Ta ni Cecilia Abena Dapaah,Mínísítà Ghana tó làwọn ọmọ ọdọ̀ jí $1m nílé rẹ̀

Aworan Minisita Cecilia

Oríṣun àwòrán, MINISTRY OF SANITATION AND WATER RESOURCES/ FACEBOOK

Aarẹ Ghana Nana Akufo-Addo ti tẹwọ gba ikọwefiposilẹ Minisita feto imọtoto ati ọrọ alumọni omi lorileede naa .

Ko si sẹyin awuyewuye to waye lẹyin ti minisita naa sọ pe awọn ọmọ ọdọ oun ji miliọn dọla kan ti oun ko pamọ sile ni Accra.

Kaakiri oju opo ayelujara ni ọrọ yi ti gbalẹ ti ọpọ si n beere pe nibo ni Minisita naa ti ri aduru owo yi.

Agbẹnusọ ile ijọba Jubilee House, ni Ghana, Eugene Arhin lo kede ọrọ yi ninu atẹjade kan.

Atẹjade naa sọ bayii pe ''Aarẹ Akufo-Addo kan saara si Cecilia Dapaah fun ifarajin ji rẹ ati ifọkansi mimu idagbasoke ba ijọba ati orileede Ghana. Aarẹ gbadura aṣeyọri ninu ilakaka rẹ''

Ọpọ ni Ghana to fi mọ awọn ajafẹtọmọniyan ati ẹgbẹ to tako iwa ajẹbanu lo ti n beere pe nibo gaan an ni o ti ri owo yii.

Bẹẹ lawọn mii n beere pe bawo ni oṣiṣẹ ijọba yoo se ni aduru owo yi ni ipamọ lasiko ti gbogbo orileede n kerora eto ọrọ aje to dẹnukọlẹ.

Lọjọ Ẹti ni awọn oniroyin labẹle gbe iroyin pe awọn ọmọ ọdọ minisita naa meji kan ati awọn eeyan mẹta miran n kawọ pọnyin rojo ni ile ẹjọ kan ni Accra.

Wọn fẹsun kan wọn pe wọn ji miliọnu dọla kan,ẹgbẹrun lọna ọọdunrun owo pọun,€300,000,aimọye miliọnu owo Ghana to jẹ Cedi ati awọn nkan miran nile minisita loṣu kẹwa ọdun 2022.

Ninu atẹjade to kede ikọwefiposilẹ Minisita Dappah, o sọ pe ''mo le fi gbogbo ọwọ mi sọya pe iye owo ti wọn gbe sita ko ṣe dede nkan ti emi ati ọkọ mi kọ silẹ lọdọ awọn ọlọpaa.Mo mọ nkan ti iru iroyin bẹẹ tunmọ si fun eeyan to ba wa ni iru ipo ti mo wa''

O fi kun pe ''Mo ṣetan lati fọwọ sowọpọ pẹlu awọn alaṣẹ lati le fi idi ododo mulẹ.''

A gbọ pe ọmọ ọdọ fi owo yi jaye ọba, koda o ra awọn nkan meremere bi ile, ọkọ ati awọn ẹṣọ olowiyebiye.

Olori ẹgbẹ alatako to fi igba kan jẹ aarẹ Ghana Johna Mahama ko dakẹ lori ọrọ yi loju opo Twitter rẹ.

O ni ọrọ naa tabuku eeyan pupọ.

O beere pe'' koda ko ṣe pe owo naa jẹ owo ẹtọ,ki lo de ti eeyan yoo fi ko aduru owo yi sile ?''

Awọn aṣofin ilẹ Ghana ti pe fun iwadii to munadoko lati fi mọ wulẹwulẹ ibi ti Minisita yi ti ri owo naa to jọ pe oun lo nii.

Amọ ṣa ta ni Minisita taa n sọrọ nipa rẹ yi gaan?

Cecilia Abena Dapaah

Cecilia Abena Dapaah jẹ oloṣelu7 lorileede Ghana to ti n ba ijọba ṣiṣẹ lati ọdun 2001.

O ṣaaju ba aarẹ John Kuffour ṣiṣẹ laarin ọdun 2001 si 2005 gẹgẹ bi oluranlọwọ pataki ko to wa gba ipo ọga ajọ to n mojuto ọrọ ipese Cocoa ni Ghana.

Lẹyin igba naa lo di Minisita fọrọ alumọni omi iṣẹ agbaṣe ati eto ile igba lọdun 2005.

Ni 2009 o jaweolubori di aṣoju nile aṣofin fun ẹkun idibo Bantama nibi to wa lati ọdun 2009 titi di 2023.

Lati oṣu kini ọdun 2017 o di minisita akọkọ ti ijọba Akuffo addo yan sipo lati mojuto ileeṣẹ irina ofurufu.

Nigba ti Aarẹ Akufo ṣe atunto ipo awọn minisita lo ba gbe ipo fun gẹgẹ bi Minisita adari ileeṣẹ alumọni omi ati imọtoto ayika.

Ibẹ lo wa lati igba ti aarẹ wọle sipo pada fun saa ẹlẹẹkeeji.