Ẹ̀yin tí mo bá ṣẹ̀, ẹ foríjìmì - Agbako sọ̀rọ̀ níbi ayẹyẹ ọ̀gọ́rùn-ún ọdún rẹ̀
Ẹgbẹ awọn oṣere tiata Yoruba, TAMPAN ti ṣe ayẹyẹ ọjọ ibi ọgọrun un ọdun fun agba oṣere ni, Charles Olumo, ti ọpọ eeyan mọ si Agbako.
Ọpọ araalu atawọn oṣere tiata Yoruba lo kopa nibi ayẹyẹ naa to waye niluu Abeokuta l'ọsẹ to kọja.
Nibi ayẹyẹ naa ni Alagba Olumo ti dupẹ lọwọ awọn to ṣe agbatẹru ayẹyẹ naa, to si tun lo anfaani ọhun lati tọrọ aforijin lọwọ gbogbo awọn 'to ba ṣẹ̀'.
Bakan naa ni ẹgbẹ TAMPAN ṣe ileri lati ma a pese owo ni oṣooṣu fun itọju Agbako, ati awọn agba oṣere miran.
Ninu ọrọ rẹ, aarẹ ẹgbẹ TAMPAN, Ọgbẹni Bolaji Amusan ti ọpọ mọ si Mr. Latin sọ pe 'dandan ni ki awọn agba osẹre to jiya nidi iṣẹ naa, jẹ ọrọ̀ rẹ̀".
Ẹwẹ, oludasilẹ ijọ INRI, Primate Ayodele naa jẹjẹẹ lati fun baba agba naa ni ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹta Naira, ọgrun Naira ati ounjẹ ni oṣooṣu titi Agbako yoo fi jade laye.
Ta ni Charles Olumo Agbako?
Ọdun 1923 ni wọn bi alagba Charles Olumo nipinlẹ Ogun, ti orukọ abisọ rẹ si jẹ Abdulsalam Sanyaolu.
O lọ sile ẹkọ alakọbẹrẹ niluu Egba-Owode, ko to lọ silu Abeokuta nibi to ti kẹkọ nile ẹkọ girama Lisabi Grammar School.
Lẹyin ọdun 1990, irawọ Agbako bẹrẹ si n tan lagbo oṣere tiata Yoruba.
Laipẹ yin ni agba osere tiata naa kede pe aisan n se oun, ti ara oun ko si le eyi ti BBC Yoruba gbe jade.
Bakan naa lo fara han ninu sọọsi kan nil;u Ibadan lati se ayẹyẹ ọjọ ibi ọgọrun ọdun rẹ
Lara awọn sinima to lamilaka ti Agbako ti kopa ni Saworo Ide, Taxi Driver, Jagun, Amin Orun, Aiye, Jayesinmi, Igbo Dudu sti bẹẹ bẹẹ lọ.