Tinubu appointments: Kí ló kan ẹkùn tàbí ẹ̀yà nínú ìyànsípò àwọn tí yóò bá Ààrẹ ṣiṣẹ́

Aworan aarẹ Buhari

Oríṣun àwòrán, NIGERIAN PRESIDENCY

    • Author, Makuochi Okafor
    • Role, Broadcast Journalist, BBC Igbo

Aarẹ Naijiria tuntun Bola Tinubu yan awọn olori ileeṣẹ aabo Naijiria laipẹ yii.

Lara igbeṣẹ yii, o ni kawọn to wa nidi aabo bii olori ileeṣẹ awọn ọmọ ogun, ti ọmọ ogun ori omi ọga ọlọpaa, ọga ileeṣẹ to n mojuto ibode to si fi awọn miran rọpo wọn.

Lootọ ko si ohun to jẹ tuntun ninu igbesẹ yi amọ iriwisi ọtọọtọ ti n tẹle iyansipo ti aarẹ ṣe tawọn kan si n foju wo wipe ṣe ti ilu ni aarẹ wo lati fi ṣe iyansipo yi ni tabi o ṣaa fẹ awọn ti ọkan rẹ yoo balẹ lati ba siṣẹ pọ.

Amọ loju opo ayelujara ọrọ to jọ mọ ẹkun ati ẹya ibi tawọn ti aarẹ yan ti wa lọmọ Naijiria n mu bẹnu.

Koda wọn ti n ṣe afiwe iyansipo aarẹ Tinubu pẹlu ti aarẹ Buhari.

Awọn olori ologun lasiko Buhari
Awọn olori ologun ti Tinubu yan

“Mo nifẹ si awọn olori ileeṣẹ aabo Naijiria ti aarẹ yan tori o wa lati ẹkun orisi ti o wa ni Naijiria''

Gbajugbaja sọrọsọrọ ori redio nii Osikhena Dirisi (@Osi_Suave) lo sọ bẹloju opo Twitter.

Bẹẹ ni ẹlomiran sọ pe ibi yowu ki wọn ti wa, ki wọn ṣaa ti ṣe isẹ wọn bi iṣẹ lo jẹ oun logun.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

BBC ba onwoye kan sọrọ lori iyansipo yi to si ni iyansipo naa ka ọrọ ẹya ati iṣedeede laarin ẹkun Naijiria pẹlu ilana iwe ofin Naijiria.

Kabir Adamu to jẹ onimọ nipa ọrọ aabo to ba BBC sọrọ gboṣuba kare fun awọn ti aarẹ yan sipo olori ileeṣẹ ọmọ ogun ati ọga ọlọpaa gẹgẹ bi eleyi to fi ti ẹnu ṣe.

Ṣugbọn o ni ni tohun ti pe aarẹ Tinubu ko ti pari gbogbo iyansipo rẹ, o jọ pe o n gbe igbesẹ kan ti aarẹ to jẹ ṣaaju rẹ gbe.

O ni igbesẹ yi ni aifun awọn obirin ati ọdọ ni ipo to yẹ labẹ ijọba rẹ.

Gẹgẹ bi ajọ iṣọkan agbaye UN ti ṣe sọ, eeyan miliọnu 206 lo wa lorileede Naijiria ni ọdun 2021,ninu wọn la si ti ri obirin ida 49.95% ti ida 60% si jẹ awọn ti ọjọ ori wọn wa labẹ ọdun 25.

Iṣedeede nidi iyansipo jẹ nkan tawọn eeyan n ran lẹnu ni paapa lasiko ijọba tore kọja labẹ aarẹ Buhari ti wọn si ni o ku diẹ kaato nidi iṣedeede ati dọgba n dọgba laarin awọn ẹya ati ẹkun orileede Naijiria.

Ka sọ ootọ, ọrọ iṣedeede ati dọgba yi ko ṣẹṣẹ bẹrẹ.

Lati igba ti Naijiria ti gba ominira ni o ti jẹyọ ninu oṣelu Naijiria.

Aworan Igbakeji aarẹ Kashim Shettima nibi to ti n wọ ami ipo tuntun fun adele ipo ọga ọlọpaa

Oríṣun àwòrán, NIGERIAN PRESIDENCY

Ṣe o yẹ ki Naijiria maa wo ẹya tabi ẹkun nidi iyansipo?

Orileede ti o kun fun orisi ẹya eyi to le ni 500 ni Naijiria jẹ.

Ninu wọn ẹya mẹta lo gbajumọ-Hausa-Fulani, Yoruba ati ẹya Igbo.

Ọtọọtọ ni ẹya kọọkan n da ṣe ki awọn oyinbo amunisin to ko gbogbo wọn papọ.

Labẹ ofin,ijọba alajumọṣẹ Federal System eleyi to gbe agbara fun ijọba apapọ ti awọn ijọba ipinlẹ ati ibilẹ naa si lagbara ti wọn naa ni Naijiria n lo.

Ọrọ pipin agbara yi ati idẹyẹsi awọn ẹya kan ti mu kawọn ọmọ Naijiria maa tẹnumọ iṣedeede ni ijọba.

Eyi lo ṣokunfa ogun abẹle nigba kan ti a si n gburo ija ẹlẹyamẹya loore koore ni Naijiria.

Ni ab ijọba to kọja iyẹn ijọba aarẹ Muhammadu Buhari,ọrọ aiṣedeede ati idẹyẹsi yi mu kawọn kan lati ilẹ Igbo sọ pe awọn fẹ ya sọtọ labẹ asia Biafra.

Koda nilẹ Yoruba awọn kan naa sọ pe awọn fẹ ki idasilẹ Yoruba Nation waye.

Gbogbo awọn nkan wọnyi lo mu ko ṣe pataki ki aarẹ ti yoo ba yan awọn eeyan sipo agbara wo kikaju oṣunwọn wọn ko si tun wo iṣedeede nipa pipin ipo laarin awọn ẹya Naijiria.

Adamu onimọ nipa ọrọ aabo taa ba sọrọ ni ''ọkan lara awọn ohun to n ṣokunfa ipenija aabo ni ikunsinu lori aiṣedeede yala to jẹ lootọ tabi eyi tawọn araalu lero pe o n waye''

Tori naa o sọ pe ijọba Tinubu ni lati ri wi pe araalu ri apẹrẹ iṣedeede nibi iyansipo to ba kede.

Iru ireti wo laraalu ni lọdọ awọn olori ileeṣẹ ologun ti aarẹ ṣẹṣẹ yan

Aworan awọn olori ileeṣẹ ologun ti aarẹ ṣẹṣẹ yan

Oríṣun àwòrán, NTA

Lẹnu ọdun meloo kan sẹyin ipenija aabo paapa ikọlu ati ijingbe to fi mọ iwa awọn janduku jẹ nkan ti o kan araalyu lominu.

Ajọ UN sọ pe nipari ọdun 2020 ikọlu awọn agbesunmọmi Boko Haram ṣokunfa iku eeyan to fẹ to 350,000 ti aimọye miliọnu eeyan si di ẹni to ṣipo kuro nilu lọ si ibomiran.

Lafikun, Kabir Adamu to jẹ onimọ nipa eto aabo sọ pe ''eeyan 78,000 ọmọ Naijiria lo ti padanu ẹmi wọn laarin ọdun mẹwaa sẹyin nipasẹ ipenija aabo''

O ni oun ni igbagbọ pe iṣẹ to wa niwaju awọn olori ileeṣẹ ologun yi ni pe ki wọn mu adinku ba iye ẹmi to n ba ipenija aabo lọ ni Naijiria.

Yatọ si tawọn olori ologun titun yi, araalu n reti ki aarẹ Tinubu fun araarẹ gbamuṣe lori ọrọ aabo.

Gẹgẹ bi Adamu ti ṣe sọ, ''eyikeyi ọga ileeṣẹ ologun ti ko ba kaju oṣunwọn, yiyọ bi jiga ni ki aarẹ yọ onitọhun.''

Ninu awọn ipenija ti araalu n reti ki wọn koju ni ikọlu sawọn ile ijọsin,iwa ajinigbe, ikọlu awọn agbesunmọmi ati janduku.

Bi a ko ba gbagbe,ọpọ awọn ọgba ẹwọn naa ni awọn janduku ṣe ikọlu si bẹẹ naa si ni wọn kọlu ọkọ reluwee ti wọn si ji awọn eeyan gbe.