World Albinism Day: Gerald Uche Eke sọ ìrírí rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àfín àti ohun tó fà á tó ṣe ní àrun jẹ́jẹ́re
Arakunrin Gerald Eke ti gba awọn obi ni imọran, ki wọn maṣe jẹ ki ọmọ wọn to jẹ afin maa rin ninu oorun nitori ilera ara wọn.
Eke sọ eyi lasiko Ifọrọwerọ pẹlu ileeṣẹ iroyin BBC lọna ati ṣe ayẹyẹ ọjọ awọn afin lagbaye, iyẹn World Albinism day ti ọdun 2023.
Ninu ifọrọwerọ naa Eke ni nigba ti oun wa ni kekere ni oun ti ma n rin ninu orun, ti oun ba n bọ lati ileẹkọ.
- Wo kókó pàtàkì mẹ́fà nípa ìtàn ayé Godswill Akpabio, ààrẹ ilé aṣòfin àgbà tuntun
- Ìyá arúgbó dìde nínú pósí bí wọn ṣe n múra làti sìn òkú rẹ̀
- Ṣé Damilola Faparusi yòó mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ láti se oúnjẹ fún ọgọ́fà wákàtí-
- EFCC ló láṣẹ lábẹ́ òfin láti ṣe ẹjọ́ Emefiele, kìí ṣe DSS – Falana
- Bọ́ọ̀sì tó ń bọ̀ láti ayẹyẹ ìgbéyàwó tàkìtì, èèyàn mẹ́wàá jáde láyé
- Bí ọmọ mẹ́rin sẹ jàjàbọ́ nínú aginjù rèé lẹ́yìn tí ìyá wọn kú nínú ìjàmbá ọkọ̀ bàálù
Amọ o ni ohun akọkọ ti oun ranti ni pe to ba di alẹ, ara oun a maa ṣe ọra, eleyii ti awọn oloyinbo n pe ni ''skin burn''.
O ni lẹyin naa ni inira bẹrẹ fun oun ninu ara, ko to di pe awọn dokita wa ni oun ti ni aisan jẹjẹrẹ ara, iyẹn skin cancer.
Arakunrin Gerald Eke wa rọ awọn obi lati bojuto awọn ọmọ wọn to jẹ afin, ki wọn si ri pe awọn ọmọ naa ko rin ninu oorun ni ọsan.



