Ṣé lóòótọ́ ni Adájọ́ tó ń gbọ́ awuyewuye ìbò ààrẹ kọ̀wé fipò sílẹ̀?

Oríṣun àwòrán, COURTOFAPPEAL.GOV.NG
Iroyin kan lo ti gba ori ayelujara pe Adajọ Boloukuoromo Moses Ugo, to wa ninu igbimọ to n gbọ awuyewuye lori eto idibo aarẹ, ti kọwe fipo rẹ silẹ lẹyin ti ẹgbẹ oṣelu APC dunkoko mọ-ọn.
Ileeṣẹ iroyin kan lo gbe iroyin naa sori ayelujara ati loju opo Twitter.
Lẹyin ti Ileeṣẹ iroyin naa gbe iroyin naa jade, awọn ẹka ayelujara miiran bẹrẹ si ni maa pin iroyin naa kaakiri.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 1
Iroyin ofege ni pe Adajọ Ugo kọwe fipo silẹ- NJC
Alukoro fun ẹka idajọ, NJC, Soji Oye ni irọ ni iroyin naa pe Onidajọ Moses Boloukuoromo Ugo kọwe fipo silẹ ninu igbimọ adajọ
Oye ni irọ to jina sotọ ni iroyin naa, to si rọ awọn eeyan orilẹede Naijiria lati yago fun pinpin iroyin naa kiri nitori wọn fẹ fi da wahala silẹ laarin awọn ọmọ orilẹede Naijiria ni.
O tẹsiwaju pw laipẹ Ileẹjọ to n gbọ awuyeawuye lori igbẹjọ eto idibo Aarẹ yoo fi atẹjade sita fun awọn akọroyin.
Ta ni Adajọ Boloukuoromo Moses Ugo?
Adajọ Boloukuoromo Moses Ugo jẹ ọkan lara igbimọ ẹni marun un to gbọ ẹjọ lori awuyewuye ibo to gbe aarẹ Bola Tinubu wọle.
Ugo ni adajọ agba fun ileẹjọ kotẹmilọrun nipinlẹ Kano
Adajọ, ẹni ọdun mẹtadinlọgọta lo wa lati ijọba ibilẹ Kolokuma/Opokuma nipinlẹ Bayelsa.
Bakan naa ni oun lo kere ju lara awọn adajọ to wa ninu igbimọ naa.
O ti jẹ adajọ agba fun ileẹjọ kotẹmilọrun ri nipinlẹ Bayelsa.
Ugo pari ẹkọ rẹ ni fasiti Calabar , ti wọn si pe wọ BAR ni ọdun 1990.
O lọ Ile ẹkọ awọn agbẹjọro ẹka ti ipinlẹ Eko lọdun 1989 si 1990
Adajọ melo lo n gbọ awuyeawuye lori ibo to tabo aseyọri Tinubu.
Adajọ marun un lo n se isakoso igbẹjọ lori ibo to tako bi Bola Tinubu se di aarẹ orilẹede Naijiria ninu oṣu kẹta.
Awọn adajọ naa ree;
- Haruna Simon Tsammani
- Justice Stephen Adah
- Justice Misitura O. Bolaji-Yusuf
- Justice Boloukuoromo Moses Ugo
- Justice Abba Bello Mohammed
Awọn adajọ yii lo ni di oṣu kẹsan an lati kede idajọ wọn sita
Ẹ fi sinku ofin mu awọn to n gbe iroyin ofede kiri- Bayo Onanuga
Alukoro fun iponlogo ibo fun Tinubu/Shettima ninu eto idibo aarẹ lọdun 2023, Bayo Onanuga ti rọ ileeṣẹ ọlọpaa lati fi sinku ofin mu gbogbo awọn eeyan to n gbe iroyin ofege kiri lorilẹede Naijira .
Onanuga sọ eleyi lori opo ayelujara rẹ, to si ni gbogbo ọmọ Naijiria lo n kọminu lori awọn eyan kan se n gbe iroyin ofege kiri.
"Ileẹjọ kotẹmilọrun kede laipẹ pe iroyin ofege ni iroyin meji kan to gba ori ayelujara, eyi to fẹ se akoba fun ẹka igbẹjọ naa nitori oṣelu.
"Ileeṣẹ Ọlọpaa ni lati dide si isẹ wọn. A ni ofin lorilẹede Naijiria to tako iroyin ofege. Ki Ọlọpaa gbe igbesẹ tabi ki nnkan bajẹ lọwọ iroyin ofege ."
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 2















