori orilẹ-ede meje lati Africa lo rin irinajo lọ si Ukraine ati Russia fun ipade alaafia, pẹlu ireti pe awọn yoo le wa ọna abayọ si ogun naa to n nipa lori ọrọ aje Africa.
Lara awọn nnkan ti awọn aṣoju naa sọ nigba naa ni pe ki Russia ati Ukraine da duro gẹgẹ bi orilẹ-ede olominira, ki wọn os i tẹsiwaju lati ma a ta ounjẹ oniworo si Africa.
Wọn tun n fẹ ki ogun naa dawọ duro ni kiakia, ki awọn orilẹ-ede mejeeji si bẹrẹ iduna-dura lati tu awọn ti ogun sọ di ẹlẹwọn silẹ, ati bẹẹbẹẹ lọ.
Ilana ọrọ aje
Orilẹ-ede Russia yoo tun gbiyanju lati fa oju Africa mọra nipa titẹsiwaju pẹlu ibaṣepọ okoowo wọn.
Botilẹ jẹ pe Russia ko ni eroja lati fi iga gbaga pẹlu America, France, Germany, Japan ati China gẹgẹ oluranlọwọ fun idagbasoke Africa, oun naa ni nnkan to le lo.
Ni ọdun to kọja, Russia lo fẹ ẹ jẹ orisun ajilẹ (fertiliser) to tobi ju fun Africa - ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹta tọọnu ajilẹ lo fun Africa. O tun lọw su ọrọ porọbi, afẹfẹ gaasi ati iwakusa ni Africa.
Lọwọlọwọ, ọrọ ounjẹ oniworo lo ṣe koko julọ.
Ṣugbọn yoo nira fun Russia lati dá nikan ran Africa lọwọ pẹlu iye to nilo, ayafi to ba pada sinu adehun kiko ounjẹ gba Black Sea kọja, eyi ti yoo mu ki Ukraine naa le ko ounjẹ kọja.












