Ilé aṣòfin Ghana darapọ̀ mọ́ àwọn orílẹ̀-èdè Africa tó fi òpin sí ìdájọ́ ikú

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ile aṣofin orilẹ-ede Ghana ti dibo lati fi opin si idajọ iku, igbesẹ naa si ti mu ki orilẹ-ede ọhun wa lara awọn orilẹ-ede ni Africa to ṣe bẹẹ lasiko yii.
Aadọsan (170) ọkunrin ati obinrin lo n reti iku lọwọlọwọ ni Ghana. Ṣugbọn ni bayii, ijọba yoo sọ idajọ iku wọn di ẹwọn gbere.
Ọdun 1993 ni wọn pa eeyan kẹyin nitori iru idajọ yii.
Ṣaaju asiko yii, dandan ni idajọ iku jẹ́ fun ẹsun ipaniyan ni Ghana. Bakan naa ni iditẹ mọ ijọba.
Amọ iwadii fihan pe pupọ ninu awọn ọmọ orilẹ-ede Ghana lo faramọ fifi opin si idajọ naa.
Ni ọdun to kọja, eeyan meje lo gba idajọ iku - ṣugbọn ko si ẹni ti wọn pa ninu wọn.
Aṣofin Francis-Xavier Sosu lo kọkọ da àbá naa niwaju awọn aṣofin ẹgbẹ rẹ, o si ri atilẹyin gba lọwọ igbimọ to n mojuto ofin, ẹka idajọ ati awọn ọrọ to kan ile aṣofin.
Ajọ aladani kan to n polongo tako idajọ iku niluu London, Death Penalty Project (DPP), ṣiṣẹ pọ pẹlu aṣofin Sosu lati ri i pe ayipada ba ofin naa.
Atẹjade kan lati ọdọ ajọ DPP sọ pe Ghana ni orilẹ-ede kọkandinlọgbọn ni Africa, ati ikẹrinlelọgọfa ni agbaye, to fi opinsi idajọ iku.
Ni ọdun diẹ si asiko yii, awọn orilẹ-ede Africa to ti fi opin si iru idajọ yii ni Benin, Central African Republic, Chad, Equatorial Guinea, Sierra Leone ati Zambia.
Ọgbẹni Sosu sọ pe “ojoojumọ ti awọn ẹlẹwọn to n reti idajọ iku ba jí, ni wọn ma n ro pe o jẹ ọjọ to kẹhin fun wọn nilẹ alaaye.
“Niṣe ni wọn dabi oku to n rìn.”
O ni fifi opin si idajọ iku fihan pe “a ti pinnu gẹgẹ bi awujọ lati má jẹ̀ẹ́ ẹni ti ko ni jẹ́ ẹlẹran ara, ti ko si ni ọlaju.”












