Agbébọn pa èèyàn méjì ní New Zealand ní wákàtí díẹ̀ kí ìdíje ife ẹ̀yẹ àgbáyé àwọn obínrin bẹ̀rẹ̀

Orilẹ-ede New Zealand ti n ṣọfọ bayi lẹyin ti agbebọn kan dede ṣina ibọn bolẹ nigba to ku wakati diẹ ki idije ifẹ ẹyẹ agbaye Fifa Women's World Cup bẹrẹ, eyii to mu ẹmi eeyan meji lọ.
Yatọ si awọn meji yii, eeyan mẹfa mii tun farapa, ninu eyii ti ọlọpaa wa lara wọn.
Olootu ijọba orilẹ-ede naa, Chris Hipkins ti sọ pe ikọlu naa kii ṣe iṣẹ awọn agbesumọmi.
Iroyin ni idije ife ẹyẹ agbaye naa yoo si maa tẹsiwaju lai si idiwọ kankan nitori iṣẹlẹ ọhun.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Adari agbegbe Auckland, Wayne Brown, ni ikọlu naa ko ni nnkan ṣe pẹlu idije ife ẹyẹ agbaye
Ọwọ ti tẹ agbebọn naa amọ wọn ni awọn ko tii le sọ eredi to fi ṣina ibọn fun awọn eeyan.
Adari agbegbe Auckland ti iṣẹlẹ ọhun ti waye, Wayne Brown, sọ pe ikọlu naa ko ni nnkankan lati ṣe pẹlu idije ife ẹyẹ agbaye awọn obinrin to n bẹrẹ nibẹ lonii.
Afurasi ọhun, Matu Tangi Matua Reid, kii ṣe ajoji si awọn ọlọpaa nitori irufẹ idile to ti wa, nibi ti iwa ipa ti maa n waye loorekoore.
Ọlọpaa ni awọn fi afurasi naa si atimọle ninu ile ṣaaju amọ o le jade lati ṣiṣẹ nibi ti wọn ti n kọle, bẹẹ si ni ko laṣẹ lati lo ibọn.
Hipkins ti ba awọn araalu Aucland sọrọ, nibi to ti só fun mọlẹbi awọn to ba iṣẹlẹ naa lọ kẹdun.
O ni awọn ọlọpaa yoo tu iṣu de isalẹ ikoko bi afurasi ẹni ọdun mẹrinlelogun ọhun ṣe ri ibọn to yin si awọn eeyan.
Ẹwẹ, ko si ẹnikẹni to farapa ninu awọn oṣiṣẹ FIFA atawọn agbabọọlu ninu ikọlu naa.















