Ọ̀pọ̀ ọ̀rẹ́ kọ mi torí mò ń wọ aṣọ ìbílẹ̀, wọ́n ní nǹkan míì wà nídìí rẹ̀ - Bàbá Àṣà
Ọmọ Naijiria to n gbe aṣa Yoruba larugẹ lorilẹ-ede Canada, Olaniyi Oyatoye, ti apẹle rẹ n jẹ baba Aṣa, ti sọ pe ọpọlọpọ afani loun ti ri nipa ṣiṣe bẹẹ.
Ninu ifọrọwerọ pẹlu BBC Yoruba, Oyatoye sọ pe lọpọ igba ti awọn oyinbo alawọ funfun ba pade oun ni wọn maa n fẹ di ọrẹ oun lati mọ si nipa aṣa Yoruba.
O ni lọpọ igba lawọn ọdọ bii ti oun maa n wo o pe ko ni itumọ bi oun ṣe n mura bii ọmọ Yoruba atata, eyii to maa n mu irẹwẹsi ba ọkan oun nigba mii, ṣugbọn gbigbe aṣa Yoruba larugẹ ti mu ki oun pade awọn lọbalọba ilẹ Yoruba.
O ni “o fun mi ni anfani lati maa ba ọba ṣe, lati maa ba ijoye ṣe, lati maa ba ijọba ṣe, paapaa julọ laarin awọn alawọ funfun.”

"Awọn ọre mi kan fi mi silẹ nitori bi mo ṣe mura ni ilana aṣa Yoruba"
Oyatoye sọ pe “Mo ni awọn kan to jẹ pe wọn ko ba mi ṣe mọ, ti wọn jẹ bii ọrẹ.”
“Nitori wọn ni igbagbọ pe bi mo ṣe n ko ilẹkẹ si ara, pe mo ti gba nnkan mii mọ.”
“Ti ẹ ba ri ọmọ Yoruba to de olonde sara bayii, o de olonde naa ki wọn ma baa yin ni ibọn ni.
Sugbọn ti awọn kan ba ri, wọn a sọ pe o ti lo oogun sara, ṣugbọn ti wọn ba ri ọlọpaa to de ayẹta mọra kii ṣe ẹṣẹ, amọ iṣẹ kan naa ni mejeji n ṣe.”
O ni ọpọ eeyan lo gbagbọ pe oogun oyin dara lati wo aisan amọ ẹṣẹ ni lilo agbo ibilẹ.
Gẹgẹ bo ṣe sọ, ọpọlọpọ pasitọ lo n lo ‘hand band’ amọ wọn tako lilo ilẹkẹ gẹgẹ bii ọmọ Yoruba.
Oyatoye pari ọrọ rẹ pe ọpọ ọmọ Yoruba lo nilo lati tu ero wọn pa, ki wọn si yi igbagbọ wọn pada nipa ohun to rọ mọ aṣa ilẹ baba wọn.
Ẹkunrẹrẹ ohun ti Baba Aṣa sọ wa ninu fidio oke yii.



