Ọlọ́kadà t'órí kó yọ nínú ìbúgbàmù ní Ore ṣàlàyé ohun tí ojú rẹ̀ rí

Arakunrin Awalu Salihu sọ bori ṣe ko yọ

Oríṣun àwòrán, Nigerian Tribune

Ọkan alara awọn to moribọ ninu ibugbamu ọkọ bẹntiroo to mi ilu Ore jiji lọjọ Aiku ti n ṣalaye ohun toju rẹ ri fawọn akọroyin.

Awalu Salihu to n ṣiṣẹ ọlọkada sọ fun ileeṣẹ iroyin Naijiria,Nigerian Tribune pe oun naa gbiyanju lati bawọn bu epo bẹntiroo to n danu lara ọkọ tanker yi lẹyin to fẹgbẹ lelẹ.

O to eeyan ogun ti awọn aaraadugbo n sọ kaakiri loju opo ayelujara pe o ba iṣẹlẹ yi lọ.

Pupọ n gba itọju lọwọ amọ ileeṣẹ ọlọpaa sọ pe oku eeyan mẹjọ lawọn yi ti ri nibi iṣẹlẹ naa.

Awalu ṣalaye pe awakọ ọkọ naa ko ribi dari ọkọ ọhun to si yi danu sinu koto.

Nibẹ naa lo wa ti epo bẹntiroo to gbe si bẹrẹ si ni danu sinu odo kekere kan to wa lagbegbe ọhun.

Awalu to jẹ ọmọ bibi ilu Sokoto sọ lede Hausa rẹ pe awọn to n gbe itosi ibi iṣẹlẹ yi bẹrẹ si ni ko ike ati nkan miran lati wa gbọn epo to danu.

''Emi naa gbe ọkada mi si ẹgbẹ kan ti mo si darapọ mọ wọn''

Awalu sọ pe niṣe ni awakọ tirela naa ati ọmọ iṣẹ rẹ n wo bawọn eeyan ṣe n gbọn epo to danu.

Amọ o sọ pe ko pẹ si igba naa lawọn gbọ ibugbamu kan ṣugbọn ọpọ eeyan ko kọbi ara si.

O ni ina ti bẹrẹ si ni tọ ibugbamu yi bọ lori omi amọ awọn eeyan ko fura.

''Ko pẹ si igba yi la tun gbọ ibugbamu ẹlẹẹkeeji. Ka to mọ ohun to n ṣẹlẹ, ina ti gba gbogbo ayika wa''

O ni awọn tawọn n gbọn epo fẹ ẹ to ọgọrun eeyan.

O ni awọn ṣare kuro nibẹ.Awọn mii to n gbinyanju lati gbe epo ti wọn gbọn sare kuro nibẹ lo sọ pe ina ran mọ wọn lara.

Ọpọ ni ko ba ku kani pe ibugbamu naa ṣẹlẹ lati ẹnu tanker epo gangan

Ninu alaye rẹ, Awalu sọ pe ina to sọ kii ṣe lara tanker to danu lo ti ṣẹlẹ.

O ni ibi tawọn eeyan n gbe ni itosi lo ti waye ati pe arabinrin kan to n dana nibi to ti ṣẹlẹ ku loju ẹsẹ ni.

Bakan naa ni olugbe adugbo naa kan Tijani Diekola sọ pe iṣẹlẹ naa ko ṣoju oun amọ oun tara pada sile lati lọ wa ibatan rẹ kan ti wọn ko ri.

Diekola sọ pe ''Nkan bi iṣẹju diẹ lẹyin ibugbamu naa ni mo debẹ.Mo ri oku awọn eeyan ti ina ti jo nilẹ.O lagbara debi pe ko si ẹni to le sunmọ ibugbamu yi.''

O ni laarọ ọjọ Aje yi lawọn mọlẹbi pada wa lati wo oku awọn eeyan wọn.

''Ko si ẹni to moribọ ninu awọn ti ina mu yi.Pupọ lawọn eeyan ko si damọ ninu awọn ti ina jo ninu iṣẹlẹ yi.''

Ọ̀pọ̀ èèyàn kú níbi tí wọ́n ti n bu bẹtirò lára Tanker tó ṣubú ní Ore
Ibi to jona

Oríṣun àwòrán, AFOLABI KAYODE

Ko din ni eeyan mẹwaa to ku lasiko ti wọn n bu epo bẹtiro to danu lara ọkọ agbepo kan to ṣubu nilu Ore, ijọba ibilẹ Odigbo, nipinlẹ Ondo lọjọ Aiku.

Agbẹnusọ ọlọpaa nipinlẹ Ondo, SP funmilayo Odunlami sọ fun BBC pe eeyan mẹjọ ni awọn ri akọsilẹ gba nipa rẹ lọjọ kẹtalelogun, oṣu Keje ti iṣẹlẹ naa waye, pe o kú.

SP Odunlami ṣalaye pe nibi ti awọn eeyan naa ti n bu epo ni ọkọ nla naa ti gbina.

Awọn ti iṣẹlẹ naa ṣoju wọn, sọ fun iwe iroyin The Nation pe foonu ọkan lara awọn to n bu epo bẹtiro tó dún, lo mu ki ọkọ agbepo naa gbina.

Botilẹ jẹ pe ileeṣẹ ọlọpaa sọ pe eeyan mẹjọ ṣi ni awọn le sọ pe o kú ninu iṣẹlẹ naa, awọn araalu n sọ lori ayelujara pe o to ogún eeyan to ku.

Iroyin sọ pe obinrin alaboyun kan, ati ọmọde mẹta naa wa lara awọn to ku.