Àwọn aṣòfin tako àfikún owó ìná ọba ní Nàìjíríà

Aworan

Oríṣun àwòrán, Others

Ile Asofin ni Naijiria ti kede pe awọn ko ni buwọlu afikun owo ina ọba ni Naijiria.

Eyi n waye lasiko ti awọn aṣofin naa bu ẹnu atẹ lu afikun owo ina ọba ti ajọ National Electricity Regulatory Commission (NERC) gbe wa si iwaju wọn.

Awọn aṣofin naa ni wọn fi imọ ṣọkan lẹyin ti aṣofin Aliyu Madaki sọrọ soke pe inira ti awọn ọmọ Naijiria n la kọja ko ṣee fi ẹnu sọ.

O ni kii se asiko yii ti ọwọongogo gbode bẹrẹ lati owo epo bẹntiro, ni awọn naa tun fẹ fi owo kun owo ina ọba.

Madaki ni ti wọn ba gbe igbeṣẹ naa yoo ṣafihan pe wọn ko ni imọlara nkan ti awọn ọmọ Naijiria n la kọja.

O ni oun gbogbo lo nira bayii nitori ọwọngogo epo bẹntiro to lọ si oke sii.

Lẹyin naa ni Ile Igbimọ aṣofin paṣẹ fun igbimọ to n jiroro lori ọrọ ina ọba lati ṣe agbẹyẹwọ abadofin ti ajọ NERC naa gbe wa si iwaju wọn.

Aworan

Oríṣun àwòrán, Others

Wọn ni eyi yoo fun wọn laaye lati gbe yẹwo si ọtun ati si osi fun ọna abayọ ti ko ni pa awọn ọmọ Naijiria lara.

Ile Aṣofin ni awọn ri ohun ti awọn ọmọ Naijiria n la kọja, ti iya ati iṣẹ si gbode kan.

Awọn aṣofin naa wa ni awọn ko ni laju wọn silẹ ki ohun gbogbo maa bajẹ lọ, ti wọn si ni ifẹ awọn ni lati ri pe igbeaye awọn ọmọ Naijiria dara si.

Bakan naa ni wọn fikun un pe awọn yoo ri daju pe awọn ajọ to n pese ina ọba ko ja awọn ọmọ Naijiria lole tabi fi aye ni awọn araalu lara.