Ìṣesí àwọn ológun gbúdọ̀ yí padà tórí irú ogun tó n jà wá ti yàtọ̀! Ìmọ̀ràn Tinubu fún àwọn ológun rèé

Aarẹ Tinubu

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Aarẹ Bola Ahmed Tinubu ti sọ wipe orilẹede Naijiria atawọn orilẹede alamuleti rẹ ni ẹkun Lake Chad gbudọ ṣafihan ọkan akin ninu mimu ayipada ba iṣesi ati aṣa awọn ologun.

Aarẹ jẹ ko di mimọ pe nini ayipada ninu ọgbọn ti awọn ologun n fi ṣe iṣẹ wọn ti ṣe pataki bayii nitoripe awọn orilẹede to wa ni ẹkun yii n koju ogun ti ko jokoo tẹtẹrẹ soju kan ati ogun teeyan o le mọ ibi to ti n gbe ọwọ bọ eyi to tumọ si wipe wọn o tilẹ ṣe ni ibamu pẹlu ofin ijagun mọ.

Aarẹ Tinubu n sọ ọrọ yii nibi ayẹyẹ ikẹkọjade awọn ọmọ ile ẹkọ ologun Senior Course 45 ti o wa ni Jaji.

Nibẹ ni aarẹ ti tọka sii wipe awọn ọta to n doju ogun kọ orilẹede yii lawọn ẹkun kọọkan kii ṣe awọn ojulumọ ọta to n ba ni ja iru ogun teeyan ti mọ tẹlẹ.

Aarẹ wa rọ awọn orilẹede ilẹ Afirika lati jọ ṣiṣẹ papọ lodi si awọn idunkoko mọni to ba n waye to si mẹnu ba pataki akitiyan ti orilẹede Naijiria, Cameroon, Niger Republic ati Chad n ko lati mu alafia wa si ẹkun Lake Chad.

O tun gbe ọrọ rẹ lẹsẹ nipa sisọ pe ajọṣepọ yii gbudọ jẹ gẹgẹ bii apẹrẹ to ṣee tẹle ati to ṣe tunṣe fun amulo nibikibi to ba ti wulo.

“A tun gbudọ jẹ akinkanju to dangajia lati ṣe atunṣe si iṣesi ati aṣa awọn ologun. Kii ṣe awọn ologun taa mo oju wọn la n ba ja loju ogun kii sii ṣe iru ogun taa mọ tẹlẹ. Rara, awọn ogun ti ko gbe oju kan, awọn ogun ta o mọ ibi ti wọn ti n gbe ọwọ bọ ti wọn o si tẹle ofin ijagun ni a n ba ja.

“A gbudọ sunraki bo ṣe yẹ lati le bori wọn. Eyi yoo nilo ayipada ero ọkan, ninu ọgbọn dida ati amulo awọn nnkan ijagun pẹlu ijara mọ iṣẹ.”

Nigba ti o n gboriyin fun akitiyan ijọba to ṣe kuro lori alefa ninu igbaradi fun ijagu ti awọn ọmọ ogun maa n ṣe, Aarẹ Tinubu jẹjẹ lati jara mọ iṣẹ, nipa pipese iranwọ fun ileeṣẹ ologun.

“Gẹgẹ bi adari orilẹede, mo ti fi ara mi fun awọn ipinu yii: lati ṣamulo gbogbo agbara ti ani lati rii daju pe abo to daju wa fun awọn eeyan wa ati dukia wọn ni ọna to tọ fun awujọ."

Kii ṣe ọmọ Naijiria nikan lọmọ ogun to kẹkọ gboye

Lati ilẹ Asia ati Africa atawọn orilẹede mii ni Africa ni awọn ọmọ ilẹ ẹkọ ogun ọkandinlọọdunrun to n kẹkọ jade ti wa. Aarẹ Tinubu si sọ fun wọn pe ikẹkọ wọn yii wa si asiko ti awọn orilẹede nilo rẹ.

Tinubu gboriyin fun gbogbo wọn to si ni wiwa wọn si Naijiria jẹ ẹri rere wipe aabo ilu kii ṣe nipa ipa tabi egungun bikoṣe ninu ka tun maa ni ibadọrẹ ati ifọwọsowọpọ, iṣejọba daradara ati ibọwọ funra ẹni.