Ó ṣeéṣe kí Emefiele sá kúrò ní Nàìjíríà tí ilé ẹjọ́ bá fún un ní béèlì - DSS

Godwin Emefiele

Oríṣun àwòrán, TWITTER

Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ Nàìjíríà ìyẹn Department of State Services, DSS ti rọ ilé ẹjọ́ gíga ti ìlú Abuja láti da ẹjọ́ tí gómìnà tẹ́lẹ̀ fún ilé ìfowópamọ́ báǹkì àpapọ̀, CBN wí pé àwọn ń tẹ ẹ̀tọ́ rẹ̀ lójú mọ́lẹ̀ nù.

Emiefiele nínú ẹjọ́ tó pè tako DSS àti ọ́fíìsì agbẹjọ́rò àgbà orílẹ̀ èdè látọwọ́ agbẹjọ́rò rẹ̀, J. B. Daudu ní DSS fi òun sí àhámọ́ lọ́nà àìtọ́.

Ó ní wọn kò fún òun ní ààyè láti rí àwọn ẹbí àti àwọn agbẹjọ́rò òun.

Àmọ́ níbi ìgbẹ́jọ́ náà tó wáyé lọ́jọ́ Ìṣẹ́gun, DSS ní tí ilé ẹjọ́ bá gba béèlì Emefiele, ó máa sá kúrò ní orílẹ̀èdè Nàìjíríà ni.

Agbẹjọ́rò àgbà orílẹ̀ èdè Nàìjíríà náà kín DSS lẹ́yìn nígbà tó ń júwe Emefiele bí ẹni tó le fi sá kúrò ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà tí wọ́n bá ti tu sílẹ̀.

Bákan náà ni wọ́n ní àwọn kò tẹ ẹ̀tọ́ Emefiele lójú mọ́lẹ̀ pẹ̀lú bó ṣe wà ní àhámọ́ àwọn nítorí ẹ̀mí rẹ̀ kò sí nínú ewu kankan.

Wọ́n ní àwọn kò fi ìyà tàbí ṣe báṣubáṣu ní àgọ́ àwọn tó wà àti pé àwọn gba àṣẹ láti ilé ẹjọ́ kí àwọn tó fi òfin gbé e.

Wọ́n fi kun pé èyí fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé àwọn ò tẹ ẹ̀tọ́ rẹ̀ lójú mọ́lẹ̀ rárá nítorí àṣẹ ilé ẹjọ́ ni àwọn ń tẹ̀lé.

Kìí ṣe nítorí ìwà ìgbéṣùmọ̀mí la ṣe ń wádìí Emefiele - DSS

Nínú àgbékalẹ̀ ọ̀rọ̀ wọn, wọ́n jiyàn rẹ̀ wí pé kò sí nǹkan tó jọ mọ́ ṣíṣe agbátẹrù àwọn agbéṣùmọ̀mí lára ẹ̀sùn tí Emefiele ń kojú àti pé kìí ṣe wí pé nítorí pé ó dá sí òṣèlú tàbí ṣe àyípadà owó náírà sí owó tuntun ló ṣe okùnfà rẹ̀ gbígbé rẹ̀.

Wọ́n ṣàlàyé pé àwọn ẹ̀sùn tí Emefiele ń kojú dá lórí ṣíṣe owó ìlú kúmọkùmọ, dída ètò ọrọ̀ ajé ìlú rú àti àwọn ẹ̀sùn mìíràn tó fara pẹ.

Agbẹjẹ́rò ọ́fíìsì agbẹjọ́rò àgbà Nàìjíríà, Tijani Gazal rọ ilé ẹjọ́ láti da ẹjọ́ tí Emefiele pè nù nítorí àwọn ẹ̀sùn náà kò rí ẹsẹ̀ walẹ̀.

Gazal tún ní ilé tí Emefiele gbé ẹjọ́ náà lọ kò ní àṣẹ láti gbọ́ ẹjọ́ náà.

Lẹ́yìn atótónu láti ẹnu àwọn agbẹjọ́rò, adájọ́ Hamza Muazu tó ń gbọ́ ẹjọ́ náà sún ìgbẹ́jọ́ sí ọjọ́ Kẹtàlá oṣù Keje láti gbé ìdájọ́ rẹ̀ kalẹ̀.

EFCC ló láṣẹ lábẹ́ òfin láti ṣe ẹjọ́ Emefiele, kìí ṣe DSS – Falana

Emefiele

Oríṣun àwòrán, @NTANewsNow

Agbẹjọro agba Naijiria, Femi Falana, ti sọ pe ko tọ si ileeṣẹ ọtẹlẹmuyẹ Naijiria, DSS, lati pe gomina CBN ti wọn rọ loye, Godwin Emefiele, lẹjọ.

Falana ninu atẹjade kan sọ pe o yẹ ki wọn tare Emefiele si ikawọ ajọ to n gbogun ti iwa ajẹbanu, EFCC, ni kankan.

Gẹgẹ bii ohun to sọ, EFCC lo laṣẹ labẹ ofin lati ṣe ẹjọ emefiel, kii ṣe DSS.

O ni “Ni nkan bii oṣu diẹ sẹyin, ileeṣẹ SSS fi ẹsun ṣiṣẹ onigbọwọ awọn agbesumọmi atawọn ẹsun mi kan Godwin Emefiele....”

“Lasiko naa, ijọba Buhari dena akitiyan SSS lati fi ṣikun ofun mu Emefiele ati lati ṣe ẹjọ rẹ.”

“Amọ lẹyin ti Aarẹ Bola Tinubu ni ko lọ rọọkun nile, SSS na ọwọ gan niluu Eko, wọn si gbe lọ si Abuja.”

Bo tilẹ jẹ pe DSS kọkọ sọ pe Emefiele ko si lakata awọn, wọn pada sọrọ soke pe awọn ti fi ṣikun ofin mu afurasi naa.

Ẹwẹ, Falana ni awọn idajọ kan to ti waye sẹyin ni irufẹ ẹjọ bayii fi han pe ko tọ si DSS lati ṣe ẹjọ afurasi ọhun, bi komṣe EFCC.

O ṣalaye pe ninu igbẹjọ Bukola Saraki ati ijọba apapọ to waye lọdun 2018, idajọ ile ẹjọ to ga julọ ni Naijiria lọdun naa lọhun fi han gbangba ikọja aye ni DSS n ṣe bo ṣe mu Emefiele.

O pari ọrọ rẹ pe “Ni ilana idajọ ile ẹjọ to ga julọ ninu ẹjọ Saraki, SSS ko laṣẹ lati ṣe iwadii tabi ṣe ẹjọ Emefiele lori ọrọ to jẹ mọ ṣiṣẹ owo baṣubaṣu atawọn ẹsun mii to ni ṣe pẹlu ọrọ aje ilu.”