Àwon Mùsùlùmí àtàwon onísẹ̀ṣe tọwọ́ bọ̀wé àdéhùn àlááfíà nílùú Ilorin, wọ́n ní kò sí ìjà ẹ̀sìn mọ́

Ilorin religious crisis

Awon elẹsin Musulumi atawon ẹlẹsin iṣẹṣe ni ilu Ilọrin ti fọwọ siwe adehun alaafia wi pe ki yoo si ija ẹsin tabi jagidijagan botiwu o kere mo laarin awon.

Adehun yii lo waye latari ipade alaafia ti CP Ẹbunoluwarotimi Adelesi pe laarin awon aafaa ati awon oniṣẹṣe Ilọrin lori bi igun mejeeji ṣe n dunkoko mọ ara wọn

Ohun to fa ede aiyede laarin awọn Musulumi atawọn oniṣẹṣe Ilorin

Ilorin religious crisis

Aafaa Okutagidi to ṣoju gbogbo awọn aafaa niluu Ilọrin sọ pe nnkan ẹyọkan tawọn n ja fun ni pe awọn ko faye gba ki awọn oniṣẹṣe ṣe n nnkan miran yatọ si ẹsin Islam.

O ni “Ilọrin ki i bọ nnkankan, o le bọ ọ ninu yara rẹ sugbọn wọn ki i bọ ọ ni gbangba.

O tẹsiwaju pe laye awọn baba nla awọn ni awọn ti n pana ẹbọ ti ko si le bẹrẹ pada lasiko tawọn bayii.

Nigba to n sọrọ lorukọ awon oniṣẹṣe, Ifadara Ifasola jẹ ki o di mimọ pe ohun to ṣokunfa ija ni pe awọn gbọ pe aafaa kan lọ seti odo Iyemọja to wa lagbegbe Oko-Olowo, ti wọn si ni awọn fẹ ro odo.

Lawọn wa wo o pe ti wọn ba ro odo ti aburu si ṣẹlẹ si gbogbo awọn to ba lo omi naa, yoo ba awon oniṣẹṣe lorukọ jẹ nitori odo ti awọn n bọ ni, lawọn ṣe gbe igbesẹ, tawọn aafaa tun fi wa ṣakọlu si ile oun lalẹ ọjọ Isẹgun ọjọ kẹẹdọgbọn, osu Keje yii.

Ifasola ni kii ṣe pe awọn sẹsẹ bẹrẹ iṣẹṣe niluu Ilọrin, awọn ti n ṣe bọ ọjọ ti pẹ ṣugbọn gbogbo igba ni awọn aafaa ma n di awọn lọwọ, koda o ni wọn ti gbiyanju lati dana sun ile bab oun ri.

Ilorin religious crisis

Iyanju ati akitiyan ọlọpaa

Saaju, CP Ebunoluwarotimi Adelesi koro oju mo bi igun mejeeji se n ja lori ẹsin nitori pe ko si ẹni to le gbeja Ọlọrun, o ni ki won gbaju mọ ẹsin wọn ki wọn si fi Olọrun kalẹ lati ja fun ara rẹ.

O gba wọn niyanju ki wọn ba ara wọn lo ninu ifẹ ti awọn ara iṣaaju lo nitori pe ifẹ ni akọkọ ki ẹsin to bẹrẹ

"Kilode ta n gbeja Ọlọrun? Kilode ti onikaluku o sin ohun to ba fẹ sin?”

“Kilode ti ẹ fẹ maa pa ara yin? Ẹyin lo yẹ ki ẹ maa pe ọlọpaa ti Ọlọrun ba fi iṣẹ ran an yin, ki i ṣe ọlọpaa lo yẹ ko maa pe yin.”

Ilorin religious crisis

“Ofin Naijiria sọ pe ominira wa fun ẹsin ti ẹnikẹni ba fẹ ṣugbọn ma fi ni ẹnikeji lara, bẹẹ na ni iwe ofin faye gba gbogbo eniyan lati gbe nibikibi to ba wu u. Ki wa lode ti ẹ fi n ni arayin lara?”

Lẹyin naa lo rọ awon oniṣẹṣe pe ki wọn gba iyọnda lọwọ awon ọmọ onilu ni agbegbe ti wọn ba ti fẹ bọ odo.

Lẹyin awiyewiye awọn ẹlẹsin mejeeji, CP Adelesi ni ki gbogbo awọn aafaa atawọn onisẹṣe to peju sibi ipade ọhun fọwọ si iwe adehun pe alaafia yoo jọba laarin wọn.

O fi kin pe ti wọn ba wa kọ lati gba alaafia laaye, a jẹ pe wọn ṣetan lati foju ba ile ẹjọ.

O tun pasẹ fun awọn ọlọpaa lati bẹrẹ si n lọ kaakiri ojule de ojule ki wọn si ri pe ohun gbogbo nlọ ni ibamu pẹlu ofin.

Awọn aafaa ati awọn oniṣẹṣe naa si fọwọ si iwe ohun, onikaluku si ba tirẹ lọ

Kí ló ń fa gbas-gbos láàrín àwọn Musulumi àtàwọn oníṣẹ̀ṣe nílùú Ilorin? Ohun tí òfin sọ rèé...

Tani Olohun

Oríṣun àwòrán, Tani Olohun

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Awọn agbalagba sọ pe kekere la ti n pẹka iroko, nitori to ba dagba tan, yoo maa gba ẹbọ lọwọ ẹni.

Eyii lo difa fun ija ẹsin to jọ bii eyii to n rugbo bọ bayii niluu Ilorin ati nipinlẹ Kwara.

Gẹgẹ bii awọn fidio to n kaakiri ori ayelujara lẹnu ọjọ mẹta yii, awọn oniṣẹṣe ti fẹsun kan awọn ẹlẹsin Musulumi kan pe wọn n gbogun ti awọn latari pe ilu ẹsin Musulumi ni ilu Ilorin, ati pe ko si aye fun ẹsin iṣẹṣe nibẹ.

Ti ẹ ko ba gbagbe, nnkan bii ọsẹ mẹta sẹyin ni ẹgbẹ awọn Musulumi kan lọ dunkoko mọ Ajisekemi Omolara, to jẹ oloriṣa kan niluu Ilorin yii kan naa.

Gẹgẹ bii ohun ti iya Osun naa sọ fun BBC Yoruba, o ni inu agbo ile oun loun ti fẹ ṣe ọdun naa ṣaaju ki wọn to maa dunkoko mọ oun, koda o ni wọn ṣeleri lati pa oun pẹlu.

Bo tilẹ jẹ pe awọn aṣoju awọn Musulumi kan ni awọn ko lọwọ ninu idunkokomọni naa, ti ileeṣẹ ọlọpaa si sọ pe wọn ko fi ọrọ ọhun to oun leti, Ajisekemo pada gbe ọdun naa kuro niluu Ilroin lọ siluu Eko ni ibẹru fun ẹmi rẹ, gẹgẹ bo ṣe sọ.

Ilorin kii ṣe ilẹ ibọriṣa – Alfa Okuta Agidi

Okuta Agidi

Oríṣun àwòrán, Lere Olayinka

Ọkan lara awọn adari Musulumi to da si ọrọ naa, Okuta Agidi ti sọ pe awọn ko ni gba ki ibọriṣa kankan waye niluu Ilorin.

O ni “Ibi ti awọn Olosun kan wa si lana ree, nibi ti wọn ti wa bọ odo ti ko si ninu iṣẹ ati aṣa ilẹ wa.”

“Ilorin kii bọ odo, a kii bọ odo a kii bọ okuta... ilu Islam ni Ilorin.”

“ A si ke si gbogbo yin, ẹni ẹ ko ni gbọ, ẹ ko ni gba, ibi ti a de duro bayii ko ṣee fẹnu ṣe mọ.”

“Ibi ti a de bayii, gbogbo ẹyin Alfa, ẹ lọ tu aṣiri awọn baba yin jade, gbogbo ohun ti ẹ ba le sa ki aye awọn keferi fi le bajẹ ni ki ẹ ṣe bayii.”

Wọn ni awọn yoo pa mi nitori iṣẹṣe – Afifadara Kinnihun orunmila

Priest Afifadara Kinnihun Orunmila

Oríṣun àwòrán, Priest Afifadara Kinnihun Orunmila

Ọkan lara awọn oniṣeṣe naa, Afifadara Kinnihun Orunmila sọ ninu fidio kan loju opo Facebook rẹ pe awọn kan ti wa dukoko mọ oun nile.

O ṣalaye pe oun ti ke gbajare si ẹgbẹ awọn oniṣẹṣe nipinlẹ Kwara lati da si ọrọ naa.

Gẹgẹ bii ohun to sọ, awọn oniṣẹṣe ko ba ẹnikẹni ja, alafia ni awọn n fẹ ko jọba nipinlẹ Kwara nitori awọn Musulumi naa ti n sun awọn kan ogiri.

Onikaluku lo lẹtọọ lati ṣe ẹsin to ba wu – Tani Olohun

Tani Olohun

Oríṣun àwòrán, Tani Olohun

Oniṣẹṣe kan ti ọpọ awọn ololufẹ rẹ mọ si Tani Olohun ti sọ pe ko tọ ki awọn ẹlẹsin kan maa gbogun ti awọn mii nitori oun ti wọn gbagbọ.

Ọkunrin ọhun, to jẹ ẹlẹsin Musulumi tẹlẹ ko to yipada si ẹsin iṣẹṣe sọ pe niwọn igba ti ofin orilẹ-ede Naijiria ko ti tako iṣẹṣe, ko yẹ ki ofin Ilorin tako ẹsin ọhun.

O ni awọn oniṣẹṣe kii ṣe onijọgbọn, o si yẹ ki awọn ọmọ Naijiria gba alaafia laaye laarin ara wọn lai wo ti irufẹ ẹsin ti onikaluku n ṣe.

Ṣe lootọ ni Ilorin jẹ ilu ẹsin Musulumi?

Gẹgẹ bii ohun ti a mọ, kii ṣe ẹsin Musulumi nikan lo wa niluu Ilorin.

Lootọ ni pe ẹsin naa gbilẹ nibẹ, amọ ọpọ ile ijọsin awọn ọmọlẹyin Kristi pọ kaakiri ilu ọhun, bẹẹ naa ni awọn pasitọ to lorukọ wa lati ipinlẹ Kwara yii, bii Biṣọọbu David Oyedepo, to jẹ alufaa agba ijọ Living Faith Church Worldwide, to jẹ ọmọ bibi ilu Omu-Aran, ni ijọba Irepodun.

Yatọ si awọn ile ijọsin to wa nilu Ilorin, ọpọ awọn ile ẹkọ alakọbẹrẹ ati girama to lorukọ niluu Ilorin lo jẹ eyii ti awọn Kristẹni da silẹ, bo tilẹ jẹ pe ijọba ti n ṣakoso awọn ile ẹkọ naa bayii.

Wayi o, ọpọ eeyan lo n woye boya ẹsin ibilẹ ni awọn Musulumi Ilorin ko fẹ ni tabi gbogbo ẹsin miran to yatọ si ẹsin Musulumi.

Ki ni ofin sọ lori ọrọ ẹsin?

Gẹgẹ bii ohun ti ofin sọ, Naijiria kii ṣe orilẹ-ede ẹlẹsin kan ṣoṣo bii awọn orilẹ-ede bii Iran, Iraq, Saudi Arabia, Pakistan, Afganistan, Yemen, Morcco, Algeria, ati bẹẹ bẹẹ lọ.

To n tumọ si pe ẹsin to ba wu onikaluku lo le ṣe gẹgẹ bii ohun to wa ninu iwe ofin orilẹ-de Naijiria, eyii ti wọn kọ lọdun 1999.

Iwe ofin Naijiria, ori kẹrin, ẹsẹ kejidinlogun, abala kinni sọ pe “gbogbo eeyan lo lẹtọọ si ominira ero, ẹri ọkan ati ẹsin, pẹlu ominira lati kuro ninu ẹsin kan lọ si omiran, ati ominira (yala oun nikan tabi toun ti awọn eeyan miran, wọn si le ṣe eyii ni kọrọ tabi ni gbangba) lati fi ẹsin rẹ han, ṣe itankalẹ ẹsin, tabi igbabọ ijọsin, ikọni ati iṣe ẹsin.”

Abala keji ẹsẹ ofin yii tun sọ pe “ko si ẹnikẹni ti eeyan le fi ipa mu lati ṣe nnnkan ẹsin miran, eyii to tako ẹsin tirẹ tabi ẹsin ti awọn obi tabi alagbatọ rẹ fọwọ si.”

BBC Yoruba kan si agbẹrọjo kan to ni imọ nipa ẹtọ ọmọniyan, Olusegun Kofoworola, o ni o lodi si ofin ki eeyan di awọn ẹlẹsin miran lọwọ lati ṣe ẹsin wọn bo ṣe wu wọn.

Ni ti awọn to sọ pe ilu ẹsin Musulumi ni Ilorin, Kofoworola fi kun pe “Ko si ipinlẹ kankan to ni ofin kankan... ofin to lagbara julọ ni Naijiria ni ofin orilẹ-ede Naijiria, nitori naa, ofin kankan, yala ti ijọba ipinlẹ tabi ibilẹ, ko lagbara ju ofin orilẹ-ede Naijiria lọ.”

O pari ọrọ rẹ pe ofin ni ipinlẹ ohun gbogbo, ko si sohun tabi ẹnikẹni to ju ofin lọ.

Ki ni ijọba Kwara sọ?

Titi akoko ti a n ko iroyin yii jọ, ijọba ipinlẹ Kwara ko tii sọ ohunkohun lori ọrọ yii.

A gbiyanju lati ba ijọba ipinlẹ naa sọrọ lori bi awọn Musulumi kan ṣe n kọju ija si awọn oniṣẹṣe nipinlẹ naa, pabo ni gbogbo akitiyan wa ja si.