Kò tán síbẹ̀!Arákùnrin yí lùlu wákàtí 150 ní ìrántí ìyàwó rẹ̀ tí àìsàn jẹjẹrẹ pa

Ẹ ti gbọ nipa Hilda Baci to dana laisinmi fun ọgọrun wakati ni Naijiria abi?
Iroyin arakunrin taa mu tọ yin wa yi ko ni nkan ṣe pẹlu ina dida bi kii ṣe pe o lu ilu fun aimọye wakati ni.
Ọrọ kọja igba n ba jo onilu gbe ilu lọ, ilu rẹ ko re ibikan bẹẹ si ni oun naa to jẹ onilu ko sinmi titi di nkan bi wakati aadọjọ ko to dawọ duro.
Orileede Northern Ireland ni Allister Brown ti lu ilu yi to si ti fi orukọ lelẹ ninu akọsilẹ lagbaye gẹgẹ bi ẹni to lu ilu fun igba to pẹ julọ.
Ẹni ọdun marundinlaadọta yi pari iṣẹ nla yi lọjọ Abamẹta lẹyin to bẹrẹ lọjọ Aiku to kọja.
O ti ṣaaju forukọ silẹ ninu itan gẹgẹ bi ẹni to lu ilu fun wakati to pọ julọ iyẹn wakati mẹrinlelaadoje ati iṣẹju marun un.
Ni bayi o ti kọja itan to fi lelẹ ṣaaju pẹlu wakati aadọjọ to fi lu ilu lalae sinmi.
Tori ki lo fi bẹrẹ igbiyanju yii?

Ninu ọrọ to sọ fakọroyin BBC, arakunrin Allister Brown sọ pe oun gbiyanju yi ni iranti iyawo rẹ Sharon Deegan to papoda.
Aisan jẹjẹrẹ oronro lo ṣekupa Sharon ẹni ọdun mọkandinlaadọta to dagbere fun duniya loṣu kini ọdun 2021.
Nigba to n sọrọ arakunrin Brown sọ pe ''igbiyanju nla'' ni o jẹ fun oun.
O ni ''Mo dupẹ lọwọ gbogbo awọn alatilẹyin mi.''
''Mo ti ni lọkan tipẹ lati ṣe nkan manigbagbe ni iranti Sharon''
Wn ṣe afihan igbiyanju rẹ yi loju opo ayelujara pẹlu ero ọkan lati fi kowojọ fun awọn to n ṣeto itọju aisan jẹjẹrẹ oronro.
Bẹẹ lo sọ pe oun fi ko owo jọ ni atilẹyin awọn to ni iporuru ọkan nitori o sọ pe ''ọkan mi ko balẹ lẹyin iku Sharon tori naa yoo mu ọgbọn wa lati ṣe ikowojọ fawọn nkan mejeeji yi.''
Igba kẹta ree ti yoo gbiyan ilu lilu ọlọpọ wakati
Ẹmeeji ọtọọtọ ni arakunrin Brown ti fi orukọ lelẹ gẹgẹ bi eeyan to da lu ilu fun wakati to pẹ julọ.
Ọdun 2003 lo kọkọ lulu fun wakati mejidinlọgọta.
O tun da ara lọdun 2008 nigba to lulu lalae dawọ duro fun wakati 103 ku diẹ.
O ni awọn igbiyanju ẹmẹẹji to ṣaaju jẹ igbaradi fun eleyi toun wa pada fi pegede yi.
''Iriri naa jẹ nkan to jẹ iyalẹnu;lati ni iru imọ yi fun igbaradi to peye,lati le fi mura kalẹ de awọn nkan mii to ṣẹlẹ lasiko igbiyanju yi.''
''Eyi ti mo pada ṣe yi lọ daada.Mo dupẹ lọwọ awọn ikọ to ṣe atilẹyin fun mi.''
Ofin ẹgbẹ GWR sọ pe bi arakunrin Brown ba lu ilu fun wakati kan, igbalaaye wa fun lati sinmi iṣẹju marun un.
O gbiyanju lati lulu lai sinmi ti o pada wa fi iṣẹju wọnyi sinmi fun isẹju to pọ daada.
Nigba ti yoo fi pe ọjọ marun un to bẹrẹ igbiyanju ilu lilu yi, ọrẹ rẹ sọ pe oorun wakati meji pere lo ri sun lati igba to bẹrẹ.
Laarin ogun ọdun sẹyin arakunrin Brown ati awọn onilu meji mii lagbaye lo n ba ara wọn du ipo ẹni to da nikan lu ilu fun wakati to pẹ julọ.
Nigba ti wọn beere lọwọ rẹ boya yoo kopa ninu idije ajumọṣe lati mọ ẹni to le lu ilu fun wakati to pẹ julọ, arakunrin Brown sọ pe oun to kan bayi ni ki oun wa ibi to rọrun lati joko ki oun si sun lọ.












