Ikú dóró! Sunday Igboho pàdánù ìyá rẹ̀

Oríṣun àwòrán, Others
Adigbara fun orilẹede Yoruba, Sunday Adeyemo ti ọpọ mó si Sunday Igboho ti padanu iya rẹ.
Ikede yii lo wa loju opo ayelujara Sunday Igboho, ti agbẹnusọ rẹ, Olayomi Koiki si fidi rẹ iroyin naa mulẹ.
Gẹgẹ bi Koiki se sọ, o ni Iya Igboho jade laye lọjọ Kejilelogun, oṣu keje ọdun 2023.
"Mo n fi idi rẹ mulẹ loni, Ọjọ kejilelogun, oṣu keje ọsun 2023 pe Oloye Sunday Adeyemo, ti ọpọ mọ si Sunday Igboho ti jade laye."
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post
Ninu ọrọ rẹ, Oloye Adeyemo ni o se ni laanu pe iya oun ti fi oun nikan silẹ ninu aye yii nibi ti oun ko ti eeyan foju jọ.
"N ko ti fẹ ko lọ bayii, N ko fẹ ko fi emi nikan silẹ ninu aye yii.
"Iya mi, tani ki n kọju si bayii?
"O nira fun mi lati sọ pe o di gba ose nitori eyi pọju fun mi lati gbe ."
Ti a ba gbagbe, saaju ni Agbẹjọro Sunday Igboho, Pelumi Olajengbesi fi idi rẹ mulẹ pe gbajugbaja ajafẹtọ iran Yoruba naa ko ni pẹ pada si orilẹede Naijiria.
Sunday Igboho lo di ero ahamọ lorilẹede Benin lọdun 2021 lẹyin ti ajọ DSS se ikọlu si ile rẹ lori ẹsun pe o n pe fun Idasilẹ orilẹede Ilẹ Yoruba.
Olajengbesi ninu ifọrọwerọ to se pẹlu Ileeṣẹ BBC News Yoruba ni gbogbo eto lo ti bẹrẹ lati se ayẹyẹ ipadabọsile Sunday Igboho laipẹ















