Wo oúnjẹ oníkóró mọ́kànlá tó yẹ́ kí ó má a jẹ láti dènà àìsàn ní àgọ́ ara rẹ

Aworan

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Kini a n pe ni woro irugbin ti awọn oloyinbo n pe ni Cereal? Awọn ni ounjẹ ti awọn agbẹ ma n gbin kooro wọn, ti o si see jẹ.

Wọn ma n gbin awọn koro yii ni ọgọọrọ ni fun awọn eniyan lati ri ounjẹ jẹ ati fun awọn nnkan ọgbin.

Lai tii sè é, awọn ounjẹ yii ni ohun aṣaraloore bii vitamins, minerals, carbohydrates, fat, oils ati proteins.

A ṣe akojọpọ irugbin oniworo mọkanla to dara fun ara rẹ ati ẹbi rẹ, lati dena oriṣiriṣi aisan ati aarun ni agọ ara.

Awọn wooro irugbin mọkanla naa ree:

Wheat (Triticum) – Alikama

Aworan

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Alikama jẹ ọkan lara awọn ounjẹ ti awọn eniyan ma n jẹ ju, ti o si ma n ṣe ara loore.

Bakan naa ni o ma n fun eniyan ni eroja asaraloore carbohydrates.

Alikama ma n da abo bo ara lọwọ aisan ọkan, aisan rọpa-rọṣẹ, awọn aisan jẹjẹrẹ kan to fi mọ aisan itọ suga keji.

Wọn ma n lo Alikama lati fi se burẹdi, pasta, couscous, semolina ati bulgur.

Barley - Koro Barli

Aworan

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Koro Barli ti o wọpọ julọ ni Pearl barley to si ni awọn ohun asaraloore to dara fun agọ ara.

O ma n pese fibre fun ara to fi mọ beta-glucan, ti o ma n jẹ ki ara ji pepe, amọ ki n mu ki ebi pa eniyan ju bi o ṣe yẹ lọ.

Nitori o ni gluten, ko dara fun awọn to ba ni aisan to nii se pelu gluten.

Agbado

Aworan

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Agbado jẹ ọkan lara awọn irugbin to wọpoọ ni agbaye ti o si jẹ pe ọpọ eniyan ni o ma n jẹ.

O ma n pese Vitamins, minerals, fibre, to fi mọ carotenoids ati zeaxanthin fun agọ ara.

Wọn ma n fi agbado ṣe ẹkọ ati ọpọlọpọ nkan miran fun ounjẹ jijẹ to n se ara loore.

Millet – Jero

Aworan

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Bi o tilẹ jẹpe o dabi koro, o dara pupọ fun ara to si ni ọpọlọpọ eroja bii fibre, protein ati awọn eroja ara to n gbogun ti aisan.

Bakan naa ni o ma n da aabo bo ara lọwọ aisan itọ ṣuga.

Koro Oats

Aworan

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Koro Oats dara fun ara to si ni awọn eroja bii fibre, beta glucan ati soluble fibre fun ara.

O ma n se awọn ẹya ara loore nipa pipese awọn eroja ti ara nilo lati ṣiṣẹ daradara.

Oats naa ma n fun agọ ara ni anfaani lati dagba daradara lai si aisan ninu awọn ẹya ara to ṣe koko.

Irẹsi

Aworan

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Irẹsi wa lara awọn ounjẹ onikoro ti awọn eniyan fẹran lati maa jẹ julọ to si n fun awọn eniyan ni agbara.

Kaakiri agbaye ni awọn eniyan ti n jẹ irẹsi yala ki wọn se ko rọ daradara, abi ki wọn ṣe diẹ.

Awọn eroja ara to wa ninu irẹsi naa ni flavonoids, apigenin ati quercetin to n da abo bo awọn eniyan lọwọ aisan.

Rye - Woro irugbin

Woro yii dara fun agọ ara to si ni awọn eroja bii lignans to si ma n mu ki ara dagba bi o ṣe tọ ati bi o ti yẹ.

Bakan naa ni o ma n mu adinku ba aisan ọkan, aisan to niise pẹlu nnkan oṣu obinrin, to fi mọ aisan ẹsẹ didun ati aisan jẹjẹrẹ ọyan.

Sorghum - Ọkà baba

Aworan

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Bi o tilẹ kẹpe ọpọ eniyan ko mọ ọ, o jẹ irugbin ti awọn eniyan fẹran ni agbaye.

Awọn eniyan ma n se bii irẹsi, ti wọn si le lo o lati fi ṣe agbado abi nkan miran.

O ni eroja bii ọra ati fibre to n se ara loore.

Koro yii ni awọn onimọ ni o dara ju wheat lọ nitori o tun ni awọn eroja aṣaraloore miran.

Triticale - Woro 'Triticale'

Woro yii ni o jẹ ala laarin wheat ati rye, ti wọn si ni o ni eroja protein ju awọn akẹgbẹ rẹ lọ.

O ni eroja bii minerals ati vitamins ti gluten ara rẹ si dara ju wheat lọ.

Wọn ma n lo fun burẹdi ati wheat flour bakannaa, ti awọn miran si ma n ṣe adalu rẹ.

Buckwheat - Woro 'Buckwheat'

Aworan

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Woro 'Buckwheat' ni wọn ṣe apejuwe pe o ni awọn eroja to n dena aisan pupọ, to si dara ju ọpọlọpọ koro lọ, to fi mọ oats ati wheats.

Bakan naa lo ni awọn eroja bii rutin ati awọn eroja miran bii inositol to le gbodun ti aisan suga.

Quinoa - Woro 'Quinoa'

Koro Quinoa ni wọn ṣapejuwe pe o ni awọn eroja to n gbogun ti awọn kokoro aifojuri, to si dara fun itọju alaisan, ki ara rẹ bale tete ji pepe.

Bakan naa ni Quinoa ni awọn eroja asaraloore bii omega- 3 fatty acids ati ọra ara ju awọn ounjẹ to jẹ koro miran lọ.