Gomina Adeleke yan àwọn Kọmísọ́nà rẹ̀, ohun náà náwọ́ gan ipò kọ́misọ́nà kan fún ara rẹ̀

Oríṣun àwòrán, OTHERS
Gomina ipinlẹ Osun, Ademola Adeleke ti pada mu ireti pipẹ awọn eniyan ṣẹ ni ọjọ kọkandinlogun oṣu keje lẹyin to fẹẹ to oṣu mẹjọ nipa yiyan awọn kọmisọna ti yoo ba a ṣiṣẹ ni ipinlẹ Osun.
“A ti ṣe aṣeyọri nipa didoola ipinlẹ Osun kuro ninu irinajo ajorẹyin. A ti gbe ipinlẹ naa soju ọna idagbasoke ọlọjọ pipẹ.”
Eyi n waye lẹyin ọpọlọpọ oṣu to ti gori alefa gẹgẹ bi gomina koda, ọpọ ojo ti rọ ti ilẹ ti fa a mu ti awọn eeyan si n reti pe yoo yan awọn kọmisọna.
Lara awọn nnkan gboogi to ti ṣẹlẹ ni ẹjọ to ti waye laarin oun ati gomina ana, Alhaji Gboyega Oyetola to wọ ọ lọ ile ẹjọ titi wọn ṣe ba ara wọn de ile ẹjọ to ga julọ niluu Abuja ti wọn si da Ademola Adeleke lare.
Awọn eeyan kọkọ n woye pe boya tori ẹjọ yii ni ko ṣe tii yan awọn ti yoo ba a ṣiṣẹ pe o n wo ibi ti yoo ja si amọ ẹjọ naa ti pari o ti le loṣu bayii.
Nigba to n sọ ọrọ rẹ nibi ayẹyẹ iburawọle awọn kọmisọna naa, Adeleke ṣapejuwe eto naa gẹgẹ bi eyi to laami laaka ninu iṣejọba rẹ to si ni ikọ tuntun yii “yoo wa ọkọ awọn afojusun wa fun ipinlẹ Oṣun tuntun de ebute ayọ”.
Ki lo de gan ti Adeleke ṣe pẹ yan awọn kọmisọna?

Oríṣun àwòrán, OTHERS
Ninu ọrọ rẹ, Adeleke to jẹ gomina ẹlẹẹkẹfa fun ipinlẹ Osun yii jẹ ko di mimọ pe idi ti ipenija fi wa lojuna yiyan awọn ti yoo ba a ṣiṣẹ ni pe titi di oṣu to kọja lọ yii, ile igbimọ aṣofin ipinlẹ naa ṣi wa labẹ idari ẹgbẹ oṣelu APC o si tọka si eyi nibi eto ibura wọle naa pe fun odidi oṣu mẹjọ ni oun fi da ṣe alabaṣiṣẹpọ ara oun.
O wa rọ awọn to ṣẹṣẹ yan sipo lati gbaradi fun iṣẹ to wa niwaju wọn to si ni pe gẹgẹ bi oun ṣe ti n da a ṣe latọjọ yii, igbimọ alaṣẹ ti oun yan yii yoo tun ran ijọba oun lọwọ lati ṣe iṣẹ sii ni.
“Gẹgẹ bi ẹ ṣe n wọle yii, iṣẹ to wa niwaju wa pọ bẹẹ si ni a ni iṣẹ ṣiṣe lati ṣe amulo gbogbo ohun ti wọn ro pe ko ni ṣee ṣe ko di ṣiṣe. A gbọdọ ṣe agbende ọrọ aje wa, ka pawo wọle, jẹ ki awọn ọdọ wa ri ṣe, ka gba eto ọrọ aje igbalode mọra ka si ṣe amulo aato fun ayipada oju ọjọ”.
Gomina Adeleke ni oun mọ pe awọn ti oun yan yii kun fun ọpọlọpọ oniruuru ọgbọn lati mu agbega de ba ipinlẹ Osun.
“Mo lero pe ọwọ ati ori yin kun fun ọpọlọpọ ọna abayọ si iṣoro to wa nilẹ lasiko wa yii, mo si fẹ ki ẹ bẹrẹ si ni mu wọn wa.”
Adeleke sọ fun wọn pe wọn yoo ri oun gẹgẹ bii adari ijọba to ṣetan lati gbaruku ti awọn aba daadaa wọn.
Koda o ni awọn yoo ṣe ipade apero kan eyi ti yoo gbaradi fun awọn gidi gan lati ṣe amuṣẹ gbogbo erongba ati aato wọn gẹgẹ bi ijọba.
Bakan naa, Adeleke ni oun n fẹ ki ajọṣepọ to dan mọran wa laarin awọn oṣiṣẹ ijọba atawọn ti wọn ṣẹṣẹ yan sipo tori alabajọṣiṣẹpọ ni awọn fun ilọsiwaju.
O jẹ ko di mimọ pe ireti awọn ara ipinlẹ Osun pọ gan bẹẹ si ni awọn ko ni ja wọn kulẹ dipo rẹ, iṣejọba oun yoo tun ro akitiyan wọn lagbara sii ni lati lee mu gbogbo ileri ti wọn ṣe ṣẹ.
“Bi a ba le ṣe aduru ohun taa ṣe gẹgẹ bii ijọba to jẹ alabaṣiṣẹpọ ara rẹ, ikọ wa yoo lagbara gan gẹgẹ bi igbimọ alaṣẹ ipinlẹ bayii.” Adeleke sọ bẹẹ.
Ipo kọmisọna wo ni Adeleke yan fun ara rẹ?
Iroyin to jade ni pe bi gomina Ademola Adeleke ṣe yan awọn si ipo naa ni o kede pe oun fura rẹ ni yoo moju to iṣẹ ode gẹgẹ bii kọmisọna fun ọrọ iṣẹ ode.
Bakan naa ni o ni igbakeji rẹ, Ọmọba Kola Adewusi ni yoo boju to ọrọ ere idaraya ati akanṣe eto.
Awọn to ku ni:
Dr B.T Salam
Hon. Morufu Dele Ayanfe
Mr. Moshood Olagunju
Mrs. Adenike Folasade Adeleke
Barrister Dosu Babatunde
Mr. Alfred Sesan Oyedele
Reverend Bunmi Jenyo
Hon George Alabi
Mr. Sola Ogungbile
Professor Morufu Ademola Adeleke
Barrister Wole Jimi-Bada
Hon. Dipo Eluwole
Mr. Gbola Faseru
Barrister Sola Akintola
Hon. Mayowa Anjorin
Barrister Kolapo Alimi
Alhaji Aderibigbe Rasheed
Hon Ayobola Awolowo
Hon Ojo Abiodun Bankole
Alhaji Abdulganiyu Ayobami Olaoluwa
Hon. Sunday Oroniyi
Hon. Biyi Odunlade
Mr. Soji Adeigbe
Hon Festus Adeyemo
Adeleke ni awọn ti oun gbe oriyin fun lori aṣeyọri yii ni ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party ni ipinlẹ Osun fun ipa aṣaaju ti wọn ko ninu yiyan awọn ti yoo ṣiṣẹ to si ni oun gba ipinu ẹgbẹ wọle tori pe ipinu awọn to di kọmisọna yii jẹ latọwọ awọn ti ọrọ kan gangan.
O wa gba wọn niyanju pe ki wọn rii pe afojusun wọn jẹ lati sin awọn eniyan ninu otitọ ati pe ẹni to ba hu iwa ọbayejẹ yoo foju wina ofin gidi gan.
“Gẹgẹ bi gbogbo wa ṣe mọ, mo jẹ ẹni to fẹran ajọṣiṣẹpọ, ko ni si aye fun aladanikanṣe ninu iṣejọba wa. Ẹ gbudọ ṣiṣẹ pọ gẹgẹ bi ikọ to ni erongba kan naa ni lati mu ayipada ba igbe aye awọn eniyan wa.”















