Ibadan lá ti gbérò Mecca láti ìpínlẹ̀ Oyo lọ́dún 2024 – FAAN

Papakọ ofurufu Ibadan

Oríṣun àwòrán, FAAN

Ajọ to n se akoso eto irinna ofurufu ni Naijiria, FAAN, ti fi ọwọ idaniloju sọya pe bẹrẹ lati ọdun to n bọ lọ, papakọ ofurufu to wa nilu Ibadan ni awọ̀n ero Mecca yoo ti maa tẹ baalu leti lọ silẹ Saudi Arabia fun isẹ Hajj wọn.

Ọga agba fun ajọ FAAN, Oloye Adedeji Afolabi lo fọwọ idaniloju bẹẹ sọya lasiko to se ago laafin si Olubadan tilẹ Ibadan, Ọba Lekan Balogun ni aafin rẹ to wa ni Alarere nilu Ibadan.

Titi di akoko yii, ilu Eko ni awọn arinrinajo Hajj lati ipinlẹ Oyo ti maa n lọ wọ baalu lọ fun isẹ Hajj ni Saudi Arabia.

Adedeji wa salaye pe agbega ti ba papakọ ofurufu to wa nilu Ibadan lati kuro ni eyi to le gba baalu to n fo labẹle, o si ti di eyi to le faaye gba baalu to n fo lọ silẹ okeere.

Bakan naa lo wa yan pe igbesẹ mimu agbega ba papkọ ofurufu ilẹ Ibadan naa seese nitori atilẹyin gomina Seyi Makinde, ẹni to gbe owo tuulu kalẹ fun isẹ akanse naa.

Bi kii ba se awọn asise kan to yọju, papakọ ofurufu Ibadan ni a ba ti ko awọn alalaji lati ipinlẹ Oyo lọ si Mecca lọdun yii - FAAN

Adedeji fikun pe gbogbo agbegbe papakọ ofurufu naa lo ti rẹwa si, eyi to mu ko ni aabo to peye fun awọn ero to ba fẹ gbera lati papakọ ofurufu naa.

“Bi kii ba se awọn asise kan to yọju, papakọ ofurufu Ibadan ni a ba ti ko awọn alalaji lati ipinlẹ Oyo lọ si Mecca lọdun yii.

Gomina Makinde si lo gbe owo nla kalẹ ta fi se aseyọri nidi agbega papakọ ofurufu naa, ibẹ si la ti gbe ero Mecca lọ fun Hajj lọdun to n bọ.”

Adedeji wa fikun pe awọn onimọ ẹrọ ni papakọ ofurufu naa lo mu ki awọn ina, maa tan nibẹ, ti oju ọna ibẹ si ti di onibeji.

Ọga agba ajọ FAAN naa wa lu gomina ipinlẹ Oyo lọgọ ẹnu fun atilẹyin alailẹgbẹ lori aseyọri isẹ naa.

"Gomina Makinde lo gbe owo nla kalẹ ta fi se aseyọri nidi agbega papakọ ofurufu"

Bakan naa lo wa yan pe igbesẹ mimu agbega ba papakọ ofurufu ilẹ Ibadan naa seese nitori atilẹyin gomina Seyi Makinde, ẹni to gbe owo tuulu kalẹ fun isẹ akanse naa.

“Bi kii ba se awọn asise kan to yọju, papakọ ofurufu Ibadan ni a ba ti ko awọn alalaji lati ipinlẹ Oyo lọ si Mecca lọdun yii.

Gomina Makinde si lo gbe owo nla kalẹ ta fi se aseyọri nidi agbega papakọ ofurufu naa, ibẹ si la ti gbe ero Mecca lọ fun Hajj lọdun to n bọ.”

Adedeji wa fikun pe awọn onimọ ẹrọ ni papakọ ofurufu naa lo mu ki awọn ina, maa tan nibẹ, ti oju ọna ibẹ si ti di onibeji.

O fikun pe gbogbo agbegbe papakọ ofurufu naa lo ti rẹwa si, eyi to mu ko ni aabo to peye fun awọn ero to ba fẹ gbera lati papakọ ofurufu naa.

Ọga agba ajọ FAAN naa wa lu gomina ipinlẹ Oyo lọgọ ẹnu fun atilẹyin alailẹgbẹ lori aseyọri isẹ naa.

Olubadan Lekan Balogun

Oríṣun àwòrán, Lekan Balogun

Kí ni Olubadan sọ?

Olubadan tilẹ Ibadan, Oba Lekan Balogun, lasiko to n fesi, wa fi idunnu rẹ han pe iroyin ayọ ni iroyin naa nitori pe papakọ ofurufu naa ti di papakọ ofurufu agbaye to le gba baalu ilẹ okeere.

Bakan naa ni Olubadan kan saara si Gomina Makinde pe o kare, lori agbega nla to mu ba papakọ ofurufu Ibadan naa.