Wo àwọn ohun tí Makinde, Abiodun àtàwọn míì pèsè fárá ìlú lórí bí ìjọba ṣe yọ Subsidy

Oríṣun àwòrán, Others
Bi pupọ awọn ọmọ Naijira se n kọminu lori igbesẹ ijọba apapọ lati yọ owo iranwọ Subsidy ni awọn Gomina ipinlẹ kọọkan ti bẹrẹ lati ma gbe igbesẹ lati mu ayẹdẹrun fun awọn osisẹ, ati awọn osisẹ fẹyẹnti.
Ileeṣẹ BBC News Yoruba se akọsilẹ iyatọ to wa ninu awọn igbeṣẹ awọn gomina wọnyi lati mu igbe aye dẹrun fun awọn araalu ati awọn osisẹ.
Ipinlẹ Oyo
Saaju ninu oṣu kẹfa ni gomina ipinlẹ Oyo, Seyi Makinde kede pe oun ti pese ọkọ ni oni jaburata fun awọn osisẹ , to si tun kede pe oun ti gbe igbimọ kalẹ lati bẹrẹ igbesẹ lori bi afikun yoo se de ba owo oṣu aweọn osisẹ.
Gomina ni lati le mu idikun ba nira ti awọn eeyan n dojukọ ni lati pese ohun iranwọ fun wọn, eyi ti yoo mu nnkan dẹ diẹ.
Bakan naa ni Gomina tun kede pe oun ko ni fowokun owo ọkọ fun araalu si awọn ọmọ ile ẹkọ ati awọn agbalagba yoo si ni anfani lati san idaji owo ọkọ naa.\
Ipinle Ogun
Gomina ipinlẹ Ogun, Dapo Abiodun ti ni oun ti se awọn eto silẹ fun awọn araalu lati se iranwọ lasiko ọwọngogo epo bẹntirol yii.
Ninu atẹjade ti gomina naa fi lede loju opo Twitter rẹ lo ti salaye awọn eto tuntun naa.
O ni on mọ pe ayọkuro owo iranwọ epo bẹntiro mu ki nkan buru lati aye nira fun awọn araalu.
Gomina ipinlẹ Ogun ni awọn nkan ti oun yoo pese fun awọn araalu ni;
Ipinle Kwara
Gomina ipinlẹ Kwara, AbdulRahman AbdulRazaq ti buwọlu afikun ẹgbẹrun mẹwaa sowo oṣu awọn osisẹ nipinlẹ naa.
Gomina kede ọrọ yii ninu atẹjade kan to buwọlu fun awọn akọroyin ni afikun naa yoo bẹrẹ ninu oṣu keje, ti yoo si wa titi ijọba yoo fi kede owo oṣu tuntun fun awọn osisẹ
Bakan naa Gomina ti buwọlu owo toto milọnu ọọdẹgbẹta naira lati le se iranwọ fun awọn ontaja nipinlẹ Kwara
Ipinlẹ Edo
Ijọba ipinlẹ Edo naa pẹlu ipinlẹ Kwara lati kede afikun owo oṣu fun awọn osisẹ lati N30000 si N40000
Bakan naa ni ijọba kede adikun si iye ọjọ ti awọn osisẹ yoo fi ma wa si ibi isẹ lọsẹ, lati ọjọ marun un si mẹta , ti wọn yoo si ma se isẹ ni ile fun ọjọ meji yooku.
Ipinlẹ Imo
Ninu atẹjade ti agbẹnusọ ijọba ipinlẹ Imo, Oguwike Nwachukwu fi lede fun akọroyin kede pe ijọba ti fowokun owo oṣu awọn osisẹ pẹlu ẹgbẹrun mẹwaa
Bakan naa ni Gomina Hope Uzodimma pese afikun ọkọ ti yoo ma gbe awọn osisẹ wa si ibi isẹ lati pada lọ si ile wọn.
Ipinlẹ Ebonyi
Ipinlẹ miiran to pẹlu awọn ipinlẹ to fowokun owo oṣu awọn osisẹ pẹlu ẹgbẹrun mẹwaa ni ipinlẹ Ebonyi
Gomina Nwifuru Francis Ogbonna tun buwọlu igbanisisẹ osisẹ to to ẹgbẹrun kan le diẹ sinu isẹ ijọba















