Xue Li gbajúmọ̀ aṣẹ̀ṣọ́ oge ṣàlàyé bí àwọn òbí rẹ̀ ṣe gbé e jù sílẹ̀ nítorí pé ó jẹ́ àfín

Oríṣun àwòrán, @LUXVISUALSTORYTELLERS
Awọn agba bọ wọn ni afin kii wọja ki tajatẹran o maa mọ bẹẹni oniruuru igbagbọ lawọn eeyan ni nipa wọn eleyi ti o maa n mu ipalara ba wọn lọpọ igba.
Ni ilẹ Yoruba nikan kọ lawọn afin ti n foju wina oniruru ipenija. O dabi ẹni pe bi wọn ṣe n ṣe nilẹ yii naa ni wọn n ṣe nilẹ miran.
Nigba ti Xueli wa lọmọde, awọn obi rẹ lọ ju u silẹ nile awọn ọmọ alainiya kan.
- Haram ni kí èèyàn máa san owó ìtúsílẹ̀ fún àwọn ajínigbé - Sheikh Ibrahim Maqari
- Tíṣà mu ọtí yó ló bá kó àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ọmọdé lọ ilé ijó oníhòhò
- Gbogbo ẹ̀yin ẹgbẹ́ tẹ́ẹ ní ìpínu láti da ètò àbò àti àláfíà Nàìjíríà rú, ká ṣọ́ra o!
- Ìdí tí a fi lé àwọn Fulani 42 tó ya bo agbègbè Okitipupa padà sí ìpínlẹ̀ wọn - Ìjọba ìpínlẹ̀ Ondo
- Kò sí àwáwí fún ìwà Baba Ijesha àmọ... -Yomi Fabiyi
- Bola Tinubu: Ọlọrun kò ní gbà kí Naijiria tún la ogun abẹ́lé míràn kọjá
- Ìdí rèé tí ìgbéyàwó ọdún 27 tú ká láàárín Bill àti Melinda Gates
Nigba to pe ọmọ ọdun mẹrindinlogun lo ti di ilumọọka loju ewe awọn iwe iroyin atigbadegba lori oge ṣiṣe bii Vogue ti o si di aṣoju fun ọpọ eekan ileeṣẹ aṣaraloge ati ẹṣọ oun ẹgba ọwọ ati ọrun.
Lorilẹede China awọn eeyan kan a maa fi oju wo awọn afin gẹgẹ bi egun.
Amọṣa nitoripe o da yatọ, Xueli rawọ le iṣẹ aṣaraloge.
Xue Li ni orukọ apejẹ tawọn oṣiṣẹ ile awọn ọmọ alainiya naa fun un. ni ede Chine Xue tumọ si yinyin, Li si tumọ si ẹwa.

Oríṣun àwòrán, BIEL CAPLLONCH
Nigba to pe ọmọ ọdun mẹta ni wọn gba a tọ to si lọ bẹrẹ si ni gbe pelu obinrin alagbatọ rẹ ati ọmọ rẹ.
O ni alagbatọ oun ko yi orukọ ti wọn fun un pada ati pe o fẹ ki oun maa ranti orilẹede China to jẹ orirun oun.
"Nigba ti wọn bi mi, ijọba orilẹede China gbe ofin ifetosọmọbibi kalẹ lori eeyan kan ṣoṣo ni idile kan.
To ba tun wa lọ jẹ afin lọmọ too bi, ọran kan niyẹn lọtọ.

Oríṣun àwòrán, JET VAN GAAL
Ọpọlọpọ awọn ọmọ bii temi ni wọn ti gbe ju sọnu, wọn ti ti ọpọlọpọ wọn mọle, tabi ki wọn di ẹni ẹgan bi wọn ba lọ sileewe.
Lawọn agbegbe kan nilẹ Afirika, wọn a maa pa wọn tabi ge ẹya ara wọn.
Awọn ajẹ ati alafọṣẹ a maa fi egungun wọn ṣoogun nitoripe awọn eeyan nigbagbọ pe o n wo aisan san, ṣugbọn irọ nla ni eyi, igbagbọ odi lasọn ni.
Ori ko emi yọ pe wọn kan lọ gbe mi ju silẹ lasan ni. awọn obi to bi mi ko tilẹ fi ijuwe kankan silẹ ti mo le fi mọ ọjọ ibi.

Oríṣun àwòrán, REINY BOURGONJE
Amọṣa ni ọdun kan sẹyin awọn dokita ya aworan ọwọ mi lati fi mọ iye ọdun ti mo le to wọn si sọ pe o ṣeeṣe ki n jẹ ọmọ ọdun marundinlogun.
Nigba ti mo pe ọmọ ọdun mẹrinla ni mo ti bẹrẹ si ni ṣe aṣoju ipolongo oja fun awọn ileeṣẹ to n ṣe ẹṣọ ati ẹgba ọwọ ati ọrun.
Iya mi kan si eeyan kan to n ran aṣọ ni ilu Hong Kong.
O ni ọmọ ọkunrin to ni arun kan, o wa fẹ ran awọn aṣọ kan ti yoo maa bo aṣiri rẹ ti awọn eeyan ko fi ni maa wo ẹnu rẹ nigba gbogbo.

Oríṣun àwòrán, KURT GEIGER
O beere boya mo nifẹ si kikopa nibi eto ipatẹ aṣọ oge to fẹ ṣe ni Hong Kong.
Mo fẹran didadarapọ mọọ gidigidi.
Lẹyin rẹ ni mo gba ipe fun fọto yiya kan ninu eyi ti a ti ri Brock Elbank ti oun naa pe mi fun fọto yiya ni ileeṣẹ rẹ to wa ni ilu London
O gbe fọto naa si ori oju opo ayelujara rẹ.
Lẹyin naa ni ileeṣẹ Zebedee Talent naa pe mi lati beere boya mo fẹ lati ba wọn ṣiṣẹ gẹgẹ bi ara ilakaka wọn lati rii pe awọn akanda naa lẹnu lawujọ ileeṣẹ ẹṣọ oun ẹgba ọwọ ati ọrun.
Wọn fi ọkan lara awọn fọto ti Brock ya fun mi sinu iwe iroyin atigbadegba kan lorilẹede Italy ti orukọ rẹ n jẹ Vogue loṣu kẹfa ọdun 2019 pẹlu fọto Lana del Rey ni iwaju iwe iroyin atigbadegba naa.
Lakọkọ mi o mọ iye to wọle si apo iwe iroyin atigbadegba naa ṣugbọn o pẹ ki n to mọ idi tinu awọn eeayn fi n dun si mi nigba naa.

Oríṣun àwòrán, ROB JANSEN
Ni awujọ ileeṣẹ aṣaraloge didayatọ jẹ ibukun lọna kan to si n ṣi ilẹkun fun mi lati ta awọn eeyan ji nipa awọn afin.
Lọpọ igba fọto angẹli tabi oku ni wọn saba maa n fi awọn afin ya lawujọ ẹṣọ oun ẹgba ọwọ ati ọrun. Eleyi si maa n bi mi ninu lọpọlọpọ.
Eleyi si ri bẹẹ laarin awujọ tabi aṣa to n ṣeku pa awọn afin lawọn orilẹede bii Tanzania ati Malawi.

Oríṣun àwòrán, ANNE WEIDINGER
Mo fẹ ki awọn ọdọmọde yoku to jẹ afin-tabi akanda tabi idayatọ miran- o mọ pe awọn naa lee ṣe e, wọn lee da ohun gbogbo ti wọn ni lọkan lati da.
Fun emi o, bi awa kan ṣe yatọ si awọn kan, lawọn ti a yatọ si naa yatọ si awọn kan.
Mo fẹran ere idaraya ati gigun nnkan.
Awọn eeyan lee maa sọ pe o ko lee ṣe, ṣugbọn iwọ gbiyanju rẹ, waa ri pe o le ṣe. "













